Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39

‘Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn’

‘Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn’

Wò ó! mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn, tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, . . . wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”​ÌFI. 7:9.

ORIN 60 Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àpọ́sítélì Jòhánù lọ́wọ́ ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni?

NÍ ỌWỌ́ ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nǹkan ò dẹrùn rárá fún àpọ́sítélì Jòhánù. Ìdí ni pé ó ti darúgbó, ó sì tún wà lẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun nìkan ló ṣẹ́ kù lára àwọn àpọ́sítélì. (Ìfi. 1:9) Ó mọ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà ti ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà, wọ́n sì ti dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. Ńṣe ló dà bíi pé àwọn ọ̀tá ti fẹ́ pa ìsìn tòótọ́ run pátápátá.​—Júùdù 4; Ìfi. 2:​15, 20; 3:​1, 17.

Àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n wọ aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ sì wà lọ́wọ́ wọn (Wo ìpínrọ̀ 2)

2. Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 7:​9-14, ìran tó ń múnú ẹni dùn wo ni Jòhánù rí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

2 Àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ yẹn ni Jòhánù rí ìran àgbàyanu kan. Nínú ìran náà, áńgẹ́lì kan sọ fáwọn áńgẹ́lì mẹ́rin míì pé kí wọ́n má tíì tú atẹ́gùn ìpọ́njú ńlá tí wọ́n dì mú sílẹ̀ títí dìgbà tí wọ́n á fi gbé èdìdì lé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan. (Ìfi. 7:​1-3) Àwùjọ àwọn tí wọ́n máa gbé èdìdì lé yìí ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Lúùkù 12:32; Ìfi. 7:4) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jòhánù wá mẹ́nu kan àwùjọ míì, wọ́n pọ̀ débi tó fi pariwo pé: “Wò ó!” tó fi hàn pé ohun tó rí yà á lẹ́nu gan-an. Kí ni Jòhánù rí? Ó rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn, tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ka Ìfihàn 7:​9-14.) Ẹ wo bí inú Jòhánù ṣe máa dùn tó nígbà tó mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn á máa ṣe ìjọsìn tòótọ́!

3. (a) Kí nìdí tí ìran yìí á fi mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Kò sí àní-àní pé ìran yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ Jòhánù túbọ̀ lágbára. Tó bá rí bẹ́ẹ̀ fún un, mélòómélòó àwa tá à ń gbé lásìkò tí ìran náà ń ní ìmúṣẹ! Àsìkò wa yìí ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń rọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó nírètí àtila ìpọ́njú ńlá já sínú ayé tuntun kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ àwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn ní ohun tó lé ní ọgọ́rin (80) ọdún sẹ́yìn. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò kókó méjì míì nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ náà: (1) bí wọ́n ṣe pọ̀ tó àti (2) bó ṣe jẹ́ pé ibi gbogbo láyé ni wọ́n ti wá. Ó dájú pé àwọn kókó yìí máa mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tó wà nínú àwùjọ yìí túbọ̀ lágbára.

IBO NI OGUNLỌ́GỌ̀ ÈÈYÀN NÁÀ MÁA GBÉ?

4. Òtítọ́ wo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò mọ̀, àmọ́ kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́?

4 Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kì í fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ni pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn onígbọràn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́r. 4:​3, 4) Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọ́ni pé ọ̀run ni gbogbo èèyàn rere ń lọ lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Àmọ́ ohun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéréje tó ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti ọdún 1879 fi ń kọ́ni yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè, inú ẹ̀ sì ni ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn onígbọràn máa gbé títí láé, kì í ṣe ọ̀run. Síbẹ̀, òye wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere nípa àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.​—Mát. 6:10.

5. Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000)?

5 Ìwádìí táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kí wọ́n lóye pé àwọn kan tí Jèhófà “rà látinú ayé” máa jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ìfi. 14:3) Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) làwọn Kristẹni yìí, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì fìtara ṣiṣẹ́ Jèhófà nígbà tí wọ́n wà láyé. Àmọ́ kí lèrò wọn nípa ogunlọ́gọ̀ náà?

