Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42

Kí Ni Jèhófà Máa Mú Kó O Dì?

Kí Ni Jèhófà Máa Mú Kó O Dì?

“Ọlọ́run . . . ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.”—FÍLÍ. 2:13.

ORIN 104 Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ?

JÈHÓFÀ máa ń di ohunkóhun tó bá yẹ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tó di Olùkọ́, Olùtùnú àti Ajíhìnrere. Àwọn yìí sì jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ń dì láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Àìsá. 48:17; 2 Kọ́r. 7:6; Gál. 3:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lo àwọn èèyàn láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. (Mát. 24:14; 28:19, 20; 2 Kọ́r. 1:3, 4) Bákan náà, Jèhófà lè fún ẹnikẹ́ni lára wa ní ọgbọ́n àti agbára tá a nílò ká lè di ohunkóhun láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Àwọn àlàyé yìí jẹ́ ká rí díẹ̀ lára ìtúmọ̀ orúkọ Jèhófà, àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sì gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.

2. (a) Kí ló lè mú ká máa ṣiyèméjì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé bóyá ni Jèhófà ń lò wá? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Kò sẹ́ni tí kò wù pé kí Jèhófà lo òun, síbẹ̀ àwọn kan máa ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà lè lo àwọn. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé àwọn ò ní lè ṣe púpọ̀ torí ọjọ́ orí wọn, ipò tí wọ́n wà tàbí àwọn ìdí míì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn míì lè ronú pé ohun táwọn ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó, torí náà kò sídìí fún àwọn láti tún tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe púpọ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, àá wo àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àá rí bí Jèhófà ṣe mú kó máa wù wọ́n láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti bó ṣe fún wọn lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Paríparí rẹ̀, àá jíròrò ohun tá a lè ṣe kí Jèhófà lè rí àwa náà lò.

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń FÚN WA NÍ OHUN TÁ A NÍLÒ

3. Bó ṣe wà nínú Fílípì 2:13, báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kó máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?

3 Ka Fílípì 2:13. * Jèhófà lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ọ̀nà wo ló ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn kan nínú ìjọ lè nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí kí ohun kan wà nínú ìjọ tó yẹ ká bójú tó. Àwọn alàgbà lè ka lẹ́tà sí ìjọ létí pé ètò Ọlọ́run ń wá àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sìn ní ìjọ míì tàbí lọ́wọ́ nínú apá míì nínú iṣẹ́ ìsìn. Nírú ipò yìí, a lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mo lè yọ̀ǹda ara mi tàbí àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe láti ṣèrànwọ́?’ Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n gbé iṣẹ́ ńlá kan fún wa àmọ́ tá à ń ronú pé a ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ká wá máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ibi tí mo kà yìí ran àwọn míì lọ́wọ́?’ Ohun kan ni pé Jèhófà kì í fipá múni láti ṣe ohunkóhun. Àmọ́ tó bá kíyè sí i pé à ń ronú bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i, á mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa, á sì fún wa lágbára láti ṣe é.

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa ní agbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?

4 Jèhófà máa ń fún wa ní agbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Àìsá. 40:29) Ó lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí ẹ̀bùn àbínibí wa túbọ̀ wúlò. (Ẹ́kís. 35:30-35) Jèhófà tún lè lo ètò rẹ̀ láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká bàa lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeyanjú. Torí náà, tó o bá ń ṣiyèméjì pé bóyá ni wàá lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ, sọ pé káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bákan náà, o lè bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá,” torí pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run. (2 Kọ́r. 4:7; Lúùkù 11:13) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó sọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́, ó mú kó wù wọ́n láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì fún wọn lágbára láti ṣe é. Bá a ṣe ń gbé àwọn àpẹẹrẹ yìí wò, máa ronú àwọn ọ̀nà tí Jèhófà lè gbà lo ìwọ náà.

OHUN TÍ JÈHÓFÀ MÚ KÁWỌN ỌKÙNRIN KAN DÌ

5. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe lo Mósè láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè àti ìgbà tó lò ó?

5 Jèhófà mú kí Mósè di olùdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ìgbà wo ni Jèhófà mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé lẹ́yìn tí wọ́n “kọ́ Mósè ní gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” tó sì ronú pé òun tóótun láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè ni? (Ìṣe 7:22-25) Rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀yìn tí Jèhófà dá Mósè lẹ́kọ̀ọ́ tó sì di onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà tútù ni Jèhófà tó lò ó. (Ìṣe 7:30, 34-36) Jèhófà fún un nígboyà láti kojú Fáráò ọba Íjíbítì. (Ẹ́kís. 9:13-19) Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe lo Mósè àti ìgbà tó lò ó? Ẹ̀kọ́ náà ni pé àwọn tó fìwà jọ Jèhófà tó sì gbára lé e pátápátá ló máa ń lò.—Fílí. 4:13.

6. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe lo Básíláì láti ṣèrànwọ́ fún Ọba Dáfídì?

6 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà lo Básíláì láti ran Ọba Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́. “Ebi ń pa àwọn èèyàn náà, ó ti rẹ̀ wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n” nígbà tí wọ́n sá kúrò nílùú torí Ábúsálómù ọmọ Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Básíláì ti darúgbó, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, òun àtàwọn míì sì lọ pèsè fún Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Básíláì ò ronú pé òun ò lè wúlò fún Jèhófà mọ́ torí pé òun ti dàgbà. Dípò bẹ́ẹ̀, tinútinú ló fi yọ̀ǹda àwọn nǹkan ìní rẹ̀ kó lè pèsè ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nílò. (2 Sám. 17:27-29) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, Jèhófà lè lò wá láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tó ṣaláìní bóyá lórílẹ̀-èdè wa tàbí lórílẹ̀-èdè míì. (Òwe 3:27, 28; 19:17) Tá ò bá tiẹ̀ lè ṣèrànwọ́ fún wọn ní tààràtà, a lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé kí ètò Ọlọ́run lè rí owó tí wọ́n á fi ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá.—2 Kọ́r. 8:14, 15; 9:11.

7. Báwo ni Jèhófà ṣe lo Síméónì, báwo nìyẹn ṣe fún wa níṣìírí?

7 Jèhófà ṣèlérí fún Síméónì, ọkùnrin àgbàlagbà kan ní Jerúsálẹ́mù pé kò ní kú kí Mèsáyà tó dé, á sì fojú ara rẹ̀ rí i. Ìlérí yẹn fún Síméónì níṣìírí gan-an torí pé ọjọ́ pẹ́ tí ọkùnrin olóòótọ́ yìí ti ń dúró de Mèsáyà náà. Jèhófà sì san án lẹ́san torí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà rẹ̀. Lọ́jọ́ kan “ẹ̀mí darí rẹ̀,” ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó débẹ̀, ó rí Jésù ọmọ jòjòló, Jèhófà sì mú kí Síméónì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọmọ tó máa di Kristi náà. (Lúùkù 2:25-35) Kò dájú pé Síméónì pẹ́ láyé débi táá fi rí bí Jésù ṣe ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ ó mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún un. Àmọ́ o, kékeré nìyẹn lára ìbùkún tó ṣì máa rí gbà! Ìdí ni pé nínú ayé tuntun, á rí bí Jésù ṣe máa rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé nígbà ìṣàkóso rẹ̀. (Jẹ́n. 22:18) Ó yẹ káwa náà mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún wa nínú ètò rẹ̀.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe lè lò wá bó ṣe lo Bánábà?

8 Ọkùnrin ọ̀làwọ́ kan wà nínú ìjọ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Jósẹ́fù lorúkọ ọkùnrin yìí, ó sì yọ̀ǹda pé kí Jèhófà lo òun. (Ìṣe 4:36, 37) Àwọn àpọ́sítélì pe ọkùnrin yìí ní Bánábà, tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú” bóyá torí pé ó mọ bí wọ́n ṣe ń tu èèyàn nínú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di onígbàgbọ́, kò rọrùn fáwọn ará láti sún mọ́ ọn torí pé ó ti máa ń ṣenúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. Àmọ́ torí pé ara Bánábà yá mọ́ọ̀yàn, ó sún mọ́ Sọ́ọ̀lù, ó sì ràn án lọ́wọ́. Ó dájú pé ohun tó ṣe yẹn máa wú Sọ́ọ̀lù lórí gan-an. (Ìṣe 9:21, 26-28) Nígbà tó yá, àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù rí i pé ó yẹ káwọn fún àwọn ará tó wà ní iyànníyàn Áńtíókù ti Síríà níṣìírí. Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni tí wọ́n rán lọ síbẹ̀? Bánábà ni! Ẹni tó sì yẹ kí wọ́n rán nìyẹn. Nígbà tó dé ọ̀hún, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa fi gbogbo ọkàn wọn ṣègbọràn sí Olúwa.” (Ìṣe 11:22-24) Bákan náà lónìí, Jèhófà lè sọ wá di “ọmọ ìtùnú” fáwọn ará wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. Ó lè mú ká ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì ká sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, ó sì lè jẹ́ orí fóònù làá ti tù wọ́n nínú. Ṣé wàá jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ bó ṣe lo Bánábà?—1 Tẹs. 5:14.

9. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe ran Arákùnrin Vasily lọ́wọ́ láti di olùṣọ́ àgùntàn tó jáfáfá?

9 Jèhófà ran Arákùnrin Vasily lọ́wọ́ láti di olùṣọ́ àgùntàn tó jáfáfá. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni nígbà tó di alàgbà, ó sì ronú pé bóyá lòun á lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará, pàápàá àwọn tí ìṣòro ń bá fínra. Àmọ́ àwọn alàgbà tó nírìírí dá a lẹ́kọ̀ọ́, ó sì tún gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Arákùnrin Vasily fi ohun tó kọ́ sílò, ó sì sunwọ̀n sí i. Ọgbọ́n wo ló dá? Ó ronú àwọn àfojúsùn kéékèèké kan tó fẹ́ lé bá. Bí ọwọ́ rẹ̀ ṣe ń tẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ lẹ̀rù tó ń bà á ń dín kù. Ó wá sọ pé: “Ohun tó ń bà mí lẹ́rù tẹ́lẹ̀ ti wá dohun tí mò ń gbádùn báyìí. Inú mi máa ń dùn gan-an tí Jèhófà bá jẹ́ kí n rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí màá fi tu arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú.” Ẹ̀yin arákùnrin wa, tẹ́ ẹ bá ṣe bíi ti Arákùnrin Vasily, tẹ́ ẹ jẹ́ kí Jèhófà lò yín, á fún yín ní ọgbọ́n, òye àti agbára tẹ́ ẹ máa fi ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ.

OHUN TÍ JÈHÓFÀ MÚ KÁWỌN OBÌNRIN KAN DÌ

10. Kí ni Ábígẹ́lì ṣe, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ lára rẹ̀?

10 Dáfídì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì torí pé Ọba Sọ́ọ̀lù ń lépa wọn. Àwọn èèyàn Dáfídì lọ bá Nábálì, ọmọ Ísírẹ́lì kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kó wá oúnjẹ díẹ̀ fáwọn, bó ti wù kó kéré mọ. Ojú ò tì wọ́n láti béèrè pé kí Nábálì wá nǹkan fáwọn torí pé àwọn ló ń ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀ nínú aginjù. Àmọ́ ahun ni Nábálì, kò sì fún wọn ní nǹkan kan. Dáfídì tutọ́ sókè ó fojú gbà á, ó ní àfi kóun pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà lágboolé rẹ̀. (1 Sám. 25:3-13, 22) Àmọ́, Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì níwà, ó sì tún lẹ́wà. Ó lo ìgboyà, ó lọ bá Dáfídì ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má gbẹ̀san torí pé ìyẹn máa jẹ́ kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó fọgbọ́n gba Dáfídì nímọ̀ràn pé kó fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó ń tuni lára tí Ábígẹ́lì sọ àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó hù mú kí ọkàn Dáfídì rọ̀. Ó gbà pé Jèhófà ló rán an sí òun. (1 Sám. 25:23-28, 32-34) Ábígẹ́lì ní àwọn ànímọ́ tó mú kó wúlò fún Jèhófà. Lọ́nà kan náà, bí ẹ̀yin arábìnrin bá jẹ́ olóye, tẹ́ ẹ sì mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n báni sọ̀rọ̀, Jèhófà máa lò yín láti fún àwọn míì lókun yálà nínú ìdílé yín tàbí nínú ìjọ.—Òwe 24:3; Títù 2:3-5.

11. Kí làwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù ṣe, àwọn wo ló sì ń fara wé wọn lónìí?

11 Nígbà tí wọ́n fẹ́ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù wà lára àwọn tí Jèhófà lò fún iṣẹ́ náà. (Neh. 2:20; 3:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olórí ni bàbá wọn, àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ tó lágbára tó sì léwu yẹn. (Neh. 4:15-18) Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín àwọn ọmọ yìí àtàwọn olókìkí Tékóà tí “kò rẹ ara wọn sílẹ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́” náà! (Neh. 3:5) Ẹ wo bí inú àwọn ọmọ náà ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ yẹn láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) péré! (Neh. 6:15) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, inú àwọn arábìnrin tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń dùn láti ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan. Lára ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń kọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì máa ń tún wọn ṣe. Irú àwọn arábìnrin tó mọṣẹ́, tí wọ́n nítara, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin yìí ń mú kí iṣẹ́ náà máa tẹ̀ síwájú.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe lè lò wá bó ṣe lo Tàbítà?

