ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ September 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti October 28 sí December 1, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wà lára àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ ká ní. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí ipò nǹkan bá yí pa dà fún wa?

Ìròyìn Ayọ̀ Ni Amágẹ́dọ́nì!

Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú Amágẹ́dọ́nì? Kí lá jẹ́ ká di ìgbàgbọ́ wa mú bí òpin ti ń sún mọ́lé?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó Máa Yá Wa Lára Láti Fi Ara Wa Sábẹ́ Jèhófà?

Àwọn alàgbà, àwọn bàbá àtàwọn ìyá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀ lára Gómìnà Nehemáyà, Ọba Dáfídì àti Màríà ìyá Jésù.

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”

Tá a bá máa jẹ́ ìpè Jésù, kí ló yẹ ká ṣe? A máa rí ìtura lábẹ́ àjàgà Jésù tá a bá ń ṣe ohun mẹ́ta yìí.

‘Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn’

Nínú ìran tí Jòhánù rí, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” máa la ìpọ́njú ńlá já, ó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ibi gbogbo láyé ni wọ́n ti wá àti pé wọ́n máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.