Kí Nìdí Tá A Fi Ń Jìyà, Tá À Ń Darúgbó, Tá A sì Ń Kú?
Ọmọ ni gbogbo wa jẹ́ lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa. Torí náà, kò fẹ́ kí ìyà jẹ wá rárá. Àmọ́ kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ gan-an láyé?
Àwọn Òbí Wa Àkọ́kọ́ Ló Kó Ìyà Jẹ Wá
‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.’—RÓÒMÙ 5:12.
Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́ Ádámù àti Éfà, ó fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé. Ó tún fi wọ́n sínú Párádísè, ìyẹn ọgbà ẹlẹ́wà tá à ń pè ní ọgbà Édẹ́nì. Ó sọ fún wọn pé wọ́n lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà náà, àmọ́ igi kan wà níbẹ̀ tí wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso ẹ̀. Àmọ́ Ádámù àti Éfà jẹ èso igi tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, bí wọ́n ṣe dẹ́ṣẹ̀ nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:1-19) Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, Ọlọ́run lé àwọn méjèèjì kúrò nínú ọgbà náà, àtìgbà yẹn ni nǹkan ti nira fún wọn. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bímọ, nǹkan sì nira fáwọn ọmọ wọn náà. Gbogbo wọn darúgbó, wọ́n sì kú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23; 5:5) Ìdí táwa náà sì fi ń ṣàìsàn, tá à ń darúgbó, tá a sì ń kú ni pé ọmọ Ádámù àti Éfà ni gbogbo wa.
Àwọn Áńgẹ́lì Burúkú Dá Kún Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé
“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 JÒHÁNÙ 5:19.
Sátánì ni “ẹni burúkú” yẹn. Òun ni áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jòhánù 8:44; Ìfihàn 12:9) Nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì míì dara pọ̀ mọ́ ọn. Àwọn ni Bíbélì pè ní ẹ̀mí èṣù. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí máa ń lo agbára wọn láti tan àwọn èèyàn jẹ, wọ́n sì máa ń mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wa. Wọ́n tún máa ń mú káwọn èèyàn hùwà burúkú. (Sáàmù 106:35-38; 1 Tímótì 4:1) Inú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù máa ń dùn láti fìyà jẹ àwọn èèyàn.
A Máa Ń Fọwọ́ Ara Wa Fa Ìyà Nígbà Míì
“Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”—GÁLÁTÍÀ 6:7.
Lọ́pọ̀ ìgbà, Sátánì àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ló máa ń fa ìyà tó ń jẹ wá. Àmọ́ nígbà míì, àwa èèyàn tún máa ń fọwọ́ ara wa dá kún ìyà tó ń jẹ wá. Lọ́nà wo? Tá a bá hùwà tí kò dáa tàbí a ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa. Àmọ́, tá a bá ṣohun tó dáa, a máa gba èrè ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí baálé ilé kan bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀, tó ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wọn, tó sì tún jẹ́ olóòótọ́, òun àti ìdílé ẹ̀ máa láyọ̀, ọkàn wọn á sì balẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé tẹ́tẹ́ ni baálé ilé kan ń ta kiri, tó tún ń mu ọtí àmujù tàbí tó ya ọ̀lẹ, ó lè sọ ara ẹ̀ àti ìdílé ẹ̀ di òtòṣì. Àbẹ́ ò rí i pé ohun tó dáa jù ni pé ká máa ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá wa. Ó fẹ́ ká kórè ọ̀pọ̀ ohun rere àti “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 119:165.
“Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí
‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ aṣàìgbọràn sí òbí, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere.’—2 TÍMÓTÌ 3:1-5.
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń hu àwọn ìwà tí Bíbélì sọ yẹn. Àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń hù yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà lóòótọ́. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àìsàn máa wà káàkiri. (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:10, 11) Àwọn nǹkan yìí máa ń fìyà jẹ aráyé gan-an, ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti lọ sí i.