Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 37

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó Máa Yá Wa Lára Láti Fi Ara Wa Sábẹ́ Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó Máa Yá Wa Lára Láti Fi Ara Wa Sábẹ́ Jèhófà?

Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba?HÉB. 12:9.

ORIN 9 Jèhófà Ni Ọba Wa!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ara wa sábẹ́ Jèhófà?

Ó YẸ ká fi ara wa sábẹ́ * Jèhófà torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Torí náà, ó láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ láyé àti lọ́run. (Ìfi. 4:11) Àmọ́, ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló dáa jù. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣàkóso tí wọ́n sì ń darí àwọn míì. Àmọ́ tá a bá fi àkóso wọn wé ti Jèhófà, àá rí i pé Jèhófà ni Alákòóso tó gbọ́n jù. Yàtọ̀ síyẹn, òun ló nífẹ̀ẹ́ wa jù, ó ń ṣàánú wa, ó sì ń gba tiwa rò.—Ẹ́kís. 34:6; Róòmù 16:27; 1 Jòh. 4:8.

2. Bó ṣe wà nínú Hébérù 12:9-11, kí nìdí tó fi yẹ ká fi ara wa sábẹ́ Jèhófà?

2 Jèhófà fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òun kì í ṣe torí pé a kàn bẹ̀rù òun, bí kò ṣe torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun, a sì mọ̀ pé òun jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù nípa bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa, ó ní ká jẹ́ kó máa “yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba” torí pé “ire wa” ló ń wá.—Ka Hébérù 12:9-11.

3. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fi ara wa sábẹ́ Jèhófà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

3 A lè fi hàn pé à ń fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tá a bá ń sapá láti máa ṣègbọràn sí i lójoojúmọ́, tá a sì yẹra fún ṣíṣe tinú wa. (Òwe 3:5) Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ tó ta yọ tí Jèhófà ní, bẹ́ẹ̀ lá máa rọrùn fún wa láti fi ara wa sábẹ́ rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ àtàwọn ànímọ́ míì tó ní ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. (Sm. 145:9) Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Tá a bá sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò nílò òfin jàn-ànràn-jan-anran ká tó mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á mú ká máa ṣègbọràn sí i lérò, lọ́rọ̀ àti níṣe. (Sm. 97:10) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Kí sì làwọn alàgbà, àwọn bàbá àtàwọn ìyá lè rí kọ́ lára Gómìnà Nehemáyà, Ọba Dáfídì àti Màríà ìyá Jésù? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.

KÍ NÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢÒRO LÁTI FI ARA WA SÁBẸ́ JÈHÓFÀ?

4-5. Bó ṣe wà nínú Róòmù 7:21-23, kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà?

4 Ìdí kan tó fi máa ń ṣòro fún wa láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, aláìpé sì ni wá. Torí náà, kì í fìgbà gbogbo wù wá pé ká ṣègbọràn. Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà nígbà tí wọ́n jẹ èso tó ní kí wọ́n má jẹ, èyí sì fi hàn pé tinú wọn ni wọ́n ṣe. (Jẹ́n. 3:22) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ọ̀pọ̀ kì í ka òfin Jèhófà sí torí pé tinú wọn ni wọ́n máa ń fẹ́ ṣe.

5 Kódà kì í rọrùn fáwọn tó mọ Jèhófà tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti máa ṣègbọràn sí i nígbà gbogbo. Bó ṣe rí fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà nìyẹn. (Ka Róòmù 7:21-23.) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà fẹ́ ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn bí kò tiẹ̀ rọrùn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo láti borí èrò tó lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́.

6-7. Kí ni ohun míì tó máa ń mú kó ṣòro láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Ohun míì tó lè mú kó ṣòro láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà ni àṣà ìbílẹ̀ wa tàbí ibi tá a gbé dàgbà. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ tí wọ́n sì ń ṣe tí kò bá ìlànà Jèhófà mu, kì í sì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

7 Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe rí towó ṣe. Ohun tí Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mary * kojú nìyẹn. Kó tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó dáa jù lórílẹ̀-èdè wọn ló lọ. Àwọn mọ̀lẹ́bí Mary ń fúngun mọ́ ọn pé kó gba iṣẹ́ táá máa mówó gọbọi wọlé fún un, táá sì mú kó gbayì láwùjọ. Ohun tí òun náà sì fẹ́ nìyẹn. Àmọ́, lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí òtítọ́ sì yé e, ó yí èrò rẹ̀ pa dà. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fi iṣẹ́ olówó ńlá lọ̀ mí, mo sì mọ̀ pé iṣẹ́ náà kò ní jẹ́ kí n ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́ kì í rọrùn fún mi láti kọ̀ ọ́ torí bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà. Torí náà, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa gba iṣẹ́ tó máa dí ìjọsìn mi lọ́wọ́.”—Mát. 6:24.

