Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47

Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Fi Jèhófà Sílẹ̀

Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Fi Jèhófà Sílẹ̀

“Jèhófà, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.”—SM. 31:14.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun?

 JÈHÓFÀ rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. (Jém. 4:8) Òun ni Ọlọ́run wa àti Bàbá wa, ó sì ń fẹ́ ká jẹ́ Ọ̀rẹ́ òun. Ó máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ó ń lo ètò rẹ̀ láti kọ́ wa ká má bàa kó sínú ewu. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè sún mọ́ Jèhófà?

2. Báwo la ṣe lè sún mọ́ Jèhófà?

2 Tá a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àá sì mọyì ẹ̀. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kó wù wá láti ṣe ohun tó fẹ́, ká sì máa yìn ín lógo. (Ìfi. 4:11) Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fọkàn tán òun àti ètò tó ń lò láti darí wa.

3. Kí ni Èṣù máa ń ṣe láti mú ká fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní ṣe bẹ́ẹ̀? (Sáàmù 31:13, 14)

3 Èṣù máa ń fẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀, pàápàá láwọn ìgbà tí ìṣòro bá dé bá wa. Ọgbọ́n wo ló máa ń dá? Ó máa ń ṣe àwọn nǹkan táá mú ká máa ṣiyèméjì díẹ̀díẹ̀ pé Jèhófà àti ètò ẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán. Àmọ́ tá a bá ti mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n Sátánì, a ò ní kó sí pańpẹ́ ẹ̀. Tí ìgbàgbọ́ tá a ní bá lágbára, tá a sì fọkàn tán Jèhófà pátápátá, a ò ní fi Ọlọ́run àti ètò ẹ̀ sílẹ̀.—Ka Sáàmù 31:13, 14.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro mẹ́ta tó máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìṣòro yìí sì lè mú ká má fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀ mọ́. Báwo làwọn ìṣòro yìí ṣe lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀? Kí la sì lè ṣe kí Sátánì má bàa borí wa?

TÁ A BÁ DOJÚ KỌ ÌṢÒRO TÓ LE GAN-AN

5. Báwo ni ìṣòro tó le gan-an ṣe lè mú ká má fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀ mọ́?

5 Nígbà míì, àwọn ìṣòro tó le gan-an máa ń dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará ilé wa lè máa ta kò wá tàbí kí iṣẹ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Báwo làwọn ìṣòro yìí ṣe lè mú ká má fọkàn tán ètò Ọlọ́run mọ́, kó sì mú ká fi Jèhófà sílẹ̀? Tá a bá ti ń fara da ìṣòro kan tipẹ́tipẹ́, ó lè mú ká sọ̀rètí nù, inú wa sì lè má dùn mọ́. Àwọn ìgbà tá a bá níṣòro yìí ni Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣiyèméjì pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Èṣù fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà tàbí ètò ẹ̀ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan nírú èrò yìí nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì. Wọ́n kọ́kọ́ gbà pé Jèhófà ló yan Mósè àti Áárónì láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lóko ẹrú. (Ẹ́kís. 4:29-31) Àmọ́ nígbà tí Fáráò túbọ̀ ni wọ́n lára, wọ́n dá Mósè àti Áárónì lẹ́bi pé àwọn ló fa ìyà tó ń jẹ wọ́n. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti mú kí Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kórìíra wa,  sì ti fi idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá.” (Ẹ́kís. 5:19-21) Wọ́n dá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́bi. Ìyẹn mà bani nínú jẹ́ o! Tó bá ti pẹ́ gan-an tó o ti ń fara da ìṣòro tó le, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ máa fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀?

6. Kí la rí kọ́ lára wòlíì Hábákúkù nípa bá a ṣe lè fara da ìṣòro? (Hábákúkù 3:17-19)

6 Máa gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, kó o sì fi sùúrù dúró dè é. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló dé bá wòlíì Hábákúkù. Ìgbà kan wà tó rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, ó gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Ó ní: “Jèhófà, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí o kò gbọ́? . . . Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára?” (Háb. 1:2, 3) Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá tí ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí gbà. (Háb. 2:2, 3) Lẹ́yìn tí Hábákúkù ti ronú lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn ẹ̀ là, ó tún pa dà láyọ̀. Ó wá dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì máa ran òun lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro yòówù kó dé bá òun. (Ka Hábákúkù 3:17-19.) Kí la rí kọ́? Tí ìṣòro bá dé bá ẹ, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún un. Lẹ́yìn náà, fi sùúrù dúró dè é. Ó dájú pé Jèhófà máa fún ẹ lókun láti fara da ìṣòro náà. Tó o bá sì ti rọ́wọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ náà, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára.

