Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

WỌ́N BORÍ ÌṢÒRO WỌN

Ìtàn Ricardo àti Andres

Ìtàn Ricardo àti Andres

Ẹ̀kọ́ Bíbélì lágbára láti tún ayé àwọn èèyàn ṣe lọ́nà tó ń yani lẹ́nu. Jẹ́ ká wo bí àpẹẹrẹ Ricardo àti Andres ṣe fi èyí hàn.

RICARDO: Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), mo wọ ẹgbẹ́ kan. Àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bá rìn kọ́ mi ní ìwàkiwà. Kódà, mo pinnu pé mo fẹ́ lọ ṣẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹ́wàá! Ìyẹn lè dà bí ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ ní àdúgbò wa, bí èèyàn bá ṣe pẹ́ tó ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fún un tó. Èmi náà sì fẹ́ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún mi.

Gbogbo ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi ń ṣe ni èmi náà ń ṣe. Mò ń lo oògùn olóró, mò ń ṣe ìṣekúṣe, mo sì ń hùwà ipá. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, wàhálà ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn ń yìnbọn lu ara wọn, èmi náà sì wà níbẹ̀. Mo rò pé ọjọ́ yẹn ni mo máa kú, àmọ́ mo yè é. Lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí ìgbésí ayé mi ṣe rí àti ohun tí mo fẹ́ fi ayé mi ṣe, mo sì pinnu pé màá yí pa dà. Báwo ni mo ṣe lè ṣe é? Ta ló máa ràn mí lọ́wọ́?

Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn mọ̀lẹ́bí mi ni wọ́n ní ìṣòro, wọn ò sì láyọ̀. Àmọ́ nǹkan yàtọ̀ nínú ìdílé ọ̀kan lára àwọn àbúrò ìyá mi, wọ́n máa ń láyọ̀ ní tiwọn. Èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì máa ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Kódà, àwọn ni wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Torí náà, bí mo ṣe bọ́ nínú wàhálà ìbọn lọ́jọ́ yẹn, ńṣe ni mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ó yà mí lẹ́nu pé lọ́jọ́ kejì, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn mi! Ẹni náà ló sì kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Nígbà tó yá, mo dojú kọ ìṣòro ńlá kan. Àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí i pè mí pé kí n wá bá àwọn jáde. Kò rọrùn fún mi láti pa wọ́n tì, àmọ́ mo sọ fún wọn pé mi ò lọ. Mo pinnu pé mi ò ní pa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi tì. Inú mi sì dùn pé ohun tí mo ṣe nìyẹn! Ìgbésí ayé mi wá ń dára sí i, mo sì ní ayọ̀ tòótọ́.

Mo rántí pé nígbà kan tí mò ń gbàdúrà, mo sọ fún Ọlọ́run pé tẹ́lẹ̀ ó wù mí láti lo ọdún mẹ́wàá lẹ́wọ̀n kí àwọn èèyàn lè máa bọ̀wọ̀ fún mi. Àmọ́ ní báyìí, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún mi ní àǹfààní láti di òjíṣẹ́ tó ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fún ọdún mẹ́wàá kí n lè ran àwọn míì lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ran èmi náà lọ́wọ́. Ọlọ́run dáhùn àdúrà mi torí pé ọdún mẹ́tàdínlógún rèé tí mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tó ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà sì ṣe é, mi ò lọ sẹ́wọ̀n rárá!

Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ ló ṣì wà lẹ́wọ̀n báyìí. Àwọn míì tiẹ̀ ti kú. Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àpẹẹrẹ àwọn mọ̀lẹ́bí mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìwà wọn yàtọ̀, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Wọ́n wá di ẹni tí mo bọ̀wọ̀ fún ju ẹnikẹ́ni lọ nínú ẹgbẹ́ tí mo wà tẹ́lẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó kọ́ mi ní ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé ìgbé ayé mi.

ANDRES: Àdúgbò tí wọ́n bí mi sí jẹ́ ibi tí àwọn òtòṣì pọ̀ sí. Wọ́n ń lo oògùn olóró níbẹ̀, wọ́n ń jalè, wọ́n ń pa èèyàn, wọ́n sì ń ṣe ìṣekúṣe. Ọ̀mùtí ni bàbá mi, oògùn olóró sì ti di bárakú fún un. Ojoojúmọ́ ni bàbá mi àti ìyá mi máa ń jà, wọ́n máa ń bú ara wọn, wọ́n sì máa ń lu ara wọn.

Láti kékeré ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí, tí mo sì ń lo oògùn olóró. Ìgboro ni mo sábà máa ń wà, mò ń jalè, mo sì ń ta àwọn nǹkan tí mo bá jí. Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, ó wu bàbá mi pé kí èmi àtiwọn túbọ̀ mọwọ́ ara wa, wọ́n wá kọ́ mi bí mo ṣe lè máa kó oògùn olóró àtàwọn nǹkan míì lọ sí orílẹ̀-èdè míì láti lọ tà á. Kò pẹ́ rárá tí owó ńlá fi bẹ̀rẹ̀ sí í wọlé fún mi. Àmọ́, lọ́jọ́ kan àwọn ọlọ́pàá wá mi wá sílé, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn mí pé mo gbìyànjú láti pa ẹnì kan. Bí wọ́n ṣe jù mí sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún nìyẹn.

Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, wọ́n kéde lórí rédíò ọgbà ẹ̀wọ̀n wa pé kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá sí ibì kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Mo pinnu láti lọ. Ohun tí mo gbọ́ níbẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọn ò fi òtítọ́ ọ̀rọ̀ pa mọ́ fún mi rárá, wọ́n ṣàlàyé àwọn ìlànà Ọlọ́run lórí bó ṣe yẹ kí ọmọlúwàbí máa hùwà.

Mo wá rí i pé mo nílò ìrànlọ́wọ́ kí n tó lè yí pa dà, pàápàá jù lọ nígbà tí àwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n ń halẹ̀ mọ́ mi torí pé wọn ò fẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi ní okun àti ọgbọ́n, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ńṣe ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù.

Nígbà tí ó tó àkókò tí wọ́n máa dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, àyà mi já débi pé mi ò fẹ́ lọ sílé mọ́! Bí mo ṣe ń lọ ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù ń ju ọwọ́ sí mi pé ‘pásítọ̀ ó dàbọ̀ o, máa lọ sílé.’

Mo máa ń ronú pé báwo ni ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí ká sọ pé mi ò gba Ọlọ́run láyè láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó nífẹ̀ẹ́ mi, kò sì kà mí sí ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti kọjá àtúnṣe. a

a Tó o bá fẹ́ ka àwọn ìrírí míì nípa bí Bíbélì ṣe lágbára láti tún ayé àwọn èèyàn ṣe, o lè lọ sórí ìkànnì jw.org. Lọ sí abala OHUN TÁ A NÍ, lẹ́yìn náà wá ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.”