Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ṢÉ AYÉ YÌÍ Ò NÍ BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

Igbó Kìjikìji

Igbó Kìjikìji

ÀWỌN kan gbà pé bí àwọn ẹ̀yà ara tá a fi ń mí ṣe ṣe pàtàkì ká tó lè máa wà láàyè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn igbó kìjikìji ṣe ṣe pàtàkì sí ilẹ̀ ayé yìí, kò sì sí àsọdùn nínú ohun tí wọ́n sọ . Àwọn igi ló máa ń gba afẹ́fẹ́ carbon dioxide sára, kó má bàa wu wá léwu. Àwọn igi yìí kan náà ló tún máa ń tú afẹ́fẹ́ oxygen síta, a sì nílò afẹ́fẹ́ yìí gan-an ká lè máa wà láàyè. Nǹkan bí ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá àwọn ẹranko àti ewéko tó wà láyé yìí ló ń gbénú igbó kìjikìji. Ká sòótọ́, àwọn igbó kìjikìji ń gbé ẹ̀mí wa ró.

Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Igbó KìjiKìji

Ọ̀kẹ́ àìmọye igi làwọn èèyàn ń gé lọ́dọọdún kí wọ́n lè rí ilẹ̀ tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ tàbí àwọn nǹkan míì. Láti nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) sẹ́yìn, ó tó ìdajì igbó kìjikìji tó wà láyé táwọn èèyàn ti pa run.

Tí wọ́n bá gé gbogbo igi tó wà nínú igbó kan, ńṣe làwọn ewéko àtàwọn ẹranko tó wà nínú igbó náà máa kú.

Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé

Ó jọni lójú gan-an pé àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti gé igi kúrò máa ń sọjí pa dà, tí igi á hù pa dà níbẹ̀, táwọn igi náà á sì tún pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Láìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàyẹ̀wò àwọn ilẹ̀ tí igbó kìjikìji wà tẹ́lẹ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé igi tún pa dà hù láwọn ilẹ̀ náà, tíbẹ̀ sì pa dà di igbo kìjikijì láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹnì kankan. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀:

  • Àwọn kan ṣèwádìí lórí àwọn ilẹ̀ kan tí wọ́n ti gé gbogbo ohun tó wà lórí ẹ̀ kúrò, kí wọ́n lè fi dáko, àmọ́ tí wọn ò wá gbin nǹkan kan sórí ẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ilẹ̀ tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méjì (2,200) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Amẹ́ríkà àti apá ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, wọ́n rí i pé láàárín ọdún mẹ́wàá tí wọn ò ti dáko lórí àwọn ilẹ̀ náà, ńṣe làwọn ilẹ̀ yẹn pa dà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, tí igi sì bẹ̀rẹ̀ sí í hù lórí wọn.

  • Ìwé ìròyìn Science sọ pé àwọn tó ń ṣèwádìí fojú bù ú pé, tó bá fi máa tó ọgọ́rùn-ún (100) ọdún kan sí i, àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti gé igi kúrò lórí ẹ̀ tún lè pa dà di igbó kìjikìji, káwọn ẹranko sì pa dà síbẹ̀.

  • Láìpẹ́ yìí, àwọn kan tó ń ṣèwádìí lórílẹ̀-èdè Brazil ṣàyẹ̀wò àwọn ilẹ̀ táwọn èèyàn ti gbin igi pa dà lẹ́yìn tí wọ́n ti gé gbogbo èyí tó wà níbẹ̀, wọ́n sì fi wéra pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ tí wọ́n fi sílẹ̀ pé káwọn igi tó wà níbẹ̀ hù pa dà fúnra wọn.

  • Ilé iṣẹ́ National Geographic sọ èsì ìwádìí tí wọ́n ṣe náà, wọ́n sọ pé: “Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n rí i pé kò pọn dandan káwọn gbin igi pa dà síbẹ̀.” Torí pé lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí wọ́n ti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ láì gbin igi síbẹ̀, “onírúurú igi ló hù pa dà síbẹ̀.”

Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe

Ibi gbogbo láyé làwọn èèyàn ti ń gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn igbó kìjikìji tó ṣì wà, wọ́n tún ń gbìyànjú láti jẹ́ káwọn igi tí wọ́n ti gé lulẹ̀ hù pa dà. Torí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé, “bí wọ́n ṣe ń pa igbó run lágbàáyé ti fi ìdajì dín kù” sí bó ṣe rí ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n (25) sẹ́yìn.

Àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ò tíì tó láti yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀. Àjọ Global Forest Watch sọ pé: “Láti ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àyípadà kankan nínú bí wọ́n ṣe ń pa igbó run láwọn ilẹ̀ olóoru.”

Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń gé igi nínú igbó láì gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba máa ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là nídìí iṣẹ́ yìí, owó tí wọ́n ń rí yìí ti fẹjú mọ́ wọn, torí náà wọn ò yéé gé igi, ọ̀pọ̀ igbó kìjikìjì ni wọ́n sì ń pa run.

Àwọn tó ń tọ́jú igbó kìjikìji máa ń gé díẹ̀ lára àwọn igi tó ti dàgbà, wọ́n á wá gbin igi míì síbẹ̀ kí igbó náà má bàa pa run

Bíbélì Mú Ká Nírètí

“Jèhófà a Ọlọ́run mú kí gbogbo igi tó dùn-ún wò, tó sì dára fún oúnjẹ hù látinú ilẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:9.

Ẹni tó dá àwọn igbó kìjikìji ṣe wọ́n lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa tún ara wọn ṣe, kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe wá láǹfààní. Kò fẹ́ káwọn igbó yẹn pa run rárá, ó fẹ́ kí wọ́n máa wà nìṣó, títí kan gbogbo ohun àlààyè tó ń gbé inú wọn.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa fòpin sí báwọn èèyàn ṣe ń lo ayé yìí nílòkulò, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n pa àwọn nǹkan alààyé tó wà nínú ẹ̀ run. Ka àpilẹ̀kọ náà “Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé” lójú ìwé 15.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.