7. Kí ni mọ̀lẹ́bí Shirley kan fẹ́ kó ṣe, àmọ́ kí ló jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára?

7 Túbọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìyẹn ṣe ran Arábìnrin Shirley tó ń gbé ní Papua New Guinea lọ́wọ́ nígbà tó níṣòro. b Tálákà ni ìdílé Shirley. Nígbà míì sì rèé, oúnjẹ tí ò tó nǹkan ni wọ́n ń rí jẹ. Mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe yẹ̀yẹ́ kó má bàa fọkàn tán Jèhófà mọ́. Ó sọ fún un pé: “Ṣè bó o sọ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ló ti wá ṣe fún ẹ báyìí? Ṣé o ò rí i pé ìdílé wa ṣì tòṣì ni. O wá ń fàkókò ẹ ṣòfò, o ló ò ń wàásù káàkiri.” Shirley sọ pé: “Mo wá bi ara mi pé: ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́?’ Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà lójú ẹsẹ̀, mo sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún un. Mi ò yé ka Bíbélì àtàwọn ìwé wa, mi ò yé wàásù, mo sì ń lọ sípàdé déédéé.” Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó wá rí i pé Jèhófà ń bójú tó ìdílé wọn. Ìdílé wọn ń rí oúnjẹ jẹ, wọ́n sì ń láyọ̀. Shirley sọ pé: “Mo rí i pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà mi.” (1 Tím. 6:6-8) Torí náà, tíwọ náà bá túbọ̀ ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìṣòro tàbí iyèméjì mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀.

TÍ WỌ́N BÁ HÙWÀ ÌKÀ SÁWỌN TÓ Ń ṢÀBÓJÚTÓ WA

8. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sáwọn alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run?

8 Àwọn ọ̀tá wa máa ń lo ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ìkànnì àjọlò láti parọ́ mọ́ àwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run, ká má bàa fọkàn tán wọn mọ́. (Sm. 31:13) Wọ́n ti fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin wa kan, wọ́n sì fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n. Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fàṣẹ ọba mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fẹ̀sùn èké kàn án. Kí làwọn Kristẹni yẹn wá ṣe?

9. Kí làwọn Kristẹni kan ṣe nígbà tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n?

9 Àwọn Kristẹni kan pa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù. (2 Tím. 1:8, 15) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé ojú ń tì wọ́n torí pé àwọn èèyàn ń fojú ọ̀daràn wo Pọ́ọ̀lù ni? (2 Tím. 2:8, 9) Àbí ṣé ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọ́n má lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn náà? Èyí ó wù kó jẹ́, ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù. Ó ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro, kódà ó ti fi ẹ̀mí ẹ̀ wewu nítorí wọn. (Ìṣe 20:18-21; 2 Kọ́r. 1:8) Torí náà, ẹ má jẹ́ ká dà bí àwọn tó pa Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó yẹ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́! Àmọ́, kí ló yẹ ká máa rántí nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sáwọn tó ń ṣàbójútó wa?

10. Kí ló yẹ ká máa rántí nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sáwọn tó ń ṣàbójútó wa?

10 Máa rántí ìdí tí wọ́n fi ń ṣenúnibíni sí wa, àtẹni tó ń fà á. Nínú 2 Tímótì 3:12, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn tó ń ṣàbójútó wa ni Sátánì máa ń kọ́kọ́ gbéjà kò. Ohun tó fẹ́ ni pé káwọn tó ń ṣàbójútó wa má jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà mọ́, kíyẹn sì mú kẹ́rù bà wá.—1 Pét. 5:8.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n de Pọ́ọ̀lù, Ónẹ́sífórù ò pa Pọ́ọ̀lù tì, àmọ́ ó ràn án lọ́wọ́. Bákan náà lónìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń dúró ti àwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n bá a ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí (Wo ìpínrọ̀ 11-12)

