Ìwà Àpọ́nlé Ti Dàwátì Nínú Ọ̀pọ̀ Ìdílé!
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁWỌN TÓ WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÚN ARA WỌN
