Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46

Bí Jèhófà Ṣe Ń Jẹ́ Ká Fara Dà Á Ká Sì Máa Láyọ̀

Bí Jèhófà Ṣe Ń Jẹ́ Ká Fara Dà Á Ká Sì Máa Láyọ̀

“Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín, ó sì máa dìde láti ṣàánú yín.”—ÀÌSÁ. 30:18.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. (a) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń wu Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́?

 JÈHÓFÀ máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ó sì tún ń jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń sìn ín. Báwo ló ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Báwo la ṣe lè jàǹfààní àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́ ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì, ìyẹn ni pé ṣé ó máa ń wu Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́?

2 Ọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù máa jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?” (Héb. 13:6) Ìwé ìwádìí kan sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí, ó ní ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ nípa ẹnì kan tó sáré lọ ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ń sunkún pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Torí náà, fojú inú wo bí Jèhófà ṣe ń tètè ran ẹni tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. Ó dájú pé àpèjúwe yìí máa jẹ́ kó o gbà pé Olùrànlọ́wọ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń wù ú láti tètè ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, tí Jèhófà bá ràn wá lọ́wọ́, ó máa ń jẹ́ ká fara da ìṣòro wa, ká sì máa láyọ̀.

3. Ọ̀nà mẹ́ta wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ká sì máa láyọ̀?

3 Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ká sì máa láyọ̀? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ìwé Àìsáyà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ní kí Àìsáyà kọ ló kan àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ tó yé àwa èèyàn dáadáa ni Àìsáyà sábà máa ń lò láti fi ṣàlàyé ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Àìsáyà orí ọgbọ̀n (30). Nínú orí yìí, Àìsáyà lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń mú kí nǹkan yéni nígbà tó ń ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń ran àwa èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́, (1) ó sọ pé Jèhófà máa tẹ́tí sí wa, ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa, (2) ó máa ń tọ́ wa sọ́nà àti (3) ó máa ń ṣe àwọn nǹkan rere fún wa báyìí, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́.

JÈHÓFÀ MÁA Ń TẸ́TÍ SÍ WA

4. (a) Irú èèyàn wo ni Jèhófà sọ pé àwọn Júù ìgbà ayé Àìsáyà jẹ́, kí ni Jèhófà sì jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wọn? (b) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fáwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára wọn? (Àìsáyà 30:18, 19)

4 Nínú ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Àìsáyà orí 30, Jèhófà pe àwọn Júù ní “àwọn alágídí ọmọ” tó ń “dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.” Ó tún sọ nípa wọn pé: ‘Ọlọ̀tẹ̀ èèyàn tí kò fẹ́ gbọ́ òfin Jèhófà ni wọ́n.’ (Àìsá. 30:1, 9) Torí pé àwọn èèyàn náà kọ̀ láti gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu, Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ kí àjálù dé bá wọn. (Àìsá. 30:5, 17; Jer. 25:8-11) Bó sì ṣe rí nìyẹn torí àwọn ará Bábílónì kó wọn lẹ́rú lọ sígbèkùn. Àmọ́ àwọn Júù kan wà lára wọn tó jẹ́ olóòótọ́, Àìsáyà sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìrètí wà fún wọn. Ó sọ fún wọn pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Jèhófà máa gbà wọ́n sílẹ̀. (Ka Àìsáyà 30:18, 19.) Ohun tí Jèhófà sì ṣe nìyẹn. Ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì. Àmọ́ kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ló gbà wọ́n sílẹ̀. Gbólóhùn náà “Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín” fi hàn pé àkókò díẹ̀ máa kọjá kí Jèhófà tó gba àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀. Kódà, àádọ́rin (70) ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbèkùn Bábílónì kó tó di pé Jèhófà gba àwọn tó kù sílẹ̀ láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (Àìsá. 10:21; Jer. 29:10) Nígbà tí wọ́n pa dà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn, ẹkún wọn dayọ̀.

5. Kí ni Àìsáyà 30:19 fi dá wa lójú?

5 Lónìí, ohun tí Àìsáyà sọ fáwọn èèyàn náà lè tù wá nínú, ó ní: “Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́.” (Àìsá. 30:19) Àìsáyà fi dá wa lójú pé Jèhófà máa tẹ́tí sí wa tá a bá kígbe pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó sì máa tètè gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Àìsáyà tún sọ pé: “Ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó dájú tí Àìsáyà sọ yìí rán wa létí pé ó máa ń wu Bàbá wa ọ̀run láti ran àwọn tó bá ń ké pè é lọ́wọ́. Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ yìí ló ń jẹ́ ká lè máa fara dà á, ká sì máa láyọ̀.