6. Kí lèrò àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa ogunlọ́gọ̀ náà?

6 Nínú ìran yẹn, Jòhánù rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfi. 7:9) Èyí mú káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn gbà pé ọ̀run ni ogunlọ́gọ̀ náà ń lọ bíi tàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). Tó bá jẹ́ pé ọ̀run ni àwùjọ méjèèjì yìí ń lọ, kí ni ìyàtọ̀ láàárín wọn? Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ronú pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Kristẹni tí wọn ò ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀ nígbà tí wọ́n wà láyé ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn kan lára wọn ṣì ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run déwọ̀n àyè kan, síbẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára débi tí wọ́n á fi jọba pẹ̀lú Jésù. Torí pé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run ò jinlẹ̀ tó, wọ́n á lè dúró níwájú ìtẹ́, àmọ́ wọn ò ní láǹfààní láti jókòó lórí ìtẹ́.

7. Kí lèrò àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, kí sì ni wọ́n rò nípa àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì?

7 Àwọn wo ló máa gbé lórí ilẹ̀ ayé? Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn gbà pé lẹ́yìn táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) àti ogunlọ́gọ̀ náà bá lọ sọ́run, Jèhófà máa fún ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì láǹfààní láti wà lábẹ́ àkóso Kristi, wọ́n á sì gbádùn ìbùkún tí ìṣàkóso rẹ̀ máa mú wá sórí ilẹ̀ ayé. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn gbà pé ẹ̀yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá bẹ̀rẹ̀ làwọn tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé á bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn tó bá fara mọ́ ìlànà Jèhófà á láǹfààní àtimáa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ Jèhófà máa pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ run. Wọ́n gbà pé Ọlọ́run máa yan àwọn kan láti jẹ́ “olórí” nígbà yẹn àti pé á jí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì dìde (ìyẹn àwọn tó kú ṣáájú Jésù) àwọn náà á sì jẹ́ “olórí.” Lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí, àwọn olórí yìí máa lọ sọ́run.​—Sm. 45:16.

8. Àwùjọ mẹ́ta wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé ó wà?

8 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn gbà pé àwùjọ mẹ́ta ló wà: (1) àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá Jésù jọba lọ́run; (2) ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nítara, àmọ́ tó máa láǹfààní láti dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà; àti (3) ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó máa wà láyé, tí wọ́n á sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. * Bó ti wù kó rí, nígbà tí àsìkò tó lójú Jèhófà, ó mú kí òye wọn túbọ̀ ṣe kedere lórí kókó yìí.​—Òwe 4:18.

ÌMỌ́LẸ̀ ÒTÍTỌ́ TÚBỌ̀ Ń MỌ́LẸ̀ SÍ I

Ní àpéjọ agbègbè tí wọ́n ṣe lọ́dún 1935, ọ̀pọ̀ tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé ló ṣèrìbọm (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. (a) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà”? (b) Kí nìdí tí òye tá a ní báyìí nípa Ìfihàn 7:9 fi bọ́gbọ́n mu?

9 Lọ́dún 1935, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wà nínú ìran tí Jòhánù rí. A rí i pé kò dìgbà tí ogunlọ́gọ̀ náà bá wà lọ́run kí wọ́n tó lè “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ilẹ̀ ayé ni wọ́n wà, wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́” náà ní ti pé wọ́n gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, wọ́n sì fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. (Àìsá. 66:1) Bákan náà, wọ́n dúró “níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ní ti pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù. Àpẹẹrẹ míì lohun tó wà nínú Mátíù 25:​31, 32 tó sọ pé, “a máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè” títí kan àwọn ẹni burúkú “jọ síwájú” ìtẹ́ Jésù. Ó ṣe kedere pé ayé yìí làwọn orílẹ̀-èdè wà kì í ṣe ọ̀run. Torí náà, àtúnṣe tá a ṣe sí èrò tá a ní tẹ́lẹ̀ bọ́gbọ́n mu. Ó jẹ́ ká rí ìdí tí Bíbélì ò fi sọ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà máa lọ sọ́run. Àwùjọ kan ṣoṣo ni Bíbélì sọ pé ó máa lọ sọ́run, ìyẹn sì ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa wà pẹ̀lú Jésù láti “ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.”​—Ìfi. 5:10.

10. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí ogunlọ́gọ̀ náà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀ ṣáájú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

10 Àtọdún 1935 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lóye pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí Jòhánù rí nínú ìran. Kí ogunlọ́gọ̀ náà tó lè la ìpọ́njú ńlá já, wọ́n gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀ kí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi tó bẹ̀rẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó lágbára, ìyẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n lè “bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀” ṣáájú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.​—Lúùkù 21:​34-36.

11. Kí ló mú kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ronú pé àwọn olóòótọ́ kan máa lọ sọ́run lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

11 Kí ló mú kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ronú pé àwọn olóòótọ́ kan máa lọ sọ́run lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi? Inú Ilé Ìṣọ́ February 15, 1913 ni wọ́n ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pé, ‘Báwo ni àwọn olóòótọ́ ìgbàanì ṣe máa wà lórí ilẹ̀ ayé, táwọn Kristẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ nítara á wá lọ sọ́run?’ Èrò méjì tí kò tọ́ ló mú kí wọ́n ronú bẹ́ẹ̀: (1) wọ́n ronú pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà máa lọ sọ́run; (2) àwọn Kristẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ nítara ló máa para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ náà.

12-13. Kí làwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà mọ̀ nípa èrè tí wọ́n máa gbà?

12 Bá a ṣe sọ, àtọdún 1935 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lóye pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí Jòhánù rí nínú ìran ló máa la Amágẹ́dọ́nì já. Wọ́n máa “wá látinú ìpọ́njú ńlá náà” lórí ilẹ̀ ayé níbí, wọ́n á sì máa “ké jáde pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.’ ” (Ìfi. 7:​10, 14) Bákan náà, Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó nírètí àtigbé lọ́run gba ‘ohun tó dáa ju’ ti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì. (Héb. 11:40) Ìyẹn ló mú káwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n sin Jèhófà, kí wọ́n sì máa retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìrètí tí ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ní ń múnú wọn dùn. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló ń pinnu ibi táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti máa gba èrè wọn, yálà ní ọ̀run tàbí láyé. Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ náà gbà pé èrè yòówù káwọn ní, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà nípasẹ̀ ìràpadà Jésù Kristi ló mú kó ṣeé ṣe.​—Róòmù 3:24.

WỌ́N PỌ̀ GAN-AN

14. Lẹ́yìn ọdún 1935, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi ń ṣe kàyéfì nípa bí àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ṣe máa di ogunlọ́gọ̀?

14 Lẹ́yìn tí òye tá a ní nípa ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ṣe kedere lọ́dún 1935, ọ̀pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa bí àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ṣe máa di ogunlọ́gọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Arákùnrin Ronald Parkin nígbà tí òye wa ṣe kedere nípa ogunlọ́gọ̀ náà. Ó sọ pé: “Nígbà yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56,000) làwọn akéde tó wà kárí ayé, ẹni àmì òróró sì ni púpọ̀ nínú wọn. Torí náà, kò jọ pé àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé tó ogunlọ́gọ̀.”

15. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ náà ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i?

15 Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ètò Ọlọ́run rán àwọn míṣọ́nnárì lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1968, a bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn àlàyé rẹ̀ rọrùn lóye, ó sì mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run. Láàárín ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, ohun tó ju ìdajì mílíọ̀nù èèyàn ló ṣèrìbọmi. Bí agbára Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe ń dín kù ní Látìn Amẹ́ríkà àti láwọn orílẹ̀-èdè míì, tí ìjọba sì ń mú ìfòfindè tó wà lórí iṣẹ́ wa kúrò ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ń rọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run. (Àìsá. 60:22) Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, onírúurú ìtẹ̀jáde ni ètò Ọlọ́run ti ṣe káwọn èèyàn lè túbọ̀ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Kò sí àní-àní pé àwọn èèyàn yìí ti di ogunlọ́gọ̀ lóòótọ́, torí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ báyìí.

