Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48

Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́ Tí Nǹkan Kan Bá Dán Ìgbàgbọ́ Ẹ Wò

Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́ Tí Nǹkan Kan Bá Dán Ìgbàgbọ́ Ẹ Wò

“Máa ronú bó ṣe tọ́ nínú ohun gbogbo.”—2 TÍM. 4:5.

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Báwo la ṣe lè “máa ronú bó ṣe tọ́”? (2 Tímótì 4:5)

 TÍ NǸKAN kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó dùn wá, ó lè jẹ́ kó nira fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀. Báwo la ṣe lè borí irú àwọn ìṣòro yẹn? Ó yẹ ká máa ronú bó ṣe tọ́, ká wà lójúfò, ká sì dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (Ka 2 Tímótì 4:5.) Tá a bá fẹ́ máa ronú bó ṣe tọ́, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀, ká máa ronú jinlẹ̀, ká sì máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hùwà.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti jíròrò ìṣòro mẹ́ta tó lè wá látọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìṣòro mẹ́ta tá a lè dojú kọ nínú ìjọ tó lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Àwọn ìṣòro náà ni (1) táwọn tá a jọ ń sin Jèhófà bá ṣe nǹkan tí ò dáa sí wa, (2) tí wọ́n bá bá wa wí nínú ìjọ àti (3) tí kò bá rọrùn fún wa láti fara mọ́ àwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Torí náà, báwo la ṣe lè máa ronú bó ṣe tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa?

TÁWỌN TÁ A JỌ Ń SIN JÈHÓFÀ BÁ ṢE NǸKAN TÍ Ò DÁA SÍ WA

3. Kí ló ṣeé ṣe ká ṣe tẹ́nì kan tá a jọ ń sin Jèhófà bá ṣe nǹkan tí ò dáa sí wa?

3 Ṣé ẹnì kan ti ṣe nǹkan tí ò dáa sí ẹ rí, pàápàá ọ̀kan lára àwọn alábòójútó? Arákùnrin náà lè má mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe yẹn. (Róòmù 3:23; Jém. 3:2) Síbẹ̀, ohun tó ṣe yẹn lè múnú bí ẹ gan-an. Kódà, o lè má rórun sùn torí ẹ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń darí ètò yìí lóòótọ́, kò yẹ kí arákùnrin yìí hu irú ìwà báyìí sí mi.’ Ohun tí Sátánì sì fẹ́ ká máa rò gan-an nìyẹn. (2 Kọ́r. 2:11) Irú èrò bẹ́ẹ̀ lè mú ká fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀. Torí náà, tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ti ṣe ohun tí ò dáa sí wa, kí lá mú ká máa ronú bó ṣe tọ́, ká má sì gba èròkerò láyè?

4. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe ronú lọ́nà tó tọ́ nígbà táwọn èèyàn hùwà ìkà sí i, kí la sì rí kọ́ lára ẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 50:19-21)

4 Má di àwọn èèyàn sínú. Nígbà tí Jósẹ́fù wà lọ́dọ̀ọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ hùwà ìkà sí i, wọ́n kórìíra ẹ̀ gan-an, kódà àwọn kan lára wọn fẹ́ pa á. (Jẹ́n. 37:4, 18-22) Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tà á sóko ẹrú. Ìyẹn mú kí Jósẹ́fù dojú kọ àwọn ìṣòro tó le gan-an fún nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13). Jósẹ́fù tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ṣé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun ṣá. Ó sì lè máa rò pé Jèhófà ti pa òun tì lásìkò tó yẹ kó ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ Jósẹ́fù ò ronú bẹ́ẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fara balẹ̀, ó sì ronú lọ́nà tó tọ́. Kódà, nígbà tó láǹfààní láti gbẹ̀san lára àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìfẹ́ hàn sí wọn, tó sì dárí jì wọ́n. (Jẹ́n. 45:4, 5) Ohun tó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tó fi lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ronú lọ́nà tó tọ́. Dípò kó máa ronú ṣáá nípa ohun táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ṣe sí i, ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe ló gbájú mọ́. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 50:19-21.) Kí la rí kọ́? Tí wọ́n bá ṣe nǹkan tí ò dáa sí ẹ, má bínú sí Jèhófà tàbí kó o máa rò pé Jèhófà ti pa ẹ́ tì. Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro náà. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ, má wo àìpé wọn, ṣe ni kó o máa fìfẹ́ hàn sí wọn.—1 Pét. 4:8.

