Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Iṣẹ́ Jèhófà Ni Mo Fẹ́ Fayé Mi Ṣe”

“Iṣẹ́ Jèhófà Ni Mo Fẹ́ Fayé Mi Ṣe”

A ṢẸ̀ṢẸ̀ bẹ àwùjọ àwọn ará kan wò tán lábúlé Granbori tó wà láàárín igbó kìjikìji lórílẹ̀-èdè Suriname. La bá juwọ́ sí wọn pé, ó dàbọ̀ o! Lẹ́yìn náà, ọkọ̀ ojú omi wa gbéra lórí Odò Tapanahoni, a sì ń lọ. Nígbà tó yá, ọkọ̀ wa gba ibi tí odò náà ti ń yára ṣàn gan-an, ni ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà bá gbá àpáta. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iwájú ọkọ̀ náà rì wọmi, bá a ṣe wọ abẹ́ omi lọ nìyẹn. Ẹ̀rù bà mí gan-an torí mi ò mọ bí wọ́n ṣe ń lúwẹ̀ẹ́! Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, mo ti fi ọ̀pọ̀ ọdún wọ ọkọ̀ ojú omi lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká tí mò ń ṣe!

Kí n tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún yín, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

A bí mi lọ́dún 1942 ní erékùṣù Curaçao tó wà ní Caribbean, erékùṣù náà sì rẹwà gan-an. Orílẹ̀-èdè Suriname ni bàbá mi ti wá, àmọ́ ó ṣí lọ sí erékùṣù náà láti lọ ṣiṣẹ́. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí bàbá mi ṣèrìbọmi ni wọ́n bí mi, ó sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Curaçao. a Ó máa ń kọ́ gbogbo àwa ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì a kì í fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14), bàbá mi kó ìdílé wa lọ sí Suriname kó lè tọ́jú ìyá ẹ̀ tó ti dàgbà.

ÀWỌN Ọ̀RẸ́ GIDI LÓ RÀN MÍ LỌ́WỌ́

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń fìtara sin Jèhófà ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ wa ní Suriname. Wọ́n fi ọdún díẹ̀ jù mí lọ, aṣáájú-ọ̀nà déédéé sì ni wọ́n. Mo máa ń rí ayọ̀ lójú wọn nígbà tí wọ́n bá ń sọ ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn tá a bá ti dé láti ìpàdé, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà míì, a máa ń jókòó síta lálẹ́ nígbà táwọn ìràwọ̀ ń tàn yinrin ká lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ náà. Àwọn ọ̀rẹ́ mi yìí ló jẹ́ kí n mọ ohun tí màá fayé mi ṣe. Iṣẹ́ Jèhófà ni mo fẹ́ fayé mi ṣe. Torí náà, mo ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́mọ ọdún méjìdínlógún (18).

MO KỌ́ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ PÀTÀKÌ

Èmi rèé nígbà tí mò ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní Paramaribo

Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo kọ́ nígbà tí mò ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, àwọn ẹ̀kọ́ náà sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí mo fayé mi ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí mo kọ́kọ́ kọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì kí n máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Willem van Seijl fẹ́ràn mi, ó sì dá mi lẹ́kọ̀ọ́. b Ó kọ́ mi bí mo ṣe lè bójú tó ọ̀pọ̀ iṣẹ́ nínú ìjọ. Lákòókò yẹn, mi ò mọ̀ pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn máa wúlò fún mi gan-an nígbà tó bá yá. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì ní kí n máa lọ bójú tó àwọn àwùjọ kan tó wà nínú igbó kìjikìji ní Suriname. Mo mọyì ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wúlò gan-an tí mo gbà lọ́dọ̀ Arákùnrin Willem àtàwọn arákùnrin míì! Àtìgbà yẹn ni mo ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn kí n lè máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́.

Ẹ̀kọ́ kejì tí mo kọ́ ni pé kéèyàn jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, kó sì máa ṣètò gbogbo ohun tó bá ń ṣe dáadáa. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, èmi àti arákùnrin tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe máa ń ṣètò oúnjẹ àtàwọn ohun tá a máa lò lóṣù náà. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára wa máa rìnrìn àjò tó jìn lọ sínú ìlú láti ra àwọn ohun tá a nílò. A máa ń fọgbọ́n ná owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ń fún wa lóṣooṣù, a sì ń lo àwọn nǹkan tó wà lọ́wọ́ wa díẹ̀díẹ̀ kó má bàa tán kí oṣù tó parí. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ohun tá à ń lò tán, bóyá la fi lè rí ẹni tó máa ràn wá lọ́wọ́ nínú igbó yẹn. Mo gbà pé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ pé kí n jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ mi lọ́rùn, kí n sì ṣètò gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe dáadáa ló jẹ́ kí n lè gbájú mọ́ iṣẹ́ Jèhófà láyé mi.