OGUNLỌ́GỌ̀ LÁTI ONÍRÚURÚ ORÍLẸ̀-ÈDÈ

16. Ibo ni ogunlọ́gọ̀ náà ti máa wá?

16 Jòhánù sọ nínú ìran yẹn pé ogunlọ́gọ̀ náà máa wá “látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n.” Wòlíì Sekaráyà náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fara jọ èyí, ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ yẹn, ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò di aṣọ Júù kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: ‘A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’ ”​—Sek. 8:23.

17. Kí là ń ṣe tó mú kó rọrùn fáwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè láti mọ Jèhófà?

17 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kí àwọn èèyàn látinú gbogbo èdè tó lè di ara ogunlọ́gọ̀ náà, a gbọ́dọ̀ máa wàásù ní ọ̀pọ̀ èdè. Ohun tó lé ní àádóje (130) ọdún báyìí la ti ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí onírúurú èdè. Lónìí, àwa là ń ṣiṣẹ́ ìtumọ̀ tó gbòòrò jù lọ láyé torí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè là ń tú àwọn ìwé wa sí. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìyanu ńlá ni Jèhófà ń gbé ṣe lónìí bó ṣe ń kó àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè jọ. Torí pé Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì ti wà lónírúurú èdè, ó ti ṣeé ṣe fún ogunlọ́gọ̀ náà láti máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá. Kódà ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fìtara wàásù, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an. Ẹ ò rí i pé ìyẹn mórí ẹni wú!​—Mát. 24:14; Jòh. 13:35.

OHUN TÍ ÌRAN YÌÍ TÚMỌ̀ SÍ FÚN WA

18. (a) Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 46:​10, 11, kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé Jèhófà mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa ogunlọ́gọ̀ náà ṣẹ? (b) Kí nìdí táwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé ò fi ronú pé Jèhófà bu àwọn kù?

18 Inú wa dùn gan-an bá a ṣe ń rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ní ìmúṣẹ! Kò sì yà wá lẹ́nu pé ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ. (Ka Àìsáyà 46:​10, 11.) Àwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ yìí ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìrètí tó fún wọn. Wọn kì í ronú pé Jèhófà bu àwọn kù torí pé àwọn ò sí lára àwọn ẹni àmì òróró tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí, síbẹ̀ tí wọn ò sí lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) náà. Àpẹẹrẹ kan ni Jòhánù Arinibọmi. (Mát. 11:11) Àpẹẹrẹ míì ni Dáfídì. (Ìṣe 2:34) Àwọn olóòótọ́ yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì ni Jèhófà máa jí dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn pátá títí kan àwọn ogunlọ́gọ̀ náà máa láǹfààní láti fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àwọn sì fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀.

19. Kí la máa ṣe tá a bá lóye ìran tí Jòhánù rí nípa ogunlọ́gọ̀ náà?

19 Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Jèhófà máa kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ níṣọ̀kan. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé la máa wà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà lára ogunlọ́gọ̀ tó jẹ́ ara “àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jèhófà máa mú kí ìpọ́njú ńlá tó sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀, á sì pa àwọn ìjọba ayé yìí run títí kan àwọn ẹ̀sìn tó ń fayé ni àwọn èèyàn lára. Ẹ wo àǹfààní àgbàyanu táwọn ogunlọ́gọ̀ náà máa ní, wọ́n á máa sin Jèhófà títí láé lórí ilẹ̀ ayé!​—Ìfi. 7:14.

ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìran alásọtẹ́lẹ̀ tí Jòhánù rí nípa “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” Kò sí àní-àní pé ìran yìí máa mú kí ìgbàgbọ́ gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ yẹn túbọ̀ lágbára.

^ ìpínrọ̀ 8 Wo ìwé Jehovah’s Witnesses​—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 159 sí 163.