Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Georgette Douwma/Stone via Getty Images

ṢÉ AYÉ YÌÍ Ò NÍ BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

Òkun

Òkun

INÚ òkun làwa èèyàn ti ń rí ọ̀pọ̀ lára àwọn oúnjẹ tá à ń jẹ, a tún máa ń rí àwọn èròjà aṣaralóore àtàwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣe oògùn látinú ẹ̀. Inú òkun ni ohun tó ju ìdajì lára afẹ́fẹ́ oxygen tí gbogbo ayé ń lò ti ń wá, ibẹ̀ sì ni èyí tó pọ̀ jù lára afẹ́fẹ́ carbon tó lè pani lára ń lọ. Bákan náà, òkun wà lára ohun tó máa ń pinnu bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí.

Wọ́n Ti Ba Òkun Jẹ́

Ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà lè ṣàkóbá fún òkìtì iyùn, ìṣáwùrú, àtàwọn nǹkan míì tó ń gbénú òkun. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé láìsí àwọn òkìtì iyùn yìí, nǹkan bí ìdá mẹ́rin àwọn ohun tó ń gbénú òkun ló máa kú, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọ́n ní ó ṣeé ṣe kó má sí òkìtì iyùn mọ́ láàárín ọgbọ̀n ọdún sí àsìkò tá a wà yìí.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹyẹ tó ń jẹ àwọn ohun alààyè inú òkun ló ti jẹ ike táwọn èèyàn jù sínú òkun, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọ́n gbà pé lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ẹ̀dà alààyè tó wà nínú òkun ló ń kú torí pé wọ́n ń jẹ àwọn ike yìí.

Lọ́dún 2022, Ọ̀gbẹ́ni António Guterres tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tá a ti pa òkun tì láì bójú tó o, ìdí nìyẹn tí nǹkan fi burú tó báyìí nínú òkun, tá ò bá sì tètè wá nǹkan ṣe sí i báyìí, ọ̀rọ̀ máa bẹ́yìn yọ.”

Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé

Tí ìdọ̀tí táwọn èèyàn ń dà sínú òkun ò bá pọ̀ jù, òkun àtàwọn ohun alààyè tó wà nínú ẹ̀ lè tún ara wọn ṣe, kí wọ́n sì mú ara wọn bọ̀ sípò. Ìwé Regeneration: Ending the Climate Crisis in One Generation jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣàlàyé pé ká sọ pé àwọn èèyàn ò kì í da ìdọ̀tí sínú òkun ni, “ńṣe ni omi òkun ì bá máa tún ara ẹ̀ ṣe kí omi náà lè máa mọ́ lóló láìsí ìdọ̀tí kankan.” Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀:

  • Àwọn kòkòrò tín-tìn-tín kan tí wọ́n ń pè ní phytoplankton máa ń gba afẹ́fẹ́ carbon dioxide sára, wọ́n sì máa ń kó o pa mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, afẹ́fẹ́ yìí wà lára àwọn afẹ́fẹ́ tó ń mú kí ayé yìí máa móoru gan-an. Iye afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí kòkòrò yìí ń kó pa mọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó gbogbo èyí tí igi, koríko àtàwọn ewéko míì tó wà láyé ń kó pa mọ́.

  • Àwọn kòkòrò tín-tìn-tín kan wà nínú òkun tó jẹ́ pé òkú ẹja ni wọ́n máa ń jẹ, ká sọ pé wọn kì í jẹ àwọn òkú ẹja ni, ńṣe ni wọn ì bá di ìdọ̀tí sínú òkun. Àwọn ohun alààyè míì sì wà nínú òkun tó jẹ́ pé àwọn kòkòrò tín-tìn-tín yìí ni oúnjẹ tiwọn. Àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń lọ nínú òkun, ìyẹn Smithsonian Institution Ocean Portal sọ pé bí àwọn ohun alààyè tó wà nínú òkun ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ yìí “ló ń mú kí òkun tún ara ẹ̀ ṣe kó lè wà ní mímọ́.”

  • Ohun tó ń lọ oúnjẹ nínú ẹja máa ń tú èròjà kan sínú omi, èròjà yìí sì máa ń tún omi ṣe kó má bàa ṣèpalára fáwọn òkìtì iyùn, ìṣáwùrú, àtàwọn ohun alààyè míì tó wà nínú òkun.

Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe

Táwọn èèyàn bá ń lo àwọn báàgì àtàwọn ike omi tó ṣeé tún lò, ìyẹn á mú kí ìdọ̀tí tí wọ́n ń dà sínú òkun dín kù

Ká sọ pé àwọn èèyàn ò kì í da ìdọ̀tí sínú òkun ni, kò ní sí pé à ń kó ìdọ̀tí inú òkun. Torí náà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa lo àwọn nǹkan tó ṣeé tún lò, dípò tí wọ́n á fi máa lo láílọ́ọ̀nù, ike àtàwọn nǹkan míì lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n á sì wábi jù ú sí.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tó yẹ káwa èèyàn ṣe. Láìpẹ́ yìí, àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká sọ pé, láàárín ọdún kan péré, àwọn kó ìdọ̀tí tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àti ọgọ́rùn-ún méjì (9,200) tọ́ọ̀nù lójú òkun lórílẹ̀-èdè méjìléláàádọ́fà (112). Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe nìyẹn wulẹ̀ jẹ́ bíńtí lára òbítíbitì ìdọ̀tí tó ń wọnú òkun lọ́dọọdún.

Ìròyìn kan tí àjọ National Geographic gbé jáde sọ pé: “Àwọn afẹ́fẹ́ olóró tó ń jáde látinú oríṣiríṣi epo táwọn èèyàn ń lò lójoojúmọ́ ti mú kó nira fáwọn ohun alààyè tó wà nínú òkun láti máa tún òkun ṣe kó lè wà ní mímọ́.”

Bíbélì Mú Ká Nírètí

“Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe. Ibẹ̀ ni òkun wà, ó tóbi, ó sì fẹ̀, àìmọye ohun alààyè ló wà nínú rẹ̀, èyí tó kéré àti èyí tó tóbi.”—Sáàmù 104:24, 25.

Ẹlẹ́dàá wa ló ṣe òkun lọ́nà tó fi lè máa tún ara ẹ̀ ṣe. Rò ó wò ná: Nígbà tó jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa ló dá òkun àti gbogbo nǹkan tó wà nínú ẹ̀, ṣé kò wá ní mọ bó ṣe lè mú gbogbo aburú táwọn èèyàn ti mú bá òkun kúrò? Ka àpilẹ̀kọ náà “Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé” lójú ìwé 15.