8. Kí la máa jíròrò báyìí?

8 A máa ṣe ara wa láǹfààní tá a bá ń fi ara wa sábẹ́ Jèhófà. Àmọ́, ìdí míì tún wà tó fi yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ ìyẹn àwọn alàgbà, àwọn bàbá àtàwọn ìyá máa fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà. Ìdí náà ni pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á ran àwọn míì lọ́wọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì táá jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká lo ọlá àṣẹ tí Jèhófà fún wa lọ́nà táá múnú rẹ̀ dùn.

OHUN TÁWỌN ALÀGBÀ LÈ KỌ́ LÁRA NEHEMÁYÀ

Ó yẹ kí ẹ̀yin alàgbà máa lọ́wọ́ nínú títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe bí Nehemáyà náà ṣe kópa nínú títún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. (Wo ìpínrọ̀ 9-11) *

9. Àwọn ìṣòro wo ni Nehemáyà kojú?

9 Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà gbé fáwọn alàgbà pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn òun. (1 Pét. 5:2) Kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, á dáa kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí Nehemáyà ṣe bá àwọn èèyàn Ọlọ́run lò. Nehemáyà ni gómìnà Júdà, torí náà ó ní ọlá àṣẹ déwọ̀n àyè kan. (Neh. 1:11; 2:7, 8; 5:14) Àmọ́ àwọn ìṣòro kan wà tí Nehemáyà kojú. Ó rí i pé àwọn èèyàn náà ń ṣe ohun tí kò bójú mu nínú tẹ́ńpìlì, wọn ò sì fún àwọn ọmọ Léfì ní ìpín wọn bí Òfin ṣe sọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Júù ò pa Sábáàtì mọ́, àwọn kan sì fẹ́ obìnrin àjèjì. Kí ni Gómìnà Nehemáyà máa wá ṣe báyìí?—Neh. 13:4-30.

10. Kí ni Nehemáyà ṣe nípa àwọn ìṣòro tó kojú?

10 Nehemáyà ò ṣi agbára rẹ̀ lò, kò sì gbé òfin tirẹ̀ kalẹ̀ fáwọn èèyàn náà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì rán àwọn èèyàn náà létí ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ. (Neh. 1:4-10; 13:1-3) Yàtọ̀ síyẹn, Nehemáyà dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn náà, wọ́n sì jọ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́.—Neh. 4:15.

11. Bó ṣe wà nínú 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8, báwo ló ṣe yẹ káwọn alàgbà máa ṣe sáwọn ará ìjọ?

11 Ìṣòro táwọn alàgbà ń kojú lè yàtọ̀ sí ti Nehemáyà, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè kọ́ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn. Wọn kì í gbéra ga, kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni wọ́n fi ń mú ìjọ. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.) Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n máa ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Andrew tó jẹ́ alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn ará sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà tó jẹ́ onínúure tó sì kóni mọ́ra. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará láti tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n bá fún wọn.” Arákùnrin Tony tóun náà ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí sọ pé: “Mo máa ń sapá láti fi ohun tó wà nínú Fílípì 2:3 sílò, torí náà mo máa ń rán ara mi létí pé àwọn míì sàn jù mí lọ. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n máa ṣe bí ọ̀gá lé àwọn ará lórí.”

12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

12 Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bí Jèhófà náà ṣe lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, ó máa ń rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè “gbé aláìní dìde látinú eruku.” (Sm. 18:35; 113:6, 7) Àní sẹ́, Jèhófà kórìíra àwọn agbéraga àtàwọn tó jọ ara wọn lójú.—Òwe 16:5.

13. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà máa ‘ṣọ́ ahọ́n wọn gidigidi’?