6. Báwo lohun tí Àìsáyà sọ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

6 Nǹkan míì wo ni Àìsáyà 30:19 fi dá wa lójú nípa àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà? Ó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Láwọn ẹsẹ tó ṣáájú nínú Àìsáyà orí 30, Àìsáyà lo ọ̀rọ̀ náà “yín” láti fi hàn pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀, àmọ́ ní ẹsẹ 19, ó lo “ọ” láti fi hàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lòun ń bá sọ̀rọ̀. Àìsáyà sọ pé: “O ò ní sunkún rárá. Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ”; “ó máa dá lóhùn.” Torí pé Jèhófà Bàbá wa nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ ẹ̀, kò ní sọ fún ẹnikẹ́ni nínú wa tó níṣòro pé “O jẹ́ ṣara gírí bíi tẹ̀gbọ́n ẹ tàbí bíi ti àbúrò ẹ.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń bójú tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ó sì ń gbọ́ àdúrà wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Sm. 116:1; Àìsá. 57:15.

Kí ni Àìsáyà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ [kí Jèhófà] sinmi rárá”? (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Báwo ni Àìsáyà àti Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa gbàdúrà léraléra?

7 Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó yọ wá nínú ìṣòro kan tó ń bá wa fínra, ó lè jẹ́ ohun tó máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kó fún wa lókun ká lè fara dà á. Tí Jèhófà ò bá mú ìṣòro náà kúrò nígbà tá a rò pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé ká máa gbàdúrà sí i léraléra pé kó fún wa lókun ká lè máa fara dà á nìṣó. Ohun tó sì rọ̀ wá pé ká ṣe nìyẹn. Ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Má ṣe jẹ́ [kí Jèhófà] sinmi rárá.” (Àìsá. 62:7) Kí ni gbólóhùn yìí túmọ̀ sí? Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà lemọ́lemọ́ débi tó fi máa dà bíi pé a ò jẹ́ kó sinmi. Ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ yìí jẹ́ ká rántí àwọn àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àdúrà ní Lúùkù 11:8-10, 13. Jésù rọ̀ wá níbẹ̀ pé tá a bá ń gbàdúrà, ká máa “fi ìgboyà béèrè léraléra” ká sì “máa béèrè” pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́.

JÈHÓFÀ MÁA Ń TỌ́ WA SỌ́NÀ

8. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Àìsáyà 30:20, 21 ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́?

8 Ka Àìsáyà 30:20, 21. Nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì dó ti Jerúsálẹ́mù fún ọdún kan àtààbọ̀, ojú pọ́n wọn débi pé wọ́n fi ìyà ṣe oúnjẹ, wọ́n sì fi ṣomi mu. Àmọ́ ní ẹsẹ 20 àti 21, Jèhófà ṣèlérí fáwọn Júù yẹn pé tí wọ́n bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì yí ìwà wọn pa dà, òun máa gbà wọ́n sílẹ̀. Àìsáyà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ni “Olùkọ́ [wọn] Atóbilọ́lá,” ó sì fi dá wọn lójú pé Jèhófà máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn Ẹ̀ lọ́nà tó fẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹ nígbà tí wọ́n dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn. Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́ lòun jẹ́ Olùkọ́ wọn Atóbilọ́lá torí pé ó tọ́ wọn sọ́nà, ó sì jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí láti mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà lónìí, inú tiwa náà ń dùn pé Jèhófà ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá.

9. Sọ ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà tọ́ wa sọ́nà lónìí.

9 Lẹ́yìn tí Àìsáyà pe Jèhófà ní Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, ó pè wá ní akẹ́kọ̀ọ́, ó sì sọ pé ọ̀nà méjì ni Jèhófà ń gbà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Àkọ́kọ́, Àìsáyà sọ pé: “O sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.” Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Àìsáyà fi Jèhófà wé Olùkọ́ kan tó dúró níwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Torí náà, a mọyì àǹfààní tá a ní pé Jèhófà ń kọ́ wa lónìí. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa? Ó ń kọ́ wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Inú wa dùn pé Jèhófà ń lo ètò rẹ̀ láti máa tọ́ wa sọ́nà. Àwọn ìtọ́sọ́nà tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ agbègbè, èyí tá à ń kà nínú àwọn ìwé wa, tá à ń gbọ́ lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW àtàwọn ọ̀nà míì máa ń jẹ́ ká fara dà á nígbà ìṣòro, ó sì ń mú ká máa láyọ̀.

10. Báwo ni etí wa ṣe ń “gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn [wa]”?

10 Àìsáyà sọ ọ̀nà kejì tí Jèhófà ń gbà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó ní: “Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ.” Wòlíì Àìsáyà fi Jèhófà wé olùkọ́ kan tó ń tẹ̀ lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lẹ́yìn, tó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, tó sì ń sọ ibi tí wọ́n máa gbà kí wọ́n má bàa ṣìnà. Lónìí, àwa náà ń gbọ́ ohùn Ọlọ́run lẹ́yìn wa. Lọ́nà wo? Látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ti wà tipẹ́tipẹ́. Torí náà, tá a bá ń ka Bíbélì, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti ẹ̀yìn wa.—Àìsá. 51:4.

11. Tá a bá fẹ́ máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da ìṣòro wa, nǹkan méjì wo ló yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?

11 Báwo la ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kíyè sí i pé Àìsáyà sọ ọ̀nà méjì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó ní “èyí ni ọ̀nà.” Ìkejì, ó ní “ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Àìsá. 30:21) Ká kàn mọ “ọ̀nà” tó yẹ ká máa rìn nìkan ò tó, ó tún yẹ ká máa “rìn nínú rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àlàyé tí ètò rẹ̀ ń ṣe máa ń jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò. Torí náà, tá a bá fẹ́ máa fara dà á nìṣó, ká sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan méjèèjì tá a sọ yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa.

JÈHÓFÀ MÁA Ń BÙ KÚN WA

12. Àwọn nǹkan rere wo ni Àìsáyà 30:23-26 sọ pé Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀?

12 Ka Àìsáyà 30:23-26. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí àwọn Júù tó pa dà sí Ísírẹ́lì lára lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nígbèkùn ní Bábílónì? Jèhófà bù kún wọn gan-an torí ó pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn àtohun táá jẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun nìṣó. Jèhófà bù kún àwọn èèyàn ẹ̀ torí ó pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ fún wọn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà ṣe fún wọn ni pé ó rí i pé òun fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wọn ní àbọ́yó bí wọ́n ṣe ń mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò díẹ̀díẹ̀. Àwọn ìbùkún tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Jèhófà báyìí pọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ 26, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Àìsá. 60:2) Torí pé Jèhófà bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń sìn ín, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n lókun “torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn” wọn.—Àìsá. 65:14.

13. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò ṣe ṣẹ lákòókò wa yìí?

13 Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò kàn wá lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Lọ́nà wo? Látọdún 1919 S.K., ọ̀pọ̀ èèyàn ti bọ́ nínú ìgbèkùn Bábílónì ńlá, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé. Wọ́n sì ti wà níbi tó dáa ju Ilẹ̀ Ìlérí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Inú Párádísè tẹ̀mí ni wọ́n wà báyìí. (Àìsá. 51:3; 66:8) Àmọ́, kí ni Párádísè tẹ̀mí?

14. Kí ni Párádísè tẹ̀mí, àwọn wo ló sì ń gbébẹ̀ lónìí? (Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.)

14 Àtọdún 1919 S.K. làwọn ẹni àmì òróró ti ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí. b Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tó nírètí láti gbé ayé, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” náà ti wá sínú Párádísè tẹ̀mí yìí, àwọn náà sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Jòh. 10:16; Àìsá. 25:6; 65:13.

15. Ibo ni Párádísè tẹ̀mí wà lónìí?

15 Ibo ni Párádísè tẹ̀mí wà lónìí? Kò síbi tá a dé láyé tá ò ní ráwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà. Torí náà, Párádísè tẹ̀mí wà kárí ayé. Ibi yòówù ká máa gbé, àwa náà lè wà nínú Párádísè tẹ̀mí yìí tá a bá ti pinnu pé ìjọsìn mímọ́ làá máa ṣe.

Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe kí Párádísè tẹ̀mí wa lè máa dáa sí i? (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká máa rí bí Párádísè tẹ̀mí wa ṣe lẹ́wà tó?

16 Ká lè máa gbádùn Párádísè tẹ̀mí, ara ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká mọyì àwọn ará wa kárí ayé. Báwo la ṣe lè ṣe é? Máa wo ibi táwọn ará tó wà nínú ìjọ dáa sí dípò kó o máa wo ibi tí wọ́n kù sí. (Jòh. 17:20, 21) Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Wo àpèjúwe yìí ná. Tó o bá wà nínú ọgbà kan tó rẹwà, oríṣiríṣi igi lo máa rí níbẹ̀. Lọ́nà kan náà, a lè fi oríṣiríṣi èèyàn tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí láwọn ìjọ wa wé oríṣiríṣi igi tó wà nínú ọgbà tó rẹwà yẹn. (Àìsá. 44:4; 61:3) Ohun tó yẹ ká máa wò ni bí “igbó” kan ṣe rẹwà tó, kì í ṣe kùdìẹ̀-kudiẹ tó wà lára “igi” kọ̀ọ̀kan inú igbó náà. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí kùdìẹ̀-kudiẹ wa tàbí tàwọn ará wa má jẹ́ ká rí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa kárí ayé.

17. Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe kí ìjọ lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan?

17 Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe kí ìjọ lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan? Ó yẹ ká jẹ́ ẹni àlàáfíà. (Mát. 5:9; Róòmù 12:18) Gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn ará inú ìjọ là ń mú kí Párádísè tẹ̀mí wa dáa sí i. Ká máa rántí pé Jèhófà ló pe gbogbo àwọn tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí láti wá máa ṣe ìjọsìn mímọ́. (Jòh. 6:44) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó tó bá rí i tá à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn ẹ̀ lè máa pọ̀ sí i!—Àìsá. 26:3; Hág. 2:7.

18. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa wọn, kí sì nìdí?

18 Jèhófà máa ń ṣe nǹkan rere fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, àmọ́ báwo la ṣe lè jàǹfààní àwọn nǹkan rere yìí? Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, ó máa jẹ́ ká láwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, ó sì máa jẹ́ ká ní “ìfẹ́ ará” àti “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa]” nínú ìjọ. (Róòmù 12:10) Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, á dá wa lójú pé òun ló yẹ ká máa sìn títí láé. Àwọn nǹkan yìí lá jẹ́ ká máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó báyìí.

A PINNU PÉ ÀÁ MÁA FARA DÀ Á NÌṢÓ

19. (a) Kí ni Àìsáyà 30:18 jẹ́ kó dá wa lójú? (b) Kí lá jẹ́ ká máa fara dà á, ká sì máa láyọ̀?

19 Jèhófà “máa dìde” nítorí wa nígbà tó bá fẹ́ pa ayé búburú yìí run. (Àìsá. 30:18) Ó dá wa lójú pé “Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo” ni Jèhófà, kò sì ní jẹ́ kí ọjọ́ tó dá pé òun máa pa ayé búburú Sátánì yìí run kọjá láì ṣe nǹkan kan. (Àìsá. 25:9) Torí náà, à ń fi sùúrù dúró de ọjọ́ tí Jèhófà máa gbà wá là. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa mọyì àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà, àá máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, àá sì máa ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á, ká sì máa fayọ̀ sìn ín nìṣó.

ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà ń gbà ran àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro, ká sì máa láyọ̀. A máa gbé ìwé Àìsáyà orí ọgbọ̀n (30) yẹ̀ wò, ká lè mọ nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà máa ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Bá a ṣe ń gbé orí Bíbélì yìí yẹ̀ wò, a máa rán wa létí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa báyìí àtèyí tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.

b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Párádísè Tẹ̀mí” ni ibi tí ọkàn àwa èèyàn Jèhófà ti balẹ̀, tá a sì ń jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Nínú Párádísè tẹ̀mí yìí, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àtàwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì, tí kò sì sí ẹ̀kọ́ èké kankan nínú wọn. Yàtọ̀ síyẹn, à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń fún wa láyọ̀. Àjọṣe tó dáa tún wà láàárín àwa àti Jèhófà, àlàáfíà sì wà láàárín àwa àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ìyẹn sì ń mú ká láyọ̀. Ìgbà tá a wọnú Párádísè tẹ̀mí ni ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé e.