Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 1 2024 | Ṣé Ìwà Àpọ́nlé Ò Ti Dàwátì Báyìí?

Lóde òní, àwọn èèyàn kì í sábà pọ́nni lé mọ́. Torí náà, ó máa ń jọ wọ́n lójú gan-an tí wọ́n bá rí i tẹ́nì kan ń pọ́n ẹlòmíì lé.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ kì í bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, àwọn èèyàn kì í bẹ̀rù ẹni tó jù wọ́n lọ, wọn kì í sì í bọ̀wọ̀ fáwọn ọlọ́pàá, àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ àtàwọn olùkọ́. Ti orí ìkànnì àjọlò ló wá burú jù, ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń rí ara wọn fín níbẹ̀, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú síra wọn! Kódà, ìwé ìròyìn Harvard Business Review sọ pé, ‘ojoojúmọ́ làwọn èèyàn túbọ̀ ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fúnni.’ Ìwé ìròyìn yẹn wá fi kún un pé “àwọn èèyàn ti túbọ̀ ń kíyè sí ìwà yìí, ńṣe ló sì ń burú sí i.”

 

Ṣé Ìwà Àpọ́nlé Ò Ti Dàwátì Báyìí?

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ kó o máa pọ́n àwọn èèyàn lé àti bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀mí Ò Jọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lójú Mọ́!

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa bó o ṣe lè fi hàn pé o mọyì ẹ̀mí ẹ àti tàwọn ẹlòmí ì.

Ìwà Àpọ́nlé Ti Dàwátì Nínú Ọ̀pọ̀ Ìdílé!

Táwọn tó wà nínú ìdílé bá ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, wọ́n á túbọ̀ máa láyọ̀.

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ò Níyì Lójú Ara Wọn Mọ́!

Bíbélì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa hùwà tó dáa, kí wọ́n tún níyì lójú ara wọn, ìyẹn sì ń jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn.

Ṣé Ìwà Àpọ́nlé Ò Ti Dàwátì Báyìí?

Nínú ìwé yìí, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè máa pọ́nni lé àtohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa pọ́nni lé.