Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”

Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára.”​MÁT. 11:28.

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Bó ṣe wà nínú Mátíù 11:​28-30, ìlérí wo ni Jésù ṣe?

JÉSÙ ṣèlérí amọ́kànyọ̀ kan fún àwọn èrò tó ń tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi . . . màá sì tù yín lára.” (Ka Mátíù 11:​28-30.) Ìlérí tí Jésù ṣe kì í ṣọ̀rọ̀ ẹnu lásán, òótọ́ ni. Ká lè lóye ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe fún obìnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún ọ̀pọ̀ ọdún.

2. Kí ni Jésù ṣe fún obìnrin kan tó ń ṣàìsàn?

2 Nǹkan ò dẹrùn fún obìnrin yẹn, ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́ ló ń wá. Bó ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ dókítà kan ló ń lọ sọ́dọ̀ òmíì. Odindi ọdún méjìlá (12) ló fi pààrà ilé ìwòsàn, síbẹ̀ pàbó ló já sí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nínú Òfin Mósè, aláìmọ́ ni. (Léf. 15:25) Ó gbọ́ pé Jésù ń wo àwọn aláìsàn sàn, torí náà ó wá Jésù lọ. Nígbà tó rí i, ó fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ara rẹ̀ sì yá! Kì í ṣe pé Jésù wo obìnrin náà sàn nìkan, ó tún pọ́n ọn lé lójú gbogbo èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù máa bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, èdè àpọ́nlé tó sì fìfẹ́ hàn ló fi pè é. Ó pè é ní “ọmọbìnrin.” Ẹ wo bí inú obìnrin yẹn ti máa dùn tó pé òun bọ́ lọ́wọ́ àìsàn burúkú tó ń ṣe òun!​—Lúùkù 8:​43-48.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

3 Ẹ kíyè sí i pé obìnrin yẹn ló tọ Jésù lọ. Òun ló sapá láti wá Jésù rí. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, a gbọ́dọ̀ sapá láti lọ “sọ́dọ̀” Jésù. Lásìkò wa yìí, Jésù ò ní wo ẹnikẹ́ni tó “wá sọ́dọ̀” ẹ̀ sàn lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, ó ṣì ń pè wá pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi . . . màá sì tù yín lára.” Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè márùn-ún: Báwo la ṣe lè “wá sọ́dọ̀” Jésù? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín”? Kí la máa rí kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀? Kí nìdí tí iṣẹ́ tó gbé fún wa fi ń tuni lára? Kí ló sì yẹ ká ṣe ká lè máa rí ìtura nìṣó lábẹ́ àjàgà rẹ̀?

“Ẹ WÁ SỌ́DỌ̀ MI”

4-5. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà “wá sọ́dọ̀” Jésù?

4 Ọ̀nà kan tá a lè gbà “wá sọ́dọ̀” Jésù ni pé ká kọ́ gbogbo ohun tá a lè kọ́ nípa rẹ̀, ìyẹn àwọn ohun tó ṣe àtohun tó sọ. (Lúùkù 1:​1-4) Kò sẹ́ni tó lè ṣèyẹn fún wa, àwa fúnra wa la máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. A tún lè lọ “sọ́dọ̀” Jésù tá a bá pinnu láti ṣèrìbọmi tá a sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