11. Kí la rí kọ́ lára Ónẹ́sífórù? (2 Tímótì 1:16-18)

11 Túbọ̀ máa ran àwọn tó ń ṣàbójútó wa lọ́wọ́, kó o sì dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro. (Ka 2 Tímótì 1:16-18.) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, Ónẹ́sífórù ò ṣe bíi tàwọn tó pa Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, “kò sì tijú pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n de [Pọ́ọ̀lù].” Kàkà bẹ́ẹ̀, Ónẹ́sífórù wá Pọ́ọ̀lù kàn. Nígbà tó rí i, ó ṣe àwọn nǹkan tó ràn án lọ́wọ́. Torí náà, Ónẹ́sífórù fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu nítorí Pọ́ọ̀lù. Kí la rí kọ́? A ò gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù èèyàn torí ìyẹn lè jẹ́ ká pa àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa tì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká dúró tì wọ́n, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 17:17) Torí náà, ó yẹ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ká sì dúró tì wọ́n.

12. Kí la rí kọ́ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà?

12 Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà ṣe dúró ti àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n níbẹ̀. Nígbà táwọn kan lọ jẹ́jọ́ ní kọ́ọ̀tù, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan lọ síbẹ̀ láti fún wọn níṣìírí. Kí la rí kọ́? Tí wọ́n bá ba àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa lórúkọ jẹ́, tí wọ́n fàṣẹ ọba mú wọn, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn, ká má bẹ̀rù, ká má sì pa wọ́n tì. A lè gbàdúrà fún wọn, ká bá wọn bójú tó ìdílé wọn, ká sì ṣe àwọn nǹkan míì tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ìṣe 12:5; 2 Kọ́r. 1:10, 11.

TÍ WỌ́N BÁ Ń FI WÁ ṢE YẸ̀YẸ́

13. Tí wọ́n bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká má fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀ mọ́?

13 Àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọmọ ilé ìwé wa lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń wàásù tàbí torí pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. (1 Pét. 4:4) Wọ́n lè sọ pé: “Mo fẹ́ràn bó o ṣe ń ṣe nǹkan, àmọ́ ẹ̀sìn yín ti le jù, kò sì bóde mu mọ́.” Àwọn kan lè máa ṣàríwísí pé bá a ṣe ń ṣe sáwọn tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ ò dáa. Wọ́n máa ń sọ pé: “Ṣè bí ẹ sọ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín?” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká máa ṣiyèméjì nípa àwọn òfin Jèhófà. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn òfin Jèhófà ò ti le jù báyìí? Ṣé ètò Ọlọ́run kì í fọwọ́ tó le jù mú nǹkan?’ Tá a bá bá ara wa nírú ipò yìí, kí ni ò ní jẹ́ ká fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀?

Nígbà táwọn tó pe ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ Jóòbù parọ́ mọ́ Jèhófà, Jóòbù ò gba irọ́ wọn gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé òun ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Tí wọ́n bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, kí ló yẹ ká ṣe? (Sáàmù 119:50-52)

14 Pinnu pé àwọn ìlànà Jèhófà ni wàá máa tẹ̀ lé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi Jóòbù ṣe yẹ̀yẹ́ pé ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ó pinnu pé àwọn ìlànà yẹn lòun á máa tẹ̀ lé. Ọ̀kan lára àwọn tó pe ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ Jóòbù fẹ́ kó gbà pé kò sí nǹkan tó kan Ọlọ́run bóyá Jóòbù ń tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀ àbí kò tẹ̀ lé e. (Jóòbù 4:17, 18; 22:3) Àmọ́ Jóòbù ò gba irọ́ ńlá yìí gbọ́. Ó mọ̀ pé ìlànà Jèhófà ló tọ́, ó sì pinnu pé òun á máa tẹ̀ lé e. Jóòbù ò jẹ́ káwọn èèyàn ba ìwà títọ́ òun jẹ́. (Jóòbù 27:5, 6) Kí la rí kọ́? Tí wọ́n bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, má jẹ́ kíyẹn mú kó o máa ṣiyèméjì nípa àwọn ìlànà Jèhófà. Ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Ṣé ìwọ náà ò rí i pé gbogbo ìgbà tó o tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ló ṣe ẹ́ láǹfààní? Torí náà, pinnu pé o ò ní fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ torí ètò yìí ló ń fi àwọn ìlànà náà kọ́ wa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́.—Ka Sáàmù 119:50-52.

