Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Dojú Rú—Kí Lọ̀nà Àbáyọ?

Ayé Dojú Rú—Kí Lọ̀nà Àbáyọ?

Ojoojúmọ́ ni ìṣòro ń pọ̀ sí i láyé yìí, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn mú kí nǹkan tojú sú ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ máa dojú kọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro yìí ládùúgbò tó ò ń gbé.

  • ogun

  • àjàkálẹ̀ àrùn

  • ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé àtàwọn àjálù míì

  • ipò òṣì

  • kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

  • ìwà ọ̀daràn

Tí nǹkan aburú bá ṣẹlẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀, ẹ̀rù sábà máa ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn, nǹkan sì lè tojú sú wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà sì lè mú káwọn kan bara jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tí nǹkan aburú bá ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan ò tètè gbé ẹ̀rù tó ń bà á kúrò lọ́kàn tàbí tẹ́ni náà bara jẹ́ jù, kò ní lè ronú dáadáa, ìyẹn sì lè dá kún ìṣòro náà.

Ní báyìí tí nǹkan ń nira sí i láyé yìí, o gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe kó o lè mójú tó ìlera ẹ àti ọ̀rọ̀ nípa àtijẹ àtimu, kó o sì lè dáàbò bo àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ àtàwọn nǹkan míì tó lè fún ẹ láyọ̀.

Bí ìṣòro bá tiẹ̀ ń pọ̀ sí i láyé yìí, kí lo lè ṣe tí nǹkan ò fi ní nira fún ẹ?