ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45
Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
“Ó dájú pé wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.”—ÌSÍK. 2:5.
ORIN 67 “Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa, àmọ́ kí ló dá wa lójú?
KÌ Í yà wá lẹ́nu táwọn èèyàn bá ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àtakò náà sì lè burú jùyẹn lọ lọ́jọ́ iwájú. (Dán. 11:44; 2 Tím. 3:12; Ìfi. 16:21) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ tó bá gbéṣẹ́ fún wọn, kódà tí iṣẹ́ náà bá tiẹ̀ le gan-an. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò, ìyẹn àpẹẹrẹ wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó lọ jíṣẹ́ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì.
2. Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì lọ jíṣẹ́ fún, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Ìsíkíẹ́lì 2:3-6)
2 Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà sọ pé kí Ìsíkíẹ́lì lọ jíṣẹ́ fún? Jèhófà sọ pé wọ́n jẹ́ “aláìgbọràn,” “ọlọ́kàn líle” àti “ọlọ̀tẹ̀.” Wọ́n lè ṣeni léṣe bí ẹ̀gún àti òṣùṣú, wọ́n sì burú bí àkekèé. Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì léraléra pé: “Má bẹ̀rù”! (Ka Ìsíkíẹ́lì 2:3-6.) Ohun tó jẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì lè jíṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un ni pé (1) Jèhófà ló rán an, (2) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ àti (3) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Báwo làwọn nǹkan mẹ́ta yìí ṣe ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́? Báwo ló sì ṣe lè ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí?
JÈHÓFÀ LÓ RÁN ÌSÍKÍẸ́LÌ NÍṢẸ́
3. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì tó fún un lókun, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi dá a lójú pé òun máa ràn án lọ́wọ́?
3 Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Màá rán ọ.” (Ìsík. 2:3, 4) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa fún Ìsíkíẹ́lì lókun gan-an. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ìsíkíẹ́lì rántí pé Jèhófà sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún Mósè àti Àìsáyà nígbà tó yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe wòlíì fóun. (Ẹ́kís. 3:10; Àìsá. 6:8) Ìsíkíẹ́lì tún mọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn wòlíì méjèèjì yẹn lọ́wọ́ láti borí ìṣòro wọn. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì lẹ́ẹ̀mejì pé: “Màá rán ọ,” ìyẹn jẹ́ kó fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ran òun lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, gbólóhùn míì tún fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Jèhófà sọ fún mi pé.” (Ìsík. 3:16) Gbólóhùn kan tún fara hàn léraléra pé “Jèhófà tún sọ fún mi pé.” (Ìsík. 6:1) Torí náà, àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé Jèhófà ló rán òun níṣẹ́. Ohun míì tún ni pé torí pé ọmọ àlùfáà ni Ìsíkíẹ́lì, ó ṣeé ṣe kí bàbá ẹ̀ ti sọ fún un pé Jèhófà máa ń ran àwọn wòlíì ẹ̀ lọ́wọ́. Jèhófà tún sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún Ísákì, Jékọ́bù àti Jeremáyà. Ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ.”—Jẹ́n. 26:24; 28:15; Jer. 1:8.
4. Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì tó fún un lókun?
4 Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe tí Ìsíkíẹ́lì bá lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún wọn? Jèhófà sọ pé: “Ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ torí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.” (Ìsík. 3:7) Tí wọ́n bá kọ̀ tí wọn ò fetí sí Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà ni wọn ò fetí sí yẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé tí wọn ò bá tiẹ̀ fetí sí òun, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé òun ò ṣàṣeyọrí. Jèhófà tún fi dá Ìsíkíẹ́lì lójú pé tí ọ̀rọ̀ tí òun ní kó lọ sọ fún àwọn èèyàn náà bá ṣẹ, “wọ́n á mọ̀ pé wòlíì kan wà láàárín wọn.” (Ìsík. 2:5; 33:33) Torí náà, ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì yìí fún un lókun, ó sì máa jẹ́ kó lè jíṣẹ́ tó rán an.