5. Báwo ni Miqueas ṣe ronú lọ́nà tó tọ́ nígbà táwọn èèyàn ṣe ohun tí ò dáa sí i?

5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Miqueas b láti South America. Ó rántí ìgbà kan tó ronú pé àwọn alàgbà ṣe ohun tí ò dáa sóun. Ó sọ pé: “Ojú mi ò tíì rírú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Àyà mi já. Mi ò lè sùn, mo sì sunkún gan-an torí ọ̀rọ̀ náà kọjá agbára mi.” Síbẹ̀, Miqueas ronú lọ́nà tó tọ́, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa ṣinú bí. Ó gbàdúrà léraléra, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní ẹ̀mí mímọ́ àti okun láti fara da ìṣòro náà. Ó tún ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa kó lè rí ìsọfúnni tó máa ràn án lọ́wọ́. Kí la rí kọ́? Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ, fara balẹ̀, má ṣinú bí, má sì di ẹni náà sínú. O lè má mọ ohun tó mú kí ẹni náà sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn tàbí hùwà lọ́nà yẹn. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó mú kó hu irú ìwà yẹn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ẹni náà ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tó ṣe sí ẹ, á sì jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti dárí jì í. (Òwe 19:11) Rántí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á sì fún ẹ lókun láti fara dà á.—2 Kíró. 16:9; Oníw. 5:8.

TÍ WỌ́N BÁ BÁ WA WÍ NÍNÚ ÌJỌ

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló ń mú kó bá wa wí? (Hébérù 12:5, 6, 11)

6 Tí wọ́n bá bá wa wí, ó máa ń dùn wá gan-an. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ náà ṣe dùn wá tó là ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, ó lè má jẹ́ kí ìbáwí yẹn ṣe wá láǹfààní, ó sì lè jẹ́ ká máa rò pé wọn ò dájọ́ náà bó ṣe tọ́ tàbí pé ìbáwí náà ti le jù. Torí náà, ìbáwí náà lè má ṣe wá láǹfààní tó yẹ, ó sì lè má jẹ́ ká rí i pé torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe bá wa wí. (Ka Hébérù 12:5, 6, 11.) Tó bá sì jẹ́ pé bí ìbáwí yẹn ṣe dùn wá tó la gbájú mọ́, ó lè jẹ́ kó rọrùn fún Sátánì láti wọlé sí wa lára. Sátánì ò fẹ́ ká gba ìbáwí tí wọ́n fún wa, kódà ó fẹ́ ká fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀. Torí náà, tí wọ́n bá ti bá ìwọ náà wí, kí lá mú kó o máa ronú lọ́nà tó tọ́?

Pétérù gba ìbáwí tí Jésù fún un, ìyẹn sì mú kó túbọ̀ wúlò fún Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. (a) Nínú àwòrán yẹn, báwo ni Jèhófà ṣe lo Pétérù lẹ́yìn tí Jésù bá a wí? (b) Kí lo rí kọ́ lára Pétérù?

7 Gba ìbáwí, kó o sì ṣàtúnṣe. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Jésù bá Pétérù wí níṣojú àwọn àpọ́sítélì tó kù. (Máàkù 8:33; Lúùkù 22:31-34) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa kó ìtìjú bá Pétérù gan-an! Síbẹ̀, Pétérù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù. Ó gba ìbáwí tí Jésù fún un, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe. Torí náà, Jèhófà bù kún Pétérù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì fún un ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. (Jòh. 21:15-17; Ìṣe 10:24-33; 1 Pét. 1:1) Kí la rí kọ́ lára Pétérù? Tí wọ́n bá bá wa wí, tí ìbáwí náà sì kó ìtìjú bá wa, tá a bá gba ìbáwí náà tá a sì ṣàtúnṣe, ó máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní gan-an. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará wa.

8-9. Lẹ́yìn tí wọ́n bá Bernardo wí, báwo ló ṣe kọ́kọ́ rí lára ẹ̀, àmọ́ kí ló jẹ́ kó tún èrò ẹ̀ ṣe?