5 Ọ̀nà míì tá a lè gbà lọ “sọ́dọ̀” Jésù ni pé ká tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí ni Jésù ń lò láti bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. (Éfé. 4:​7, 8, 11; Jòh. 21:16; 1 Pét. 5:​1-3) Àwa la gbọ́dọ̀ lọ bá wọn, ó ṣe tán, kò sí báwọn alàgbà ṣe lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa tàbí ohun tá a nílò. Ẹ gbọ́ ohun tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Julian sọ, ó ní: “Àìsàn tó ń ṣe mí mú kí n fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, ọ̀rẹ́ mi kan sì gbà mí nímọ̀ràn pé kí n sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ mi. Nígbà tó sọ fún mi, mo kọ́kọ́ ronú pé mi ò nílò irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, mo ní kí wọ́n wá. Kí n má tàn yín, mo gbádùn ìbẹ̀wò yẹn, kò sóhun tí mo lè fi wé.” Bíi tàwọn alàgbà méjì tó bẹ Julian wò, àwọn alàgbà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ “èrò inú Kristi,” ìyẹn ni pé, ká lóye bí Kristi ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, ká sì fara wé e. (1 Kọ́r. 2:16; 1 Pét. 2:21) Ká sòótọ́, kò sí ẹ̀bùn tá a lè fi wé irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀.

“Ẹ GBA ÀJÀGÀ MI SỌ́RÙN YÍN”

6. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín”?

6 Nígbà tí Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tó ní lọ́kàn ni pé, “Ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ mi.” Ó sì tún lè túmọ̀ sí pé “Ẹ jẹ́ ká jọ ti ọrùn bọ àjàgà, ká sì jọ máa ṣe iṣẹ́ Jèhófà.” Èyí ó wù kó jẹ́, ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ń bẹ fún wa láti ṣe.

7. Bó ṣe wà nínú Mátíù 28:​18-20, iṣẹ́ wo la ní láti ṣe, kí ló sì dá wa lójú?

7 A jẹ́ ìpè Jésù nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, tá a sì ṣèrìbọmi. Gbogbo èèyàn ni Jésù pè, kò sì ní lé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe tán láti sin Jèhófà tọkàntọkàn pa dà. (Jòh. 6:​37, 38) Ojúṣe gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi ni láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jésù. Ó sì dá wa lójú pé Jésù á máa wà pẹ̀lú wa lẹ́nu iṣẹ́ náà, kò sì ní dá wa dá a.​—Ka Mátíù 28:​18-20.

‘Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LỌ́DỌ̀ MI’

Máa tu àwọn èèyàn lára bíi ti Jésù (Wo ìpínrọ̀ 8-11) *

8-9. Kí nìdí táwọn onírẹ̀lẹ̀ fi ń wá sọ́dọ̀ Jésù, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

8 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ fẹ́ràn Jésù gan-an. (Mát. 19:​13, 14; Lúùkù 7:​37, 38) Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àtàwọn Farisí. Àwọn Farisí ò lójú àánú, wọ́n sì máa ń gbéra ga. (Mát. 12:​9-14) Ẹlẹ́yinjú àánú ni Jésù ní tiẹ̀, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn Farisí máa ń wá ipò ọlá, wọ́n sì máa ń ṣe fọ́ńté torí ipò wọn láwùjọ. Àmọ́ Jésù dẹ́bi fún wíwá ipò ọlá, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. (Mát. 23:​2, 6-11) Àwọn Farisí máa ń jẹ gàba lé àwọn míì lórí, wọ́n sì máa ń lo agbára bó ṣe wù wọ́n káwọn èèyàn lè bẹ̀rù wọn. (Jòh. 9:​13, 22) Ọ̀rọ̀ Jésù ní tiẹ̀ máa ń tu àwọn èèyàn lára, ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn.

9 Kí làwọn nǹkan tá a sọ tán yìí kọ́ ẹ? Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni pẹ̀lẹ́ àti onírẹ̀lẹ̀? Ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì? Ṣé mo máa ń fi inúure hàn sáwọn míì?’

10. Báwo ni nǹkan ṣe rí lára àwọn tó bá Jésù ṣiṣẹ́?

10 Jésù mú kára tu àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 10:​1, 19-21) Ó máa ń mú kó rọrùn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti bi í ní ìbéèrè, òun náà sì máa ń tẹ́tí sí èrò wọn. (Mát. 16:​13-16) Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dà bí irúgbìn tó wà lórí ilẹ̀ rere. Wọ́n mọyì ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn, wọ́n fi í sílò, wọ́n sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.

Jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tó sì ṣeé bá sọ̀rọ̀

Máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ọlọ́run

Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó o sì máa ṣiṣẹ́ kára *

11. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

11 Ṣé olórí ìdílé ni ẹ́ tàbí ẹni tó ń múpò iwájú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe sáwọn ará ilé mi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́? Ṣé mo máa ń mára tù wọ́n? Ṣé mo máa ń jẹ́ kí wọ́n sọ tinú wọn tàbí bi mí ní ìbéèrè? Ṣé mo sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn?’ Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí àwọn Farisí tó máa ń gbaná jẹ mọ́ àwọn tó bá ń bi wọ́n ní ìbéèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì máa ń ṣenúnibíni sáwọn tí èrò wọn yàtọ̀ sí tiwọn.​—Máàkù 3:​1-6; Jòh. 9:​29-34.

‘ARA MÁA TÙ YÍN’

12-14. Kí nìdí tí ara fi máa ń tù wá bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa?

12 Kí nìdí tí ara fi máa ń tù wá bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa? Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà, àmọ́ ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò.

13 Àwọn alábòójútó tó dáa jù la ní. Jèhófà tó jẹ́ Alábòójútó wa Tó Ga Jù Lọ kì í ṣe abaraámóorejẹ, ó sì máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Ó mọyì iṣẹ́ tá à ń ṣe fún un. (Héb. 6:10) Ó sì máa ń fún wa lágbára ká lè ṣe ojúṣe wa láṣeyanjú. (2 Kọ́r. 4:7; Gál. 6:​5, àlàyé ìsàlẹ̀) Jésù Ọba wa náà ò kẹ̀rẹ̀, àpẹẹrẹ tó dáa ló fi lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 13:15) Àwọn alàgbà tó ń bójú tó wa ńkọ́? Àwọn náà ń sa gbogbo ipá wọn láti máa fara wé Jésù “olùṣọ́ àgùntàn ńlá.” (Héb. 13:20; 1 Pét. 5:2) Wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ onínúure, bí wọ́n ṣe ń kọ́ wa, tí wọ́n ń dáàbò bò wá tí wọ́n sì ń fún wa níṣìírí.

14 Àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù la ní. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán la ní, iṣẹ́ tá a jọ ń ṣe sì ń múnú wa dùn, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ ẹ̀ níbòmíì. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná: Àǹfààní ńlá la ní pé àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run là ń bá ṣiṣẹ́, ìlànà gíga ni wọ́n sì ń tẹ̀ lé, síbẹ̀ wọn ò jọ ara wọn lójú. Wọ́n ní ẹ̀bùn lóríṣiríṣi, síbẹ̀ wọn kì í gbéra ga, wọ́n gbà pé àwọn míì sàn ju àwọn lọ. Torí pé wọ́n mú wa lọ́rẹ̀ẹ́, wọn kì í fojú alábàáṣiṣẹ́ lásán wò wá. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa débi pé wọ́n lè yọ ojú wọn fún wa, àní sẹ́ wọ́n ṣe tán àtifi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí wa!

15. Ojú wo ló yẹ ká fi wo iṣẹ́ tá à ń ṣe?

15 Iṣẹ́ tó dáa jù là ń ṣe. À ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Jèhófà, a sì ń já irọ́ Sátánì. (Jòh. 8:44) Ẹrù tó ń wọni lọ́rùn ni Sátánì gbé ka àwọn èèyàn lórí, ó sì ń fayé ni wọ́n lára. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́ ká gbà gbọ́ pé Jèhófà ò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá àti pé kò nífẹ̀ẹ́ wa. Ká ní bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ohun ìbànújẹ́ gbáà ni ì bá jẹ́! Àmọ́ kò sóhun tó jọ ọ́ torí pé irọ́ funfun báláú ni. Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó wá “sọ́dọ̀” Jésù. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá. (Róòmù 8:​32, 38, 39) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn bá a ṣe ń rí ìyípadà táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!