JÈHÓFÀ LÓ RÁN ÀWA NÁÀ NÍṢẸ́ LÓNÌÍ
5. Bí Àìsáyà 44:8 ṣe sọ, kí ló fi wá lọ́kàn balẹ̀?
5 Ọkàn tiwa náà balẹ̀ lónìí torí a mọ̀ pé Jèhófà ló rán wa níṣẹ́. Jèhófà dá wa lọ́lá torí ó pè wá ní “ẹlẹ́rìí” òun. (Àìsá. 43:10) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Bí Jèhófà ṣe gba Ìsíkíẹ́lì níyànjú pé: “Má bẹ̀rù,” bẹ́ẹ̀ náà ló gba àwa náà níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín.” Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn tó ń ta kò wá? Ìdí ni pé Jèhófà ló rán àwa náà níṣẹ́, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́.—Ka Àìsáyà 44:8.
6. (a) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe tó fi wá lọ́kàn balẹ̀? (b) Kí ló ń fún wa lókun láti máa wàásù nìṣó?
6 Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí Jèhófà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Tí o bá gba inú omi kọjá, màá wà pẹ̀lú rẹ, tí o bá sì gba inú odò kọjá, kò ní kún bò ọ́. Tí o bá rin inú iná kọjá, kò ní jó ọ, ọwọ́ iná ò sì ní rà ọ́.” (Àìsá. 43:2) Bí àwa náà ṣe ń wàásù lónìí, a máa ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó dà bí odò àti iná. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù nìṣó. (Àìsá. 41:13) Bó ṣe rí nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, ọ̀pọ̀ ni ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù lákòókò tiwa yìí náà. Àmọ́ ó yẹ ká máa rántí pé bí wọn ò tiẹ̀ gbọ́ wa, kò túmọ̀ sí pé a ò ṣàṣeyọrí. A mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa bá ò ṣe jẹ́ kó sú wa, ìyẹn sì ń fún wa lókun láti máa wàásù nìṣó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀.” (1 Kọ́r. 3:8; 4:1, 2) Arábìnrin kan tó ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tipẹ́ sọ pé: “Inú mi dùn pé Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá wa, ó sì máa ń san wá lẹ́san.”
Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ ỌLỌ́RUN FÚN ÌSÍKÍẸ́LÌ LÓKUN
7. Tí Ìsíkíẹ́lì bá ń rántí ìran tó rí, báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
7 Ìsíkíẹ́lì rí i pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára gan-an. Nínú ìran tó rí, ó rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń darí àwọn áńgẹ́lì alágbára àtàwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò tó wà lọ́run. (Ìsík. 1:20, 21) Kí ni Ìsíkíẹ́lì wá ṣe? Ó sọ pé. “Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀.” Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yẹn bà á lẹ́rù débi pé ó dojú bolẹ̀. (Ìsík. 1:28) Torí náà, tí Ìsíkíẹ́lì bá ti ń rántí ìran àgbàyanu tó rí yẹn, ó máa ń jẹ́ kó dá a lójú pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ran òun lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun.
8-9. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì mú kó ṣe? (b) Báwo ni Jèhófà tún ṣe fún Ìsíkíẹ́lì lókun láti lọ jíṣẹ́ fáwọn èèyàn olórí kunkun yẹn?
8 Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Ọmọ èèyàn, dìde dúró kí n lè bá ọ sọ̀rọ̀.” Ohun tí Jèhófà sọ yìí àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló fún Ìsíkíẹ́lì lókun láti dìde dúró. Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Ẹ̀mí wọ inú mi, ó sì mú kí n dìde dúró.” (Ìsík. 2:1, 2) Lẹ́yìn ìgbà yẹn àti jálẹ̀ gbogbo àkókò tí Ìsíkíẹ́lì fi jíṣẹ́ Ọlọ́run, “ọwọ́” Ọlọ́run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń tọ́ ọ sọ́nà. (Ìsík. 3:22; 8:1; 33:22; 37:1; 40:1) Ẹ̀mí Ọlọ́run ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́ nígbà tó lọ jíṣẹ́ fún àwọn “olórí kunkun àti ọlọ́kàn líle” tó wà ní Ísírẹ́lì. (Ìsík. 3:7) Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Mo ti mú kí ojú rẹ le bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le bí iwájú orí wọn. Mo ti mú kí iwájú orí rẹ dà bíi dáyámọ́ǹdì, ó le ju akọ òkúta lọ. Má bẹ̀rù wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́.” (Ìsík. 3:8, 9) Ohun tí Jèhófà ń sọ fún Ìsíkíẹ́lì ni pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí orí kunkun àwọn èèyàn náà mú kó o rẹ̀wẹ̀sì. Màá fún ẹ lágbára.’