13 Alàgbà kan tó ń fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ “ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi,” àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn tó bá yájú sí i. (Jém. 1:26; Gál. 5:14, 15) Arákùnrin Andrew tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi kí n fìbínú sọ̀rọ̀ sẹ́ni tó bá yájú sí mi. Àmọ́ torí pé mo máa ń ronú nípa àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí n sì máa hùwà pẹ̀lẹ́.” Tí ẹ̀yin alàgbà bá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ àti ìfẹ́ bá àwọn ará sọ̀rọ̀ títí kan àwọn alàgbà bíi tiyín, ṣe lẹ̀ ń fi hàn pé ẹ fi ara yín sábẹ́ Jèhófà.—Kól. 4:6.

OHUN TÍ Ẹ̀YIN BÀBÁ LÈ KỌ́ LÁRA ỌBA DÁFÍDÌ

14. Kí ni ojúṣe ẹ̀yin bàbá nínú ìdílé, kí sì ni Jèhófà ń retí pé kẹ́ ẹ ṣe?

14 Ẹ̀yin bàbá ni Jèhófà fi ṣe olórí ìdílé, ó sì retí pé kẹ́ ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ máa tọ́ wọn sọ́nà, kẹ́ ẹ sì máa bá wọn wí. (1 Kọ́r. 11:3; Éfé. 6:4) Àmọ́, ó níbi tí àṣẹ yín mọ torí pé ẹ máa jíhìn fún Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀. (Éfé. 3:14, 15) Tí ẹ̀yin bàbá bá ń lo ipò orí yín bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ìyẹn á fi hàn pé ẹ̀ ń fi ara yín sábẹ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lẹ lè kọ́ lára Ọba Dáfídì lórí kókó yìí.

Tó o bá ń gbàdúrà, ó yẹ kí ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ rí i pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 15-16) *

15. Kí nìdí tí Ọba Dáfídì fi jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún ẹ̀yin bàbá?

15 Kì í ṣe pé Dáfídì jẹ́ olórí ìdílé nìkan, Jèhófà tún fi í ṣe olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Agbára wà lọ́wọ́ Dáfídì lóòótọ́ torí pé ọba ni. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣi agbára náà lò, ìyẹn sì mú kó ṣàṣìṣe. (2 Sám. 11:14, 15) Àmọ́, ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì gba ìbáwí Jèhófà. Ó gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà, ó sì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. Lẹ́yìn náà, ó sapá láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà. (Sm. 51:1-4) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó gba ìmọ̀ràn táwọn míì fún un títí kan àwọn obìnrin. (1 Sám. 19:11, 12; 25:32, 33) Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe rẹ̀, ó sì rí i pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé òun.

16. Ẹ̀kọ́ wo ni ẹ̀yin bàbá lè rí kọ́ lára Dáfídì?

16 Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí ẹ̀yin bàbá lè kọ́ lára Ọba Dáfídì: Má ṣi agbára tí Jèhófà fún ẹ lò. Tó o bá ṣàṣìṣe, mọ ẹ̀bi ẹ lẹ́bi, kó o sì gba ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún ẹ látinú Bíbélì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Tó o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú ìdílé ẹ, sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà, jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà lo gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìjọsìn Jèhófà ni kó o jẹ́ kó gbawájú láyé ẹ. (Diu. 6:6-9) Àpẹẹrẹ rere tó o bá fi lélẹ̀ lẹ̀bùn tó dáa jù tó o lè fún ìdílé ẹ.

OHUN TÍ Ẹ̀YIN ÌYÁ LÈ KỌ́ LÁRA MÀRÍÀ

17. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé fún ẹ̀yin ìyá?

17 Iṣẹ́ pàtàkì ni Jèhófà gbé fún ẹ̀yin ìyá, ó sì fún yín láṣẹ déwọ̀n àyè kan lórí àwọn ọmọ yín. (Òwe 6:20) Kódà, ipa kékeré kọ́ ni ìyá máa ń ní lórí ọmọ, àwọn ọmọ ò sì ní gbàgbé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ lọ́dọ̀ ìyá wọn. (Òwe 22:6) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan díẹ̀ tẹ́ ẹ lè kọ́ lára Màríà ìyá Jésù.

18-19. Kí ni ẹ̀yin ìyá lè kọ́ lára Màríà?

18 Màríà mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Ó múra tán láti fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.—Lúùkù 1:35-38, 46-55.