8 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Bernardo tó ń gbé ní Mòsáńbíìkì. Alàgbà ni tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, kò láǹfààní yẹn mọ́. Báwo ló ṣe kọ́kọ́ rí lára Bernardo nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún un pé kò ní lè máa bá iṣẹ́ náà lọ mọ́? Ó sọ pé: “Inú mi ò dùn sáwọn alàgbà torí pé ìbáwí tí wọ́n fún mi yẹn ò bá mi lára mu.” Ó ń dùn ún pé àwọn ará ìjọ á máa fojú tí ò dáa wo òun. Ó sọ pé, “Ó tó oṣù bíi mélòó kan kí n tó gba ìbáwí tí wọ́n fún mi, kí n sì pa dà fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀.” Kí ló mú kí Bernardo yí èrò ẹ̀ pa dà?

9 Kí ló mú kí Bernardo ṣàtúnṣe? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì jẹ́ alàgbà, mo máa ń ka Hébérù 12:7 fáwọn tí wọ́n bá wí nínú ìjọ kí wọ́n lè fi ojú tó tọ́ wo ìbáwí náà. Torí náà, mo bi ara mi pé, ‘Ta ló yẹ kó fi ẹsẹ Bíbélì yìí sílò báyìí?’ Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni títí kan èmi fúnra mi.” Lẹ́yìn ìyẹn, Bernardo ṣe àwọn nǹkan míì kó lè túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀. Ó túbọ̀ ń ka Bíbélì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ń lo àkókò tó pọ̀ láti ṣàṣàrò lórí ohun tó kà. Bó tiẹ̀ ń rò pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń fi ojú tí ò dáa wo òun, síbẹ̀ ó máa ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù, ó sì máa ń dáhùn láwọn ìpàdé ìjọ. Nígbà tó yá, Bernardo pa dà di alàgbà. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti bá ìwọ náà wí bíi ti Bernardo, má jẹ́ kó dùn ẹ́ jù, àǹfààní tí ìbáwí náà máa ṣe ẹ́ ni kó o wò. Gba ìbáwí náà, kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. c (Òwe 8:33; 22:4) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ẹ torí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí i àti ètò rẹ̀.

TÍ KÒ BÁ RỌRÙN FÚN WA LÁTI FARA MỌ́ ÀWỌN ÀYÍPADÀ TÓ Ń WÁYÉ NÍNÚ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

10. Àwọn àyípadà wo ló ṣeé ṣe kó dán ìgbàgbọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì kan wò?

10 Táwọn àyípadà kan bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run, ó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Kódà, tá ò bá ṣọ́ra, ó lè jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àyípadà kan tí Jèhófà ṣe tó dán ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan wò nígbà tó fún wọn ní Òfin Mósè. Kí Jèhófà tó fún wọn ní Òfin yẹn, gbogbo olórí ìdílé ló máa ń ṣiṣẹ́ àlùfáà. Wọ́n máa ń mọ pẹpẹ, wọ́n sì máa ń rúbọ sí Jèhófà lórí ẹ̀ nítorí ìdílé wọn. (Jẹ́n. 8:20, 21; 12:7; 26:25; 35:1, 6, 7; Jóòbù 1:5) Àmọ́ nígbà tí Jèhófà fún wọn lófin yẹn, àwọn olórí ìdílé ò láǹfààní láti máa rúbọ fúnra wọn mọ́. Jèhófà wá yan àwọn àlùfáà láti ìdílé Áárónì pé kí wọ́n máa rúbọ. Lẹ́yìn tí àyípadà yẹn wáyé, tí olórí ìdílé kan tí kò sí lára àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì bá lọ rúbọ, ó lè fikú ṣèfà jẹ. d (Léf. 17:3-6, 8, 9) Ṣé ó ṣeé ṣe kí àyípadà yìí wà lára ìdí tí Kórà, Dátánì, Ábírámù àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àtààbọ̀ (250) olórí ní Ísírẹ́lì fi ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì? (Nọ́ń. 16:1-3) A ò lè sọ. Àmọ́ èyí ó wù ó jẹ́, ohun tá a mọ̀ ni pé Kórà àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn ò jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Torí náà, táwọn àyípadà kan bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run tó dán ìgbàgbọ́ ẹ wò, kí ló yẹ kó o ṣe?

Nígbà táwọn ọmọ Kóhátì gba iṣẹ́ míì, tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń kọrin, tí wọ́n ń ṣọ́bodè, tí wọ́n sì ń bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Kí la rí kọ́ lára àwọn ọmọ Kóhátì tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì?