9 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí Ọlọ́run darí Ìsíkíẹ́lì nínú ìran, ó sì gbé e lọ síbi tó ti fẹ́ jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Ọwọ́ Jèhófà wà lára mi lọ́nà tó lágbára.” Ó gba wòlíì náà ní ọ̀sẹ̀ kan gbáko láti ronú nípa iṣẹ́ tó fẹ́ lọ jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó lè mọ̀ ọ́n dáadáa. (Ìsík. 3:14, 15) Jèhófà darí Ìsíkíẹ́lì lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan, “ẹ̀mí wá wọ inú [rẹ̀].” (Ìsík. 3:23, 24) Ní báyìí, Ìsíkíẹ́lì ti gbára dì láti lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an.
Ẹ̀MÍ ỌLỌ́RUN Ń FÚN WA LÓKUN LÓNÌÍ
10. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa wàásù nìṣó, kí sì nìdí?
10 Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù nìṣó? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́ nígbà yẹn. Kó tó di pé Ìsíkíẹ́lì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lókun kó lè ṣe iṣẹ́ náà. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ káwa náà lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù lónìí. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ń gbógun tì wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. (Ìfi. 12:17) Tá a bá fojú èèyàn wò ó, a ò lè borí Sátánì. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù nìṣó, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì! (Ìfi. 12:9-11) Lọ́nà wo? Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń fi hàn pé ẹ̀rù Sátánì ò bà wá bó ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa. Gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì. Torí náà, kí la lè sọ pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń wàásù nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ń ta kò wá? Ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa.—Mát. 5:10-12; 1 Pét. 4:14.
11. Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń ṣe fún wa, kí la sì lè ṣe kí Ọlọ́run lè máa fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀?
11 Kí ló tún dá wa lójú bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mú kí ojú àti iwájú orí Ìsíkíẹ́lì le? Ó dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tá a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (2 Kọ́r. 4:7-9) Torí náà, kí la lè ṣe kí Ọlọ́run lè máa fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀? Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, kó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ máa béèrè, . . . ẹ máa wá kiri, . . . ẹ máa kan ilẹ̀kùn.” Torí náà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 11:9, 13; Ìṣe 1:14; 2:4.
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN FÚN ÌSÍKÍẸ́LÌ LÓKUN
12. Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 2:9–3:3, ibo ni àkájọ ìwé náà ti wá, kí ló sì wà nínú ẹ̀?
12 Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí Ọlọ́run fún Ìsíkíẹ́lì lágbára, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún fún un lókun. Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó rí ọwọ́ kan tó mú àkájọ ìwé dání. (Ka Ìsíkíẹ́lì 2:9–3:3.) Ibo ni àkájọ ìwé náà ti wá? Kí ló wà nínú ẹ̀? Báwo ni àkájọ ìwé náà sì ṣe fún Ìsíkíẹ́lì lókun? Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jókòó sórí ìtẹ́ ni àkájọ ìwé náà ti wá. Ó lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí ni Jèhófà ní kó fún un ní àkájọ ìwé náà. (Ìsík. 1:8; 10:7, 20) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú àkájọ ìwé náà, ìyẹn ìdájọ́ tí Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì lọ sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n wà nígbèkùn. (Ìsík. 2:7) Wọ́n kọ ọ̀rọ̀ náà sí inú àti ẹ̀yìn àkájọ ìwé náà.
13. Kí ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣe sí àkájọ ìwé náà, kí sì nìdí tó fi dùn?
13 Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé kó jẹ àkájọ ìwé náà, kó sì “jẹ ẹ́ yó.” Ìsíkíẹ́lì ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ó sì jẹ gbogbo àkájọ ìwé náà. Kí ni ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nínú ìran yìí túmọ̀ sí? Ìyẹn ni pé Ìsíkíẹ́lì gbọ́dọ̀ mọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fẹ́ lọ sọ fáwọn èèyàn náà dunjú, ó sì gbọ́dọ̀ yé e dáadáa. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yani lẹ́nu. Ìsíkíẹ́lì rí i pé àkájọ ìwé náà “dùn bí oyin.” (Ìsík. 3:3) Kí nìdí tó fi sọ pé ó dùn bí oyin? Ìdí ni pé bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń ṣojú fún Jèhófà dà bí ohun kan tó dùn bí oyin, ó sì kà á sí àǹfààní ńlá. (Sm. 19:8-11) Torí náà, ó mọyì bí Jèhófà ṣe yan òun láti máa ṣiṣẹ́ wòlíì.