12 Jèhófà mú kí “àwọn iṣẹ́ rere àti ọrẹ àánú” tí Tàbítà ń ṣe pọ̀ gidigidi pàápàá fáwọn opó. (Ìṣe 9:36) Ọ̀pọ̀ ló ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ nígbà tó kú torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì lójú àánú. Àmọ́, ìdùnnú ṣubú layọ̀ wọn nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù jí i dìde. (Ìṣe 9:39-41) Kí la rí kọ́ lára Tàbítà? Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ bó ti wù kó kéré tó.—Héb. 13:16.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe lo Arábìnrin Ruth, kí ni arábìnrin yìí wá sọ?

13 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ruth máa ń tijú gan-an, síbẹ̀ ó fẹ́ di míṣọ́nnárì. Nígbà tó wà ní kékeré, ṣe ló máa ń fìtara pín ìwé àṣàrò kúkúrú láti ilé kan sí òmíì. Ó sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ yìí gan-an.” Síbẹ̀, ó máa ń ṣòro fún un láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lójúkojú. Láìka pé ojú máa ń tì í, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18). Lọ́dún 1946, ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, nígbà tó sì yá, ó ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Hawaii àti Japan. Jèhófà lò ó gan-an láti tan ìhìn rere kálẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè yẹn. Lẹ́yìn tó ti wàásù fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin (80) ọdún, ó sọ pé: “Jèhófà ni ọ̀ránmọ-níṣẹ́-fàyàtì-í, ó sì ti fún mi lókun. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìtìjú mi. Ó dá mi lójú hán-ún pé Jèhófà lè lo ẹnikẹ́ni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e.”

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ LÒ Ẹ́

14. Bó ṣe wà nínú Kólósè 1:29, kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè lò wá?

14 Tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Àmọ́, kí ni Jèhófà máa mú kó o dì? Ó sinmi lórí bí ìwọ fúnra rẹ bá ṣe sapá tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Ka Kólósè 1:29.) Tó o bá yọ̀ǹda ara rẹ, Jèhófà lè mú kó o di ajíhìnrere tó nítara, olùkọ́ tó dáńtọ́, ẹni tó mọ bí wọ́n ṣe ń tu àwọn míì nínú, òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ọ̀rẹ́ tòótọ́ tàbí ohunkóhun tó máa mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.

15. Bó ṣe wà nínú 1 Tímótì 4:12, 15, kí ló yẹ káwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ máa bẹ Jèhófà fún?

15 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin wa ńkọ́? Ètò Ọlọ́run nílò àwọn ọkùnrin tó lókun dáadáa láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìdí sì ni pé nínú ọ̀pọ̀ ìjọ, iye àwọn alàgbà pọ̀ ju iye àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ. Torí náà, ẹ̀yin arákùnrin wa tẹ́ ẹ ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ṣé ẹ lè sapá láti gba àwọn àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ? Nígbà míì, àwọn arákùnrin kan máa ń sọ pé “akéde tí mò ń ṣe yìí ti tó mi, mo ṣáà ń ṣe déédéé.” Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó sì fún ẹ lágbára tí wàá fi ṣe gbogbo nǹkan tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Oníw. 12:1) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a nílò yín gan-an!—Ka 1 Tímótì 4:12, 15.

16. Kí ló yẹ ká bẹ Jèhófà fún, kí sì nìdí?

16 Jèhófà lè mú kó o di ohunkóhun tó bá fẹ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Torí náà, bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kó o sì tún bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní agbára tí wàá fi ṣe é. Yálà ọmọdé ni ẹ́ tàbí àgbàlagbà, lo àkókò rẹ, okun rẹ àti gbogbo ohun tó o ní láti bọlá fún Jèhófà báyìí. (Oníw. 9:10) Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù dí ẹ lọ́wọ́ àtiṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni gbogbo wa ní láti máa bọlá fún Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́ bá a ṣe ń ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, bó ti wù kó kéré mọ!

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ṣe tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé o máa ń ronú pé bóyá lo ṣì wúlò fún Jèhófà? Àbí o máa ń ronú pé èyí tó ò ń ṣe báyìí ti tó? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe lè mú kó máa wù ẹ́ láti di ohunkóhun kó o lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ àti bó ṣe máa fún ẹ lágbára láti ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 3 Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí, síbẹ̀ gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni ìlànà inú rẹ̀ wúlò fún.