Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35

Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Jèhófà . . . ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.”​SM. 138:6.

ORIN 48 Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Ṣàlàyé.

JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì rí ojú rere rẹ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì sọ pé Jèhófà “jìnnà sí àwọn agbéraga.” (Sm. 138:6) Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a sì fẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ wa. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? (2) Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? (3) Àwọn ìgbà wo ló lè ṣòro láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn? Bákan náà, àá rí i pé tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àá múnú Jèhófà dùn, àá sì ṣe ara wa láǹfààní.​—Òwe 27:11; Àìsá. 48:17.

OHUN TÍ Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ TÚMỌ̀ SÍ

3. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

3 Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra ẹ̀ lójú. Bíbélì fi hàn pé ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń bẹ̀rù Ọlọ́run, kì í sì í fojú pa àwọn míì rẹ́. Bákan náà, ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ.​—Fílí. 2:​3, 4.

4-5. Ṣé èèyàn lè dá ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ lójú? Kí nìdí?

4 Ìwà àwọn kan máa ń jẹ́ kó dà bíi pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Wọ́n lè máa ṣe jẹ́jẹ́, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà sì lè mú kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn míì. Síbẹ̀ kó jẹ́ pé nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, agbéraga ni wọ́n. Àmọ́ bópẹ́ bóyá, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ máa hàn sójú táyé.​—Lúùkù 6:45.

5 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti pé ẹnì kan máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, tó sì máa ń sojú abẹ níkòó kò túmọ̀ sí pé ó gbéra ga. (Jòh. 1:​46, 47) Síbẹ̀, ó yẹ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má lọ máa gbára lé ara wọn torí ẹ̀bùn àbínibí wọn. Torí náà, yálà a máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa tàbí a jẹ́ onítìjú èèyàn, gbogbo wa gbọ́dọ̀ sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò ronú pé òun sàn ju àwọn míì lọ (Wo ìpínrọ̀ 6) *

6. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:​10, kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Jèhófà lo Pọ́ọ̀lù gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, débi pé ṣe ló ń dá ìjọ sílẹ̀ láti ìlú kan dé òmíì. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó gbéṣe ju tàwọn àpọ́sítélì tó kù lọ. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò gbéra ga kò sì ronú pé òun sàn ju àwọn tó kù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó sọ pé: “Èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 15:9) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sóun ló mú kóun ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe òun. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:10.) Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ torí pé inú ìjọ yẹn kan náà làwọn kan ti ń gbéra ga bíi pé wọ́n sàn ju Pọ́ọ̀lù lọ.​—2 Kọ́r. 10:10.

Onírẹ̀lẹ̀ ni Arákùnrin Karl F. Klein tó ti fìgbà kan rí wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Báwo làwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú lóde òní ṣe fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

7 Ọ̀pọ̀ wa ló gbádùn ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Karl F. Klein, tó fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nínú ìrírí rẹ̀, Arákùnrin Klein sọ àwọn àṣìṣe tó ṣe àtàwọn ìṣòro tó kojú láìfọ̀rọ̀ pa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọdún 1922 ló kọ́kọ́ wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ torí pé ojú ń tì í, kò wàásù láti ilé dé ilé mọ́ fún odindi ọdún méjì. Nígbà tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, inú bí i lẹ́yìn tí arákùnrin kan bá a wí, ó sì di onítọ̀hún sínú. Ìgbà kan tún wà tí nǹkan ṣẹlẹ̀ sí i tó sì mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ó borí rẹ̀. Bó ti wù kó rí, ó gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ẹ ò rí i pé ó gba ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kí irú arákùnrin táwọn ará mọ̀ dáadáa bẹ́ẹ̀ tó lè sọ àwọn àṣìṣe tó ṣe láìfọ̀rọ̀ pa mọ́! Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń rántí ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Klein àti bí kò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. *

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ LẸ́MÌÍ ÌRẸ̀LẸ̀?

8. Báwo ni 1 Pétérù 5:6 ṣe jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn?

8 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé ó máa ń múnú Jèhófà dùn. Ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ sì jẹ́ kí èyí ṣe kedere. (Ka 1 Pétérù 5:6.) Nígbà tí ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn” ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Pétérù, ó sọ pé: “Bíi májèlé ni ìgbéraga rí. Ohun tó máa ń yọrí sí kì í dáa. Ànímọ́ kan tó lè mú kí ẹ̀bùn yòówù tẹ́nì kan ní dìdàkudà mọ́ ọn lára níwájú Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrẹ̀lẹ̀ lè mú kí ẹni tí ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan di ẹni tó máa wúlò fún Jèhófà. . . . Inú Ọlọ́run wa á dùn láti san ọ́ lẹ́san rere bó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.” * Kò sí àní-àní pé ohun tó dáa jù tá a lè ṣe ni pé ká múnú Jèhófà dùn.​—Òwe 23:15.

9. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń sún mọ́ ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

9 Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn, ó tún máa ń ṣe wá láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ káwọn míì sún mọ́ wa. Kí ohun tá a sọ yìí lè túbọ̀ ṣe kedere, wò ó báyìí ná: Irú èèyàn wo ni wàá fẹ́ mú lọ́rẹ̀ẹ́? Ṣé agbéraga ni àbí onírẹ̀lẹ̀? (Mát. 7:12) Ọ̀pọ̀ wa kì í fẹ́ da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó máa ń rin kinkin mọ́ èrò wọn tàbí tí kì í gba èrò àwọn míì. Lọ́wọ́ kejì, ó máa ń wù wá láti wà pẹ̀lú ẹni tó máa ń ‘báni kẹ́dùn, tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tó lójú àánú, tó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.’ (1 Pét. 3:8) Tó bá jẹ́ pé ó máa ń wù wá láti wà pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀, kò sí àní-àní pé ó máa wu àwọn náà láti wà pẹ̀lú wa tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

10. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fara da ìṣòro?

10 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, nígbà míì nǹkan kì í lọ bá a ṣe fẹ́, wọ́n sì lè fi ohun tó tọ́ sí wa dù wá. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.” (Oníw. 10:7) Nígbà míì, àwọn tó ṣiṣẹ́ kára tàbí tó lẹ́bùn tó ta yọ kì í gbayì lójú àwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́bùn làwọn èèyàn máa ń gbé gẹ̀gẹ̀. Síbẹ̀, Sólómọ́nì sọ pé á dáa ká má ṣe yọ ara wa lẹ́nu nípa ohun tá ò lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. (Oníw. 6:9) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa da ara wa láàmú táwọn nǹkan tá ò retí bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa.

ÀWỌN ÌGBÀ WO LÓ LÈ ṢÒRO LÁTI FI Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ HÀN?

Báwo ni irú nǹkan yìí ṣe lè mú kó ṣòro fún wa láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn? (Wo ìpínrọ̀ 11-12) *

11. Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá bá wa wí?

11 Ojoojúmọ́ la máa ń kojú àwọn ipò tó lè mú kó ṣòro fún wa láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ipò díẹ̀ yẹ̀ wò. Tí wọ́n bá bá wa wí. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ó gba ìgboyà kẹ́nì kan tó lè fún wa nímọ̀ràn torí àṣìṣe wa. Tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àṣìṣe náà ti kọjá ohun tá a rò. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé ká má gba ìbáwí náà. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ẹni náà tàbí ká máa bínú torí bó ṣe gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀. Àmọ́ tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a máa sapá láti ní èrò tó tọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà.

12. Òwe 27:​5, 6 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹni tó bá wa wí? Ṣàpèjúwe.

12 Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mọyì ìbáwí tí wọ́n bá fún un. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé o ti kí ọ̀pọ̀ àwọn ará lẹ́yìn ìpàdé, lẹnì kan bá fà ẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì rọra sọ fún ẹ pé oúnjẹ ti há sí ẹ léyín. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé ojú máa tì ẹ́, ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó yẹ kẹ́nì kan ti sọ fún ẹ tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, ṣé inú ẹ ò ní dùn pé ẹni náà sọ fún ẹ? Lọ́nà kan náà, ṣé kò yẹ ká mọyì ẹni tó lo ìgboyà, tó sì bá wa wí lásìkò tó tọ́. Ṣe ló yẹ ká mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, dípò ká sọ ọ́ di ọ̀tá.​—Ka Òwe 27:​5, 6; Gál. 4:16.

Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ táwọn míì bá gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan? (Wo ìpínrọ̀ 13-14) *

13. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn tí wọ́n bá fún àwọn míì láǹfààní iṣẹ́ ìsìn?