Ẹ̀kọ́ kẹta tí mo kọ́ ni pé àǹfààní wà nínú kéèyàn máa fi èdè ìbílẹ̀ àwọn èèyàn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láti kékeré ni mo ti gbọ́ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní Suriname, ìyẹn èdè Dutch, Gẹ̀ẹ́sì, Papiamento àti Sranantongo (tó tún ń jẹ́ Sranan). Àmọ́ mo rí i pé àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé inú igbó kìjikìji máa ń fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dáadáa tá a bá wàásù fún wọn ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Síbẹ̀, ó nira fún mi láti sọ díẹ̀ lára àwọn èdè yẹn, irú bí èdè Saramaccan tó ní ohùn òkè àti ohùn ìsàlẹ̀. Torí náà, mo sapá gan-an mo sì mọ̀ ọ́n sọ. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti kọ́ èèyàn púpọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ torí mo lè sọ èdè ìbílẹ̀ wọn.

Ká sòótọ́, ojú tì mí nígbà kan tí mi ò lè sọ èdè kan dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ obìnrin tó ń sọ èdè Saramaccan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé ṣé ara ẹ̀ le torí inú tó ń yọ ọ́ lẹ́nu. Àmọ́ nígbà tí mo máa sọ èdè náà, ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ ni pé, ṣé o lóyún ni? Ọ̀rọ̀ náà ò bá a lára mu rárá. Láìka irú àwọn àṣìṣe yìí sí, mo ṣì máa ń sapá gan-an láti sọ èdè ìbílẹ̀ àwọn tí mò ń wàásù fún.

MO GBA IṢẸ́ MÍÌ

Lọ́dún 1970, wọ́n sọ mí di alábòójútó àyíká. Lọ́dún yẹn kan náà, mo fi ètò aláwòrán kan han àwùjọ àwọn ará níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú igbó kìjikìji. Àkòrí ètò náà ni, “Ṣíṣèbẹ̀wò sí Orílé-Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ká tó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ará náà, èmi àtàwọn arákùnrin kan máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi tẹ́ẹ́rẹ́ gba orí àwọn odò tó wà nínú igbó kìjikìji náà. Inú ọkọ̀ náà là ń kó jẹnẹrétọ̀ àti táǹkì epo sí, títí kan àtùpà àti ẹ̀rọ tá a fi ń gbé àwòrán jáde. Tá a bá ti dé ibi tá à ń lọ, àá tún kó gbogbo ẹrù yìí jáde kúrò nínú ọkọ̀ lọ síbi tá a ti fẹ́ fi àwòrán náà han àwọn èèyàn. Ohun tí mo sábà máa ń rántí jù nípa àwọn ìrìn àjò yẹn ni bí àwọn ará tí wọ́n wà ní àdádó yẹn ṣe gbádùn ètò náà. Inú mi dùn gan-an pé mo lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ètò rẹ̀. Àwọn nǹkan tara tí mo ti yááfì kò já mọ́ nǹkan kan tá a bá fi wé ayọ̀ tí mò ń rí bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà.

MO HUN OKÙN ONÍFỌ́NRÁN MẸ́TA

Èmi àti Ethel ṣègbéyàwó ní September 1971

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mò ń ráyè ṣe iṣẹ́ ìsìn mi dáadáa torí mi ò tíì gbéyàwó, síbẹ̀ ó wù mí pé kí n fẹ́yàwó. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà kí n lè rí ìyàwó tó máa lè ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú igbó kìjikìji tá á sì máa láyọ̀. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ Ethel sọ́nà. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni, ó sì ti múra tán láti ṣe iṣẹ́ náà kódà nígbà tí ò bá rọrùn. Àtikékeré ló ti ń wu Ethel láti fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa wàásù bíi tiẹ̀. Torí náà, a ṣègbéyàwó ní September 1971, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká.