11 Máa fara mọ́ àwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, iṣẹ́ pàtàkì làwọn ọmọ Kóhátì máa ń ṣe. Àwọn kan lára wọn ló máa ń gbé àpótí májẹ̀mú lọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkigbà tí wọ́n bá ti ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíì. (Nọ́ń. 3:29, 31; 10:33; Jóṣ. 3:2-4) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Àmọ́ nǹkan yí pa dà fún wọn nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí torí pé wọn kì í gbé àpótí májẹ̀mú yẹn káàkiri mọ́. Àmọ́ nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso, ó yan àwọn ọmọ Kóhátì kan pé kí wọ́n máa kọrin, ó ní kí àwọn kan máa ṣiṣẹ́ aṣọ́bodè, ó sì ní kí àwọn tó kù máa bójú tó ilé ìkẹ́rùsí. (1 Kíró. 6:31-33; 26:1, 24) Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn ọmọ Kóhátì ráhùn pé àwọn ju ẹni tó ń ṣerú iṣẹ́ yẹn lọ tàbí kí wọ́n sọ pé kí wọ́n fún àwọn níṣẹ́ tó gbayì jùyẹn lọ. Kí la rí kọ́? Tí àyípadà bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run, rí i pé o fara mọ́ àwọn àyípadà náà, kódà tí àyípadà náà bá kan iṣẹ́ tó ò ń ṣe. Jẹ́ kí inú ẹ máa dùn sí iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún ẹ. Máa rántí pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run kọ́ ló ń sọ bó o ṣe wúlò tó lójú Jèhófà. Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an tó o bá jẹ́ onígbọràn, ìyẹn sì ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ èyíkéyìí tó ò ń ṣe lọ.—1 Sám. 15:22.

12. Báwo ló ṣe rí lára Zaina nígbà tí wọ́n ní kó kúrò ní Bẹ́tẹ́lì lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Arábìnrin Zaina tó ń gbé ní Middle East gba iṣẹ́ ìsìn míì, tó sì kúrò nídìí iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì tó fẹ́ràn gan-an. Wọ́n sọ ọ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lẹ́yìn tó ti lò ju ọdún mẹ́tàlélógún (23) lọ ní Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ pé: “Ó dùn mí gan-an nígbà tí wọ́n fún mi níṣẹ́ míì. Mo máa ń wo ara mi bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, mo sì máa ń bi ara mi pé, ‘Àṣìṣe wo ni mo ṣe?’” Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tó wà nínú ìjọ ẹ̀ tún máa ń dá kún ìṣòro ẹ̀ tí wọ́n bá ti ń sọ fún un pé: “Ká sọ pé o mọṣẹ́ dáadáa nígbà tó o wà ní Bẹ́tẹ́lì, ètò Ọlọ́run ò ní sọ pé kó o máa lọ.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ yẹn máa ń kó ìbànújẹ́ bá Zaina débi pé alaalẹ́ ló máa ń sunkún. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Mi ò jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí n má fọkàn tán ètò Ọlọ́run mọ́ tàbí kí n máa ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́.” Àmọ́, kí ló mú kí Zaina bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó tọ́?

13. Kí ni Zaina ṣe tó mú kó borí èrò tí ò tọ́ tó ní?

13 Báwo ni Zaina ṣe borí èrò tí ò tọ́ tó ní? Ó ka àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú àwọn ìwé wa tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tó ní. Àpilẹ̀kọ náà, “O Mà Lè Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì!” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2001 ràn án lọ́wọ́ gan-an. Zaina sọ pé: “Àpilẹ̀kọ yẹn ṣàlàyé pé ó ṣeé ṣe kí Máàkù tó kọ Bíbélì náà nírú èrò yẹn nígbà tí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un yí pa dà. Àpẹẹrẹ tó dáa tí Máàkù fi lélẹ̀ ló jẹ́ kí n borí ìṣòro tí mo ní.” Yàtọ̀ síyẹn, Zaina ò fi àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sílẹ̀. Dípò kó máa ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀ tàbí kó máa káàánú ara ẹ̀, ṣe ló máa ń lọ sóde ìwàásù pẹ̀lú àwọn ará. Ó wá sọ pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀ àti pé àwọn tó ń ṣàbójútó wa nífẹ̀ẹ́ òun dénú. Síbẹ̀, ó gbà pé ohun tó dáa jù ni ètò Ọlọ́run máa ń ṣe kí iṣẹ́ Jèhófà lè máa tẹ̀ síwájú.

