Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó yẹ kí àwọn òbí máa fìfẹ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn

BÁ A ṢE LÈ YANJÚ ÌṢÒRO NÁÀ

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Ọmọlúwàbí

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Ọmọlúwàbí

Nígbà tí àwọn ọmọ ilé ìwé kan ń rìnrìn-àjò tí ilé ẹ̀kọ́ wọn ṣètò, wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn ọmọkùnrin kan lára wọn pé wọ́n fẹ́ fipá bá ọmọkùnrin míì lò pọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ilé ẹ̀kọ́ kan tó lókìkí lórílẹ̀-èdè Kánádà ni gbogbo wọn ń lọ. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Leonard Stern sọ sínú ìwé ìròyìn Ottawa Citizen pé: “Ti pé àwọn ọ̀dọ́ kan kàwé, wọ́n gboyè, wọ́n sì wà ní ipò pàtàkì láwùjọ kò túmọ̀ sí pé wọ́n máa níwà ọmọlúwàbí.”

Stern tún sọ pé: “Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí àwọn òbí ni bí wọ́n ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí. Àmọ́, ohun tó máa ń gba ọ̀pọ̀ òbí lọ́kàn jù lọ ni bí àwọn ọmọ wọn ṣe máa ṣe dáadáa níléèwé, bí wọ́n á ṣe rí iṣẹ́ tó dáa, àti bí wọ́n á ṣe di olówó.”

Lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn kàwé. Àmọ́, ti pé ẹnì kan kàwé rẹpẹtẹ kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún máa lè borí èrò tí kò dára tàbí ìwà burúkú. Ibo wá ni a ti lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ ká ní ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí?

Ẹ̀KỌ́ TÓ Ń JẸ́ KÁ NÍ ÌWÀ RERE TÓ SÌ Ń MÚNI SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ńṣe ni Bíbélì dà bíi dígí. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a máa rí ibi tá a kù sí àti àwọn ìwà tó yẹ ká tún ṣe. (Jákọ́bù 1:23-25) Àmọ́ Bíbélì tún lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan àti láti ní àwọn ìwà tó máa mú kí àlááfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀. Lára wọn ni ìwà rere, inú rere, ìpamọ́ra, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìfẹ́. Bíbélì tiẹ̀ pe ìfẹ́ ní “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Kí nìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́.

  • “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀ (pẹ̀lú ìgbéraga), kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo (ohun burúkú), ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, . . . a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”​—1 Kọ́ríńtì 13:​4-8.

  • “Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni.”​—Róòmù 13:⁠10.

  • “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”​—1 Pétérù 4:8.

Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ, tó o bá wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ? Ó dájú pé ara máa ń tù ẹ́, ọkàn rẹ sì máa ń balẹ̀. Ìdí ni pé àárín àwọn tó ń fẹ́ kó dára fún ẹ lo wà, o sì mọ̀ pé wọn ò ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára.

Ìfẹ́ tún máa ń mú kí èèyàn ṣe àwọn àyípadà kan, bóyá nínú ìwà rẹ̀, fún àǹfààní àwọn ẹlòmíì. Ohun tí Bàbá kan tó ń jẹ́ George ṣe nìyẹn. Nígbà tí ọmọbìnrin rẹ̀ bímọ, ó wù ú láti máa bá ọmọ-ọmọ rẹ̀ ṣeré. Àmọ́, ó ní ìṣòro kan. George máa ń mu sìgá gan-an, bàbá ọmọ yẹn ò sì fẹ́ kó máa mu sìgá nítòsí ọmọ náà. Kí ni George wá ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń mú sìgá fún àádọ́ta (50) ọdún, síbẹ̀ ó jáwọ́ nínú rẹ̀ nítorí ìlera ọmọ-ọmọ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ lágbára gan-an!

Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìwà rere, inú rere àti ìfẹ́

Gbogbo wa la lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́ hàn. Ara àwọn òbí làwọn ọmọ ti máa ń kọ́ bí èèyàn ṣe ń fi ìfẹ́ hàn, iṣẹ́ ńlá lèyí sì jẹ́ fún àwọn òbí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń bọ́ wọn, wọ́n sì máa ń tọ́jú wọn nígbà tí wọ́n bá fara pa tàbí tí wọ́n bá ń ṣàìsàn. Àwọn òbí tó bá mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì máa ń kọ́ wọn. Wọ́n tún máa ń bá àwọn ọmọ wí, wọ́n sì máa ń kọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe lè máa hùwà rere kí wọ́n sì yẹra fún ìwà búburú. Bákan náà, àwọn òbí rere máa ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.

Àmọ́ àwọn òbí kan ò fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn, ìyẹn ò sì dáa rárá. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ wọn ò lè ṣe dáadáa ni? Rárá o! Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà, títí kan àwọn tó wá láti ìdílé tí kò ti sí àlááfíà ló ti ṣe àwọn àyípadà tó yani lẹ́nu, tí wọ́n sì ti wá di ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn kan tí àwọn èèyàn rò pé ọ̀rọ̀ wọn ti kọjá àtúnṣe!