Ìdílé olówó kọ́ ni Ethel ti wá, torí náà kò ni ín lára nígbà tá à ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká nínú igbó kìjikìji. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ lọ bẹ ìjọ wò láwọn ibi tó jìnnà, a kì í di ẹrù púpọ̀. Inú odò la ti máa ń fọṣọ tá a sì ti ń wẹ̀. Bákan náà, ohunkóhun táwọn ará bá fi ṣe wá lálejò la máa ń jẹ. Ó lè jẹ́ aláǹgbá kan tó ń jẹ́ iguana tàbí ẹja kan tó ń jẹ́ piranha, ó sì tún lè jẹ́ ẹran èyíkéyìí tí wọ́n pa nínú igbó tàbí ẹja tí wọ́n pa nínú odò. Tá ò bá rí abọ́, inú ewé ọ̀gẹ̀dè la máa ń bu oúnjẹ wa sí, tá ò bá sì rí ṣíbí, ọwọ́ la fi máa jẹun. Èmi àti Ethel gbà pé bá a ṣe fi àwọn nǹkan kan du ara wa ká lè ṣiṣẹ́ Jèhófà dáadáa ti jẹ́ ká sún mọ́ ọn, ká sì di okùn onífọ́nrán mẹ́ta. (Oníw. 4:12) Kò sí nǹkan tá a lè fayé wa ṣe tó dáa jùyẹn lọ!

Ọjọ́ kan tá à ń bọ̀ látibi tá a ti lọ bẹ àwọn ará wò nínú igbó kìjikìji ni ohun tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀. Bá a ṣe dé ibi tí odò náà ti ń yára ṣàn, ọkọ̀ wa sáré wọnú omi, ó sì tún jáde sókè. A dúpẹ́ pé a wọ ẹ̀wù tó lè jẹ́ ká léfòó lọ́jọ́ yẹn, a ò sì já sómi. Àmọ́ omi rọ́ wọnú ọkọ̀ wa, torí náà a da oúnjẹ tó wà nínú ìkòkò oúnjẹ wa sínú omi, a sì fi àwọn ìkòkò náà gbọ́n omi kúrò nínú ọkọ̀ wa.

A bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹja tá a máa pa jẹ torí a ti da gbogbo oúnjẹ wa nù, àmọ́ a ò rẹ́ja pa. Torí náà, a gbàdúrà sí Jèhófà, a sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa lóúnjẹ tá a máa jẹ lọ́jọ́ yẹn. Bá a ṣe gbàdúrà tán báyìí ni ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tá a jọ wà níbẹ̀ ju ìwọ̀ sínú odò, ó sì gbé ẹja ńlá kan tó tó àwa márààrún jẹ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, a sì jẹ àjẹyó.

MO JẸ́ ỌKỌ, BÀBÁ ÀTI ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

Lẹ́yìn tá a ti jọ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká fún ọdún márùn-ún, Ethel ìyàwó mi lóyún láìrò tẹ́lẹ̀, torí náà àwa náà máa tó di òbí. Inú mi dùn nígbà tó ṣẹlẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ bí ìyẹn ṣe máa kan iṣẹ́ ìsìn wa. Ó wu èmi àti Ethel gan-an láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tá à ń ṣe nìṣó tó bá ṣeé ṣe. Nígbà tó dọdún 1976, a bí Ethniël ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́. Ọdún méjì ààbọ̀ lẹ́yìn náà la wá bí Giovanni ọmọkùnrin wa kejì.

A wà níbi ìrìbọmi ní Odò Tapanahoni nítòsí Godo Holo ní ìlà oòrùn Suriname lọ́dún 1983

Nítorí pé iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run fẹ́ ṣe pọ̀ gan-an ní Suriname nígbà yẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ká máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká nìṣó, ká sì máa tọ́ àwọn ọmọ wa. Nígbà táwọn ọmọ wa ṣì kéré, wọ́n ní kí n máa ṣèbẹ̀wò sáwọn àyíká tí ìjọ wọn ò pọ̀. Ìyẹn jẹ́ kí n máa lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan láàárín oṣù láti ṣe alábòójútó àyíká, kí n sì máa fi àwọn ọ̀sẹ̀ yòókù ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé nínú ìjọ tí wọ́n yan ìdílé mi sí. Ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa máa ń tẹ̀ lé mi tí mo bá fẹ́ lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà nítòsí ilé wa wò. Àmọ́ èmi nìkan ni mo máa ń lọ tí mo bá fẹ́ lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà nínú igbó kìjikìji yẹn wò tàbí tá a bá fẹ́ ṣe àpéjọ àyíká níbẹ̀.