14. Àyípadà wo ni ò rọrùn fún Vlado láti fara mọ́, kí ló sì ràn án lọ́wọ́?

14 Alàgbà ni Arákùnrin Vlado tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Slovenia, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin (73) sì ni. Kò rọrùn fún un nígbà tí wọ́n da ìjọ ẹ̀ pọ̀ mọ́ ìjọ míì, tí ètò Ọlọ́run sì ní kí wọ́n má lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ mọ́. Ó sọ pé: “Mi ò mọ ìdí tí wọ́n fi sọ pé ká má lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà tóyẹn mọ́. Ó dùn mí gan-an torí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ṣe ni. Káfíńtà ni mí, mo sì wà lára àwọn tó ṣe àga inú Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe dà wá pọ̀ yẹn gba pé ká ṣe ọ̀pọ̀ àyípadà, àwọn àyípadà yẹn ò sì rọrùn rárá fáwa tá a ti dàgbà.” Kí ló ran Vlado lọ́wọ́ láti fara mọ́ àyípadà náà? Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà tá a bá fara mọ́ àwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ni Jèhófà máa bù kún wa. Àwọn àyípadà yẹn ń múra wa sílẹ̀ de àwọn àyípadà ńlá míì tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú.” Ṣé ó nira fún ìwọ náà láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ nígbà tí wọ́n da ìjọ yín pọ̀ mọ́ ìjọ míì tàbí nígbà tí wọ́n yan iṣẹ́ ìsìn míì fún ẹ? Ó dájú pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Torí náà, tó o bá fara mọ́ àwọn àyípadà yìí, tó o sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò ẹ̀, Jèhófà máa bù kún ẹ.—Sm. 18:25.

MÁA RONÚ LỌ́NÀ TÓ TỌ́ NÍ GBOGBO ÌGBÀ

15. Kí ló máa mú ká ronú lọ́nà tó tọ́ táwọn ará ìjọ bá ṣe nǹkan tó dùn wá?

15 Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó dájú pé àwọn ará ìjọ á máa ṣe àwọn nǹkan tó dùn wá. Àwọn nǹkan yẹn sì lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ronú lọ́nà tó tọ́. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ nínú ìjọ, má di ẹni náà sínú. Tí wọ́n bá bá ẹ wí tí ìbáwí náà sì kó ìtìjú bá ẹ, àǹfààní tó máa ṣe ẹ́ ni kó o wò. Torí náà gba ìbáwí náà, kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Yàtọ̀ síyẹn, tí àyípadà bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run tó kan iṣẹ́ tó ò ń ṣe, rí i pé o fara mọ́ àwọn àyípadà náà, kó o sì kọ́wọ́ ti ètò tí wọ́n ṣe.

16. Kí lá jẹ́ kó o máa fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀?

16 O ṣì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ táwọn nǹkan kan bá dán ìgbàgbọ́ ẹ wò. Àmọ́ kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa ronú lọ́nà tó tọ́. Ìyẹn ni pé kó o máa fara balẹ̀, kó o máa ronú jinlẹ̀, kó o sì máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Pinnu pé wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì tó nírú ìṣòro tó o ní, kó o sì ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè kọ́ lára wọn. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, má sì ya ara ẹ sọ́tọ̀ nínú ìjọ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sóhun tí Sátánì lè ṣe táá jẹ́ kó o fi Jèhófà àti ètò ẹ̀ sílẹ̀.—Jém. 4:7.

ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára

a Nígbà míì, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé inú ìjọ ló ti ṣẹlẹ̀ sí wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nǹkan mẹ́ta tó lè ṣẹlẹ̀ àti nǹkan tó yẹ ká ṣe ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

c O tún lè rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2009, ojú ìwé 30-32.

d Òfin Mósè sọ pé àgọ́ ìjọsìn ni kí àwọn olórí ìdílé ti máa pa ẹran tí wọ́n máa jẹ. Àmọ́ tí ibi tí ìdílé kan ń gbé bá jìnnà gan-an sí àgọ́ ìjọsìn, olórí ìdílé náà lè pa ẹran náà nílé wọn.—Diu. 12:21.