15. Kí nìdí táwọn mọ̀lẹ́bí Brizit ṣe ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́?

15 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Brizit tó wá láti orílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ohun tó gbà gbọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1997, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, ọkọ ẹ̀ sọ pé kí òun, Brizit àtàwọn ọmọbìnrin wọn lọ máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí òun nílùú míì. Àmọ́ ìṣòro tí Brizit ní ju ìyẹn lọ. Torí pé ọkọ ẹ̀ ò tíì ríṣẹ́ míì, Brizit máa ní láti ṣiṣẹ́ kára gan-an kó lè rówó táá fi máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọ tó sún mọ́ ibi tó ń gbé tó nǹkan bíi kìlómítà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àtààbọ̀ (350). Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí ọkọ ẹ̀ ń ta kò ó nítorí ohun tó gbà gbọ́. Àtakò náà le débi pé Brizit àti ìdílé ẹ̀ ní láti kó lọ síbòmíì. Láìrò tẹ́lẹ̀, ọkọ ẹ̀ kú. Nígbà tó yá, àrùn jẹjẹrẹ pa ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá (12) péré. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé àwọn mọ̀lẹ́bí Brizit dá a lẹ́bi pé òun ló fa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n ní ká sọ pé kò di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo àjálù yìí ò bá má ṣẹlẹ̀ sí wọn. Láìka gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sí, ó túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà, kò sì fi ètò rẹ̀ sílẹ̀.

16. Ìbùkún wo ni Brizit rí torí pé kò fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀?

16 Nítorí pé ibi tí ìjọ wà jìnnà sí ibi tí Brizit ń gbé, alábòójútó àyíká sọ fún un pé kó máa wàásù lágbègbè yẹn, kó sì máa ṣèpàdé nílé. Nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́, ó rò pé kò lè ṣeé ṣe. Àmọ́ ó ṣe ohun tí alábòójútó àyíká sọ. Ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn lágbègbè ẹ̀, ó sì máa ń ṣèpàdé nílé. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń ṣètò àkókò tóun àtàwọn ọmọbìnrin ẹ̀ jọ máa ṣe ìjọsìn ìdílé. Àǹfààní wo ló rí? Brizit bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan lára wọn sì ṣèrìbọmi. Lọ́dún 2005, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Jèhófà bù kún un torí pé ó fọkàn tán an àti pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí ètò rẹ̀. Ní báyìí, àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, ìjọ méjì ló sì ti wà lágbègbè yẹn! Brizit mọ̀ pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tóun ní àti yẹ̀yẹ́ látọ̀dọ̀ ìdílé òun.

MÁ FI JÈHÓFÀ ÀTI ÈTÒ Ẹ̀ SÍLẸ̀

17. Kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe?

17 Sátánì fẹ́ ká gbà pé Jèhófà máa pa wá tì tá a bá níṣòro àti pé ìyà máa jẹ wá tá a bá wà nínú ètò Jèhófà. Sátánì fẹ́ kẹ́rù máa bà wá tí wọ́n bá ba àwọn tó ń ṣàbójútó wa lórúkọ jẹ́, tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí wọn tàbí tí wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Ó tún máa ń lo àwọn èèyàn kí wọ́n lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ká má bàa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà mọ́, ká má sì fọkàn tán ètò ẹ̀ mọ́. Àmọ́, a mọ àwọn ọgbọ́n burúkú tí Sátánì ń dá, kò sì lè tàn wá jẹ. (2 Kọ́r. 2:11) Pinnu pé o ò ní gba irọ́ Sátánì gbọ́ àti pé o ò ní fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀. Máa rántí pé Jèhófà ò ní pa ẹ́ tì láé. (Sm. 28:7) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀!—Róòmù 8:35-39.

18. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

18 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ àwọn ìṣòro tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tún lè dán wa wò bóyá a fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀. Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè borí àwọn ìṣòro náà? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

a Ká lè máa fara da ìṣòro wa ká sì jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a gbọ́dọ̀ máa fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀. Àmọ́ Èṣù máa ń fẹ́ lo àwọn ìṣòro tó dé bá wa láti mú ká má fọkàn tán Jèhófà àti ètò ẹ̀ mọ́. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro mẹ́ta tí Èṣù máa ń lò àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe ká má bàa fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.