Nígbà tí mò ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká, ọkọ̀ ojú omi ni mo máa ń wọ̀ lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà ní àdádó wò

Ó gba pé kí n ṣètò ara mi dáadáa kí n lè máa bójú tó gbogbo ojúṣe mi. Ọ̀sẹ̀ kan kì í kọjá ká má ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa. Tí mo bá ti lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà lọ́nà tó jìn wò, ìyàwó mi ló máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Àmọ́ gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe, èmi àti ìdílé mi máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Èmi àti ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa jọ máa ń ṣeré ìnàjú. Nígbà míì, ó lè jẹ́ géèmù tàbí ká kàn ṣeré jáde. Mo máa ń pẹ́ kí n tó sùn lálẹ́ kí n lè múra àwọn iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún mi. Torí Ethel jẹ́ ìyàwó tó dáńgájíá tí Òwe 31:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó máa ń tètè jí láàárọ̀ kí ìdílé wa lè jọ ka ẹsẹ ojúmọ́, ká sì jọ jẹun àárọ̀ káwọn ọmọ wa tó lọ sílé ìwé. Mo mà dúpẹ́ o, pé irú ìyàwó tó ń ṣiṣẹ́ kára báyìí ni mo fẹ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣe gbogbo ojúṣe mi.

Èmi àti ìyàwó mi ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ àwọn ọmọ wa kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù. Ó wù wá káwọn ọmọ wa fayé wọn ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. A ò fẹ́ kó jẹ́ pé àwa la yan iṣẹ́ náà fún wọn, àmọ́ a fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ló yan iṣẹ́ náà. A máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa ń fún èèyàn láyọ̀. Àmọ́, a tún máa ń sọ àwọn ìṣòro tá a máa ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ náà àti bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́, tó sì bù kún ìdílé wa. Bákan náà, a máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa mú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́. Ìyẹn àwọn tó fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ láyé wọn.

Jèhófà pèsè gbogbo ohun tá a nílò ká lè tọ́ àwọn ọmọ wa yanjú. Àmọ́ ṣá o, èmi náà máa ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí n ṣe. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nínú igbó kìjikìji kí n tó gbéyàwó ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe lè tọ́jú owó pa mọ́ láti fi ra nǹkan tó nílò. Àmọ́ nígbà míì, kò sí bá a ṣe sapá tó, awọ kì í kájú ìlù. Láwọn àkókò yẹn, mo rí i pé Jèhófà kì í dá wa dá a, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 1986 sí 1992, rògbòdìyàn kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Suriname. Láwọn ọdún yẹn, ó ṣòro gan-an láti rí àwọn ohun tá a nílò rà. Síbẹ̀, Jèhófà ń pèsè fún wa.—Mát. 6:32.

MI Ò KÁBÀÁMỌ̀ OHUN TÍ MO FAYÉ MI ṢE

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Èmi àti Ethel

Ethniël ọmọ wa àgbà àti Natalie ìyàwó ẹ̀

Giovanni ọmọ wa àti Christal ìyàwó ẹ̀

Kò sígbà tí Jèhófà kì í bójú tó wa, torí náà, ọkàn wa balẹ̀, a sì ń láyọ̀. Àrídunnú làwọn ọmọ wa, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ pé a tọ́ wọn kí wọ́n lè sin Jèhófà. Inú wa tún dùn gan-an pé àwọn náà pinnu láti fayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn ọmọ wa méjèèjì, Ethniël àti Giovanni kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Suriname ni àwọn àtàwọn ìyàwó wọn ti ń sìn báyìí.

Ara èmi àti ìyàwó mi ti ń dara àgbà, àmọ́ a ṣì ń fayé wa ṣiṣẹ́ Jèhófà, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sì làwa méjèèjì. Kódà, ọwọ́ wa dí gan-an débi pé mi ò tíì ráyè kọ́ bí wọ́n ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ títí di báyìí. Àmọ́ mi ò kábàámọ̀ rárá torí tí mo bá ń rántí gbogbo ohun tí mo ti ṣe, mo gbà pé ọ̀kan lára ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe láti kékeré ni bí mo ṣe fayé mi ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

b Wo ìtàn ìgbésí ayé Willem van Seijl nínú Jí! October 8, 1999 lédè Gẹ̀ẹ́sì, àkòrí ẹ̀ ni: Reality Has Exceeded My Expectations.”