Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ṣé ẹni tó ń jẹ́ Módékáì wà lóòótọ́?
NÍNÚ ìwé Ẹ́sítà, ọkùnrin Júù kan tó ń jẹ́ Módékáì kó ipa pàtàkì nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tó wà nígbèkùn, ààfin ọba Páṣíà ló ti ń ṣiṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ níbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún Ṣ.S.K. “nígbà ayé [Ọba] Ahasuérúsì.” (Lóde òní, Sásítà Kìíní ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí.) Nígbà táwọn èèyàn kan ń gbìmọ̀ láti pa Ọba Ahasuérúsì, Módékáì ló tú àṣírí wọn. Torí náà, ọba ní kí wọ́n dá a lọ́lá láti fi hàn pé òun mọyì ohun tó ṣe fóun. Lẹ́yìn tí Hámánì tó jẹ́ ọ̀tá Módékáì àti ọ̀tá àwọn Júù kú, ọba sọ Módékáì di olórí ìjọba ẹ̀. Ipò tí Módékáì wà yìí jẹ́ kó ṣe òfin tí ò jẹ́ kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù run ní ilẹ̀ ọba Páṣíà.—Ẹ́sítà 1:1; 2:5, 21-23; 8:1, 2; 9:16.
Àwọn òpìtàn kan sọ pé ìtàn àròsọ ni ìwé Ẹ́sítà àti pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Módékáì. Àmọ́ lọ́dún 1941, àwọn awalẹ̀pìtàn rí ohun kan tó lè jẹ́ ẹ̀rí pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Módékáì. Kí ni wọ́n rí?
Àwọn tó ń ṣèwádìí rí wàláà kan tí wọ́n fi èdè Páṣíà kọ orúkọ kan sí lára, orúkọ náà ni Marduka (tá à ń pè ní Módékáì lédè Yorùbá). Iṣẹ́ alábòójútó ni Módékáì ń ṣe nílùú Ṣúṣánì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti ń ṣírò owó ló ti ń ṣiṣẹ́. Nígbà tí wọ́n rí wàláà yìí, Ọ̀gbẹ́ni Arthur Ungnad tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn àwọn ará ìlà oòrùn sọ pé, “yàtọ̀ sí inú Bíbélì tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa Módékáì, inú wàláà yìí nìkan ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.”
Látìgbà tí Ọ̀gbẹ́ni Ungnad ti sọ̀rọ̀ yẹn, àwọn ọ̀mọ̀wé ti túmọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún wàláà tí wọ́n fi èdè Páṣíà kọ. Lára wọn ni àwọn wàláà tó wà nílùú Pasẹpólísì tí wọ́n rí níbi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí nítòsí ògiri ìlú náà. Àwọn wàláà yìí sì ti wà látìgbà tí Sásítà Kìíní ti ń ṣàkóso. Èdè Élámù tí wọ́n ń sọ ní Páṣíà ni wọ́n fi kọ wọ́n, ọ̀pọ̀ orúkọ tó wà nínú ìwé Ẹ́sítà sì wà níbẹ̀. a
Àwọn wàláà Pasẹpólísì kan dárúkọ Marduka, wọ́n sì sọ pé iṣẹ́ akọ̀wé ọba ló ń ṣe ní ààfin Ṣúṣánì nígbà tí Sásítà Kìíní ń ṣàkóso. Ọ̀kan lára àwọn wàláà yẹn sọ pé atúmọ̀ èdè ni Marduka. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Módékáì náà ni wàláà yìí sọ. Ìjòyè ni láàfin Ọba Ahasuérúsì tó jẹ́ Sásítà Kìíní, ó sì ń sọ ó kéré tán èdè méjì. Ẹnubodè ààfin tó wà ní Ṣúṣánì ló máa ń jókòó sí. (Ẹ́sítà 2:19, 21; 3:3) Ẹnubodè náà tóbi gan-an, ibẹ̀ làwọn ìjòyè ọba sì ti máa ń ṣiṣẹ́.
Ohun táwọn wàláà yẹn sọ nípa Marduka àtohun tí Bíbélì sọ nípa Módékáì jọra wọn láìkù síbì kan. Ìgbà kan náà ni wọ́n gbé ayé, ìlú kan náà ni wọ́n gbé, ipò kan náà ni wọ́n wà níbi iṣẹ́ kan náà. Torí náà, gbogbo ẹ̀rí tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé ẹnì kan náà ni Marduka táwọn awalẹ̀pìtàn rí nínú wàláà àti Módékáì tó wà nínú ìwé Ẹ́sítà.
a Lọ́dún 1992, Ọ̀jọ̀gbọ́n Edwin M. Yamauchi kọ ìwé kan, ó sì dárúkọ àwọn èèyàn mẹ́wàá látinú ìwé Pasẹpólísì, orúkọ àwọn èèyàn náà sì tún wà nínú ìwé Ẹ́sítà.