13 Táwọn míì bá gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jason sọ pé: “Tí mo bá rí i pé àwọn míì gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, mo máa ń ronú pé kí ló dé tí wọn ò fi fún mi láǹfààní yẹn?” Ṣé ìwọ náà máa ń nírú èrò yìí? Kò burú téèyàn bá ń “sapá” láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i nínú ètò Ọlọ́run. (1 Tím. 3:1) Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ ohun tá à ń rò. Torí pé tá ò bá ṣọ́ra, ìgbéraga lè bẹ̀rẹ̀ sí í ta gbòǹgbò lọ́kàn wa. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé òun lòun tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Arábìnrin kan sì lè máa sọ lọ́kàn ẹ̀ pé, ‘Ọkọ mi tóótun ju ẹni tí wọ́n fún láǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn lọ.’ Àmọ́ tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lóòótọ́, a ò ní fàyè gba irú èrò bẹ́ẹ̀.

14. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Mósè ṣe nígbà táwọn míì gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?

14 A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Mósè ṣe nígbà táwọn míì gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Mósè mọyì àǹfààní tó ní láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà yan àwọn míì láti bá Mósè ṣiṣẹ́, ṣé Mósè jowú wọn? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀. (Nọ́ń. 11:​24-29) Mósè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì gbà káwọn míì máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà. (Ẹ́kís. 18:​13-24) Èyí mú kó rọrùn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti tètè yanjú àwọn ẹjọ́ wọn torí pé Mósè nìkan kọ́ ló ń ṣèdájọ́. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ire àwọn èèyàn ló jẹ Mósè lọ́kàn kì í ṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fáwa náà lónìí! Ká rántí pé ká tó lè wúlò fún Jèhófà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa gbọ́dọ̀ ju ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní lọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.”​—Sm. 138:6.

15. Ìyípadà wo ló ti dé bá àwọn kan?

15 Tí ipò wa bá yí pa dà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ètò Ọlọ́run ti yí iṣẹ́ wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2014, ètò Ọlọ́run fún gbogbo àwọn alábòójútó agbègbè àtàwọn ìyàwó wọn ní iṣẹ́ míì. Lọ́dún yẹn kan náà, ètò Ọlọ́run sọ pé táwọn alábòójútó àyíká bá ti pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, kí wọ́n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Táwọn arákùnrin tó jẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá sì ti pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún, wọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ni ètò Ọlọ́run ti ní kí wọ́n lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àìlera, ojúṣe ìdílé tàbí àwọn ìṣòro míì ti mú káwọn míì fi iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀.

16. Báwo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí ipò wọn yí pa dà ṣe ń fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

16 Kò rọrùn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí láti mú ara wọn bá ìyípadà náà mu. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan ti wà lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Torí náà, kò rọrùn rárá fún wọn láti kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn tí wọ́n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, iṣẹ́ tuntun tí wọ́n gbà mọ́ wọn lára. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ohun pàtàkì tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà làwọn ya ara wọn sí mímọ́ fún, kì í ṣe fún iṣẹ́ kan tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. (Kól. 3:23) Inú wọn sì ń dùn láti máa fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbà. Ṣe ni wọ́n “kó gbogbo àníyàn [wọn] lọ sọ́dọ̀” Jèhófà, torí ó dá wọn lójú pé á bójú tó wọn.​—1 Pét. 5:​6, 7.

17. Kí nìdí tí inú wa fi dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

17 A mà dúpẹ́ o pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá ṣe ara wa láǹfààní, àá sì ṣe àwọn míì náà láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, á mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run. Bí Jèhófà tiẹ̀ jẹ́ “Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ,” inú wa dùn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì mọyì wọn gan-an!​—Àìsá. 57:15.

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wà lára àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ ká ní. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Kí sì nìdí tó fi máa ń ṣòro láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí ipò nǹkan bá yí pa dà fún wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo àpilẹ̀kọ náà “Jehofah Ti Bá Mi Lò Pẹlu Èrè-Ẹ̀san” nínú Ile-Iṣọ Naa April 15, 1985.

^ ìpínrọ̀ 53 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà pẹ̀lú àwọn ará nílé Kristẹni kan, ó sì ń bá àwọn ọmọdé ṣeré

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Arákùnrin àgbàlagbà kan gba ìmọ̀ràn Bíbélì tí arákùnrin míì tí kò tó o lọ́jọ́ orí fún un.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN OJÚ ÌWÉ: Arákùnrin àgbàlagbà náà ò jowú arákùnrin tó kéré sí i yẹn nígbà tó gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ.