Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Ká Wà Lálàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn

Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Ká Wà Lálàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn

Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ ká mọ ohun tó lè mú ká wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, bóyá nílé wa, níbiṣẹ́ tàbí tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa. Wo àpẹẹrẹ àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Ọlọ́run fún wa, tó sì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́.

Máa Dárí Jini

“Ẹ máa . . . dárí ji ara yín fàlàlà, kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.”​—KÓLÓSÈ 3:13.

Gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. A lè ṣẹ àwọn èèyàn, àwọn náà sì lè ṣẹ̀ wá. Torí náà, ó yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn báwa náà ṣe fẹ́ kí wọ́n máa dárí jì wá. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, tá a sì ti dárí jì í, a ò tún ní máa di ẹni náà sínú mọ́. Kò yẹ ká máa “fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni,” bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ ká maa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa àṣìṣe tí ẹni náà ṣe. (Róòmù 12:17) Àmọ́ kí la máa ṣe tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá gan-an, tá ò sì lè gbé e kúrò lọ́kàn? Ó máa dáa ká lọ bá ẹni náà káwa méjèèjì sì jọ sọ̀rọ̀ náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. A gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ṣe la fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ kí àlàáfíà sì jọba, kì í ṣe pé a fẹ́ lọ jẹ́ kó mọ̀ pé òun ló jẹ̀bi.​—Róòmù 12:18.

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀, Kó O sì Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Èèyàn

“Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”​—FÍLÍPÌ 2:3.

Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, ó máa yá wọn lára láti sún mọ́ wa. Ọkàn wọn á balẹ̀ pé a máa ṣe dáadáa sí wọn, àá gba tiwọn rò, a ò sì ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dùn wọ́n. Àmọ́, tá a bá ń wo ara wa bíi pé a ṣe pàtàkì ju àwọn míì lọ, tàbí tá a gbà pé ohun tá a bá sọ labẹ gé, wàhálà nìyẹn máa dá sílẹ̀. Ńṣe làwọn èèyàn á máa yẹra fún wa, a ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn tá a bá tiẹ̀ rẹ́ni bá wa ṣọ̀rẹ́.

Má Ṣe Ojúsàájú

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—ÌṢE 10:34, 35.

Ẹlẹ́dàá wa kì í ka àwọn èèyàn kan sí ju àwọn míì lọ. Kì í wo orílẹ̀-èdè tẹ́nì kan ti wá, èdè ẹ̀, ipò ẹ̀ láwùjọ tàbí irú àwọ̀ tó ní, torí pé ìkan náà ni gbogbo wa jẹ́ lójú ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Láti ara ọkùnrin kan ló ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn.” (Ìṣe 17:26) Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo wa. Tá a bá ń yẹ́ àwọn èèyàn sí, tá a sì ń gba tiwọn rò, inú wọn á dùn, inú àwa náà á dùn, inú Ẹlẹ́dàá wa náà á sì dùn sí wa.

Jẹ́ Oníwà Tútù

“Ẹ fi . . . ìwà tútù . . . wọ ara yín láṣọ.”​—KÓLÓSÈ 3:12.

Tá a bá jẹ́ oníwàtútù, ó máa rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wa. Wọ́n á lè bá wa sọ̀rọ̀ fàlàlà, kódà wọ́n á lè tọ́ wa sọ́nà tá a bá ṣàṣìṣe torí wọ́n mọ̀ pé a ò ní bínú. Tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ń bínú sí wa, ọ̀rọ̀ tútù tá a fi dá a lóhùn lè mú kínú ẹ̀ rọ̀. Òwe 15:1 sọ pé “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.”

Jẹ́ Ọ̀làwọ́, Kó O sì Máa Moore

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—ÌṢE 20:35.

Olójúkòkòrò lọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, tara wọn nìkan ni wọ́n sì mọ̀. Àmọ́ àwọn tó bá lawọ́ máa ń láyọ̀ gan-an. (Lúùkù 6:38) Ìdí sì ni pé ọ̀làwọ́ èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ju àwọn ohun ìní lọ. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n máa dúpẹ́ oore, kí wọ́n sì máa mọyì ohun táwọn èèyàn bá ṣe fún wọn. (Kólósè 3:15) Bi ara ẹ pé, ‘Irú èèyàn wo ni mo fẹ́ ká jọ máa ṣe nǹkan pọ̀, ṣé ahun àti aláìmoore èèyàn ni àbí ẹni tó lawọ́ tó sì máa ń moore?’ Kókó ibẹ̀ ni pé bó o bá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí ẹ ni kí ìwọ náà máa ṣe sí wọn.​—Mátíù 7:12.