MÁA RÍ ÌTURA LÁBẸ́ ÀJÀGÀ JÉSÙ

16. Báwo ni iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa ṣe yàtọ̀ sí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa?

16 Iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yàtọ̀ sí iṣẹ́ tara wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀pọ̀ wa bá fi máa délé lẹ́yìn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, á ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, iṣẹ́ tá a ṣe lọ́jọ́ náà sì lè má fi bẹ́ẹ̀ wú wa lórí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá lo ara wa dé góńgó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti ti Jésù, inú wa máa ń dùn gan-an. Ó lè rẹ̀ wá tẹnutẹnu lóòótọ́, kódà ó lè jẹ́ pé ńṣe la tiraka lọ sípàdé lọ́jọ́ náà. Àmọ́ nígbà tá a bá fi máa pa dà sílé, ṣe ni inú wa máa ń dùn tí ara wa sì máa ń yá gágá. Bó sì ṣe máa ń rí náà nìyẹn tá a bá sapá láti lọ sóde ẹ̀rí tá a sì ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Àǹfààní tá a máa ń rí kọjá ohun tó ń ná wa lọ!

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ibi tí agbára wa mọ?

17 Àmọ́ ohun kan wà tó yẹ ká fi sọ́kàn. Ohun náà sì ni pé ó níbi tí agbára wa mọ. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣe ju agbára wa lọ. Bí àpẹẹrẹ, tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa ṣe kìràkìtà nídìí mo fẹ́ dogún mo fẹ́ dọgbọ̀n. Àmọ́ ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ fún ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó bi í pé: “Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ọ̀dọ́kùnrin yẹn máa ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ èèyàn dáadáa torí pé Ìhìn Rere Máàkù dìídì sọ pé Jésù “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Jésù wá sọ ohun tó máa ṣe kó lè di ọmọ ẹ̀yìn òun, ó ní: ‘Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o wá máa tẹ̀ lé mi.’ Ó wu ọkùnrin náà pé kó tẹ̀ lé Jésù àmọ́ kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí “ohun ìní rẹ̀ pọ̀” gan-an. (Máàkù 10:​17-22) Bí ò ṣe gba àjàgà Jésù nìyẹn o, tó sì ń bá a lọ láti sìnrú fún “Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lò bá ṣe?

18. Kí ló yẹ ká máa ṣe látìgbàdégbà, kí sì nìdí?

18 Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò bóyá ohun tó tọ́ la fi sípò àkọ́kọ́ láyé wa. Kí nìdí? Ká lè rí i dájú pé à ń lo okun wa bó ṣe tọ́. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mark sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi gbà pé nǹkan tẹ̀mí ló gbawájú láyé mi. Lóòótọ́ mò ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ mo kíyè sí i pé mi ò yé ronú nípa owó àti bí màá ṣe mú kí nǹkan túbọ̀ dẹrùn fún mi nípa tara. Ó máa ń yà mí lẹ́nu pé dípò kí nǹkan sàn, ṣe ló túbọ̀ ń nira. Ìgbà yẹn ló wá yé mi pé àwọn nǹkan tara ló gbà mí lọ́kàn jù àti pé ipò kejì ni mo fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí.” Arákùnrin Mark tún èrò rẹ̀ ṣe, ó ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ìyẹn sì mú kó túbọ̀ máa lo ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sọ pé, “Mo ṣì máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ mò ń rí ọwọ́ Jèhófà àti Jésù láyé mi, ìyẹn sì mú kí n pọkàn pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi.”

19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fojú tó tọ́ wo nǹkan?

