Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Ò Jọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lójú Mọ́!

Ẹ̀mí Ò Jọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lójú Mọ́!

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÍ Ẹ̀MÍ JỌ Ẹ́ LÓJÚ

Tẹ́nì kan bá ń ṣe ohun tó lè pa á lára tàbí ohun tó lè ṣàkóbá fáwọn ẹlòmíì, ìyẹn máa fi hàn pé ẹ̀mí ò jọ ọ́ lójú.

  • Sìgá mímu máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, ó sì máa ń mú kó nira fún àgọ́ ara èèyàn láti gbógun ti àrùn náà. Ìwádìí kan fi hàn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀fóró pa ló jẹ́ pé sìgá mímu ló fà á tàbí kí wọ́n sábà máa wà nítòsí ẹni tó ń fa sìgá.

  • Ọdọọdún là ń gbọ́ròyìn nípa bí wọ́n ṣe ń yìnbọn pa ọ̀pọ̀ èèyàn, ìyẹn sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Ìròyìn kan láti Stanford University sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá wà nílé ìwé táwọn jàǹdùkú ti wá yìnbọn, tẹ́ni náà ò bá tiẹ̀ fara pa, ọ̀pọ̀ ọdún lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn á fi wà lọ́kàn ẹ̀, táá sì máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá a.”

  • Tẹ́nì kan tó ti mutí yó tàbí tó lo oògùn olóró bá ń wa mọ́tò, ó lè ṣàkóbá fáwọn awakọ̀ míì tí wọ́n jọ wà lójú títì. Kódà, ó lè fi ẹ̀mí àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà sínú ewu. Táwọn èèyàn bá ń ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ̀mí ò jọ wọ́n lójú, àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ló sábà máa ń jìyà ẹ̀.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Yẹra fún ohun tó lè pa ẹ́ lára. O ṣì lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó lè ṣàkóbá fún ìlera ẹ, irú bíi sìgá mímu, ọtí àmujù, lílo oògùn olóró, tàbí mímu sìgá tí wọ́n ń fi páìpù fà. Ńṣe nirú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń bani láyé jẹ́, ó sì máa fi hàn pé ẹ̀mí àwọn tó wà láyìíká ẹ ò jọ ẹ́ lójú, títí kan tàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ.

“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ààbò jẹ ẹ́ lógún. Máa ṣàtúnṣe tó yẹ nínú ilé ẹ, kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀. Má ṣe máa wakọ̀ níwàkuwà, sì rí i pé ò ń tún ohun tó bá bà jẹ́ nínú ọkọ̀ ẹ ṣe. Má jẹ́ káwọn èèyàn tì ẹ́ láti ṣe ohun tó lè wu ẹ́ léwu tàbí ohun tó lè gbẹ̀mí ẹ.

“Tí o bá kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ, kí o má bàa mú kí ilé rẹ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹnì kan já bọ́ látorí rẹ̀.”—Diutarónómì 22:8. a

Máa hùwà tó dáa sáwọn èèyàn. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé ẹ̀mí àwọn èèyàn jọ wá lójú ni pé ká máa hùwà tó dáa sí wọn láìka àṣà wọn, ẹ̀yà wọn, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. A ò sì ní máa wò ó bóyá wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà, bóyá wọ́n kàwé tàbí wọn ò kàwé. Ó ṣe tán, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìkórìíra ló sábà máa ń fa ogun àti báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ìkà síra wọn kárí ayé.

“Ẹ mú gbogbo inú burúkú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín, títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe. Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín.”—Éfésù 4:31, 32.

OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè yẹra fáwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún ìlera wọn. Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti di bárakú fún wọn, àtàwọn ìwà burúkú tó lè ṣàkóbá fún wọn.

A kì í fọ̀rọ̀ ààbò ṣeré rárá láwọn ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé. Tá a bá ń kọ́ àwọn ilé ìpàdé wa tàbí àwọn ilé míì tá à ń lò láti mú kí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ síwájú, a máa ń rí i pé a kọ́ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láwọn ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa fara pa. Léraléra la máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ilé wa, ká lè rí i pé ó wà níbàámu pẹ̀lú òfin tí ìjọba ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò.

A máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, láàárín oṣù méjìlá péré, a ṣèrànwọ́ ní ibi ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn àjálù tó lágbára ti ṣẹlẹ̀ kárí ayé, a sì ná nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá dọ́là (ó lé ní bílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún náírà) lára owó táwọn ará wa fi ṣètọrẹ, ká lè pèsè ohun táwọn tí àjálù náà dé bá nílò.

Nígbà tí àrùn Ebola bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn nípakúpa ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà lọ́dún 2014 àti ní Democratic Republic of Congo lọ́dún 2018, a kọ́ àwọn èèyàn láwọn ohun tí wọ́n lè ṣe, kí wọ́n lè dènà àrùn burúkú náà. A rán àwọn aṣojú lọ sáwọn àwùjọ kéékèèké kí wọ́n lè lọ sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó sọ pé “Ìgbọràn Ń Dáàbò Boni.” A ṣètò ibi táwọn èèyàn ti lè máa fọwọ́ sí ẹnu ọ̀nà àwọn ilé ìpàdé wa, a jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí wọ́n máa fọ ọwọ́, a sì tún jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan míì tí wọ́n lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn.

Nínú ìkéde kan tí wọ́n ṣe lórí rédíò ní Sierra Leone, wọ́n gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún bí wọ́n ṣe ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó àrùn Ebola.

Ibi tí wọ́n ti ń fọwọ́ ní ilé ìpàdé kan ní Liberia nígbà tí àrùn Ebola ń jà lọ́dún 2014

a Báwọn tó ń gbé lápá Middle East ṣe ń tẹ̀ lé òfin yìí nígbà àtijọ́ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ààbò ìdílé wọn àti tàwọn ẹlòmíì jẹ wọ́n lógún.