Ìgbà tó bá rẹ ìyá kan tàbí tí nǹkan tojú sú u gan-an ló yẹ kó sapá láti fìfẹ́ hàn sí ìdílé rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 19) *

19 Ẹ̀yin ìyá, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè kọ́ lára Màríà. Àkọ́kọ́, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ẹ sì ń gbàdúrà láyè ara yín kí àjọṣe tí ẹ̀yin fúnra yín ní pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára. Ìkejì, ẹ múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kẹ́ ẹ lè múnú Jèhófà dùn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé àwọn òbí tó máa ń tètè bínú ló tọ́ yín dàgbà, wọ́n sì máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí yín. Torí náà, ẹ lè ronú pé bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ tọ́ àwọn ọmọ yín nìyẹn. Ní báyìí tẹ́ ẹ ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe, ó lè má rọrùn láti fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀ pàápàá táwọn ọmọ yín bá ṣẹ̀ lásìkò tó ti rẹ̀ yín tẹnutẹnu. (Éfé. 4:31) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kẹ́ ẹ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́. Ìyá kan tó ń jẹ́ Lydia sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà kíkankíkan pé kí n má ṣi ọ̀rọ̀ sọ sí ọmọ mi tó bá ṣẹ̀ mí. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ṣe ni mo séra ró tí mo sì gbàdúrà sínú pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Àdúrà tí mò ń gbà ni kì í jẹ́ kí n ṣinú bí.”—Sm. 37:5.

20. Ìṣòro wo làwọn ìyá kan ní, báwo sì ni wọ́n ṣe lè borí rẹ̀?

20 Ìṣòro táwọn ìyá kan ní ni pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn. (Títù 2:3, 4) Ìdí sì ni pé inú ilé tí wọn ò ti mọ bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ ni wọ́n ti tọ́ àwọn míì dàgbà. Tó bá jẹ́ pé irú ilé bẹ́ẹ̀ lo dàgbà sí, kò di dandan pé kó o ṣe irú àṣìṣe táwọn òbí ẹ ṣe. Ìyá kan tó fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà máa kọ́ béèyàn ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ rẹ̀. Ó lè má rọrùn láti yí bó o ṣe ń ronú pa dà lóòótọ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe. Tó o bá sapá, wàá ṣe ara ẹ àti ìdílé rẹ láǹfààní.

MÁA BÁ A LỌ LÁTI FI ARA RẸ SÁBẸ́ JÈHÓFÀ

21-22. Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 65:13, 14, àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn fi ara rẹ̀ sábẹ́ Jèhófà?

21 Ọba Dáfídì mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa fi ara rẹ̀ sábẹ́ Jèhófà. Ó ní: “Àwọn ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n ń mú ọkàn yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀. A ti fi wọ́n kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ; èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.” (Sm. 19:8, 11) Lónìí, ṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere. Àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà ń “kígbe ayọ̀ torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn” wọn.—Ka Àìsáyà 65:13, 14.

22 Tó bá ń yá ẹ̀yin alàgbà, ẹ̀yin bàbá àti ẹ̀yin ìyá lára láti fi ara yín sábẹ́ Jèhófà, ìgbésí ayé yín á dùn bí oyin, ìdílé yín á láyọ̀, ìjọ Ọlọ́run á sì túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ máa múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Àbí, ṣé nǹkan míì wà tó tún dáa jùyẹn lọ?

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká fi ara wa sábẹ́ Jèhófà. A tún máa jíròrò ohun táwọn tó ní ọlá àṣẹ ìyẹn àwọn alàgbà, àwọn bàbá àtàwọn ìyá máa rí kọ́ lára Gómìnà Nehemáyà, Ọba Dáfídì àti Màríà ìyá Jésù.

^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ojú ẹni tó ń sìnrú lọ̀pọ̀ máa fi ń wo ẹni tó fi ara rẹ̀ sábẹ́ àwọn míì. Àmọ́, tọkàntọkàn làwa èèyàn Jèhófà fi ń ṣègbọràn sí i, torí náà a kì í wò ó bíi pé ṣe ló ń fipá mú wa ṣègbọràn.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Alàgbà kan àti ọmọ ẹ̀ jọ ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe; Nehemáyà ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn mí ì nígbà tí wọ́n ń tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́.

^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Bàbá kan ń gbàdúrà àtọkànwá pẹ̀lú ìdílé rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 66 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Ọmọ kan gbá géèmù fún ọ̀pọ̀ wákàtí dípò kó ṣe iṣẹ́ ilé àti iṣẹ́ ilé ìwé rẹ̀. Ó ti rẹ ìyá ẹ̀ tẹnutẹnu nígbà tó dé láti ibi iṣẹ́, síbẹ̀ ó bá a wí láì fìbínú sọ̀rọ̀.