19 Àá máa rí ìtura nìṣó lábẹ́ àjàgà Jésù tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta yìí. Àkọ́kọ́, máa fojú tó tọ́ wo nǹkan. Ká rántí pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe, a sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ náà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Òṣìṣẹ́ ni wá, Jèhófà sì ni Ọ̀gá wa. (Lúùkù 17:10) Tá a bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe wù wá, àjàgà náà á nira fún wa. Bí àpẹẹrẹ, kò sí bí màlúù kan tó wà lábẹ́ àjàgà ṣe lè lágbára tó, tó bá yà kúrò níbi tí olówó rẹ̀ darí ẹ̀ sí, tó sì ń lo agídí, ṣe ló máa rẹ̀ ẹ́, á sì ṣe ara ẹ̀ léṣe. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, àá borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè yọjú, àá sì gbé nǹkan ribiribi ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ohun kan tó dájú ni pé, kò sẹ́ni tó lè dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́!​—Róòmù 8:31; 1 Jòh. 4:4.

20. Kí lohun tó yẹ kó sún wa láti fi ara wa sábẹ́ àjàgà Jésù?

20 Ìkejì, jẹ́ kí ohun tó tọ́ máa sún ẹ ṣe iṣẹ́ Jèhófà. Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fògo fún Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn tó jẹ́ pé ojúkòkòrò àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí wọ́n máa tẹ̀ lé Jésù dẹni tí kò láyọ̀ mọ́, ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ṣe ni wọ́n pa Jésù tì. (Jòh. 6:​25-27, 51, 60, 66; Fílí. 3:​18, 19) Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn ò pa Jésù tì, wọ́n fayọ̀ sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì nírètí pé àwọn máa bá Jésù Kristi jọba ní ọ̀run. Bíi tiwọn, tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti ọmọnìkejì wa ló mú ká fi ara wa sábẹ́ àjàgà Jésù, àá máa láyọ̀.

21. Bó ṣe wà nínú Mátíù 6:​31-33, kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe?

21 Ìkẹta, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. A ti pinnu pé a máa fayé wa sin Jèhófà, àá sì yááfì àwọn nǹkan ká lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Jésù ti sọ fún wa tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa. Àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro yòówù kó yọjú. Bá a ṣe ń fara dà á, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà á túbọ̀ máa lágbára sí i. (Jém. 1:​2-4) Ó tún dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò, pé Jésù máa darí wa àti pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fún wa níṣìírí. (Ka Mátíù 6:​31-33; Jòh. 10:14; 1 Tẹs. 5:11) Kí lèèyàn tún ń fẹ́ tó jùyẹn lọ?

22. Kí ló ń múnú wa dùn?

22 Kò sí àní-àní pé ara tu obìnrin tí Jésù wò sàn lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́ ohun tó máa jẹ́ kó rí ìtura tó wà pẹ́ títí ni pé kó di ọmọlẹ́yìn Kristi. Kí lo rò pé obìnrin náà ṣe? Tó bá jẹ́ ìpè Jésù, tó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ àjàgà rẹ̀, á ti wà pẹ̀lú Jésù lọ́run báyìí. Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Ohun yòówù kó yááfì kó lè di ọmọlẹ́yìn Kristi tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé la máa wà títí láé, inú wa dùn pé a jẹ́ ìpè Jésù tó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi!”

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

^ ìpínrọ̀ 5 Jésù pè wá pé ká wá sọ́dọ̀ òun. Tá a bá máa jẹ́ ìpè Jésù, kí ló yẹ ká ṣe? Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn ìbéèrè yìí, á sì tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè rí ìtura torí pé à ń bá Jésù ṣiṣẹ́

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Onírúurú ọ̀nà ni Jésù gbà tu àwọn èèyàn lára.

^ ìpínrọ̀ 66 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Bíi ti Jésù, arákùnrin yìí ń ṣe àwọn nǹkan táá mú kí ara tu àwọn míì.

ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Onírúurú ọ̀nà ni Jésù gbà tu àwọn èèyàn lára. Bíi ti Jésù, arákùnrin yìí ń ṣe àwọn nǹkan táá mú kí ara tu àwọn míì.