14. Kí ni Ìsíkíẹ́lì ṣe kó lè lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an?
14 Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wá sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún ọ, kí o sì fi í sọ́kàn.” (Ìsík. 3:10) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì rántí ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà, kó sì ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ṣe àwọn nǹkan yìí, ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ síyẹn, inú àkájọ ìwé yẹn kan náà ni ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tí Jèhófà ní kó lọ sọ fáwọn èèyàn yẹn wà. (Ìsík. 3:11) Torí náà, tí Ìsíkíẹ́lì bá ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun sọ fáwọn èèyàn náà dáadáa, ìgbà yẹn ló máa wá lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an.—Fi wé Sáàmù 19:14.
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN Ń FÚN WA LÓKUN LÓNÌÍ
15. Ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, kí ló yẹ ká ‘fi sọ́kàn’?
15 Káwa náà lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa fún wa lókun. A gbọ́dọ̀ máa “fi” gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ń sọ fún wa “sọ́kàn.” Lónìí, Bíbélì ni Jèhófà fi ń bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí èrò wa, kó sì tún máa fún wa lókun?
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn nǹkan wo ló sì yẹ ká máa ṣe kó lè yé wa dáadáa?
16 Tá a bá jẹ oúnjẹ kan, tó sì dà lára wa, ó máa ń ṣara wa lóore. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá à ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára. Ká má sì gbàgbé ohun tá a rí kọ́ nínú àkájọ ìwé yẹn. Jèhófà fẹ́ káwa náà ‘jẹ Ọ̀rọ̀ òun yó,’ ìyẹn ni pé kí ohun tó wà níbẹ̀ yé wa dáadáa. Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa gbàdúrà, ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Tá a bá fẹ́ ka Bíbélì, ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká gbàdúrà kóun tá a fẹ́ kà lè wọ̀ wá lọ́kàn. Lẹ́yìn náà, àá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Ohun tó kàn ni pé ká dánu dúró láwọn ibi tó yẹ, ká ṣàṣàrò, ká sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àǹfààní wo la máa rí? Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á yé wa dáadáa, ìgbàgbọ́ wa á sì túbọ̀ lágbára.
17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú Bíbélì?
17 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀? Ìdí ni pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, á sì jẹ́ ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká nígboyà láti kéde gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà, á mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayé wa á dùn bí oyin, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Sm. 119:103.
OHUN TÓ Ń MÚ KÁ MÁA WÀÁSÙ NÌṢÓ
18. Kí làwọn èèyàn tá à ń wàásù fún á wá mọ̀ níkẹyìn, kí sì nìdí?
18 Ọlọ́run dìídì yan Ìsíkíẹ́lì pé kó máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fáwa yàtọ̀ síyẹn. Iṣẹ́ tiwa ni pé ká máa wàásù ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ohun tá a sì ti pinnu pé àá máa ṣe nìyẹn títí dìgbà tí Jèhófà máa fi sọ pé iṣẹ́ náà ti parí. Nígbà tí àkókò ìdájọ́ náà bá dé, àwọn èèyàn tá à ń wàásù fún ò ní lè sọ pé kò sẹ́ni tó kìlọ̀ fáwọn tàbí pé Ọlọ́run pa àwọn tì. (Ìsík. 3:19; 18:23) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á wá mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán wa níṣẹ́ tá à ń jẹ́ fún wọn.
19. Kí ló máa fún wa lókun ká lè ṣiṣẹ́ ìwàásù wa parí?
19 Kí ló máa fún wa lókun ká lè ṣiṣẹ́ ìwàásù wa parí? Nǹkan mẹ́ta tó fún Ìsíkíẹ́lì lókun ló máa fún àwa náà lókun. Àkọ́kọ́, torí pé a mọ̀ pé Jèhófà ló rán wa níṣẹ́, ìyẹn ń jẹ́ ká máa wàásù nìṣó. Ìkejì, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń fún wa lágbára. Àti ìkẹta, ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń kọ́ ló ń fún wa lókun. Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, ká sì fara dà á “dé òpin.”—Mát. 24:13.
ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó ran wòlíì Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́ nígbà tó lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Torí náà, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran wòlíì yìí lọ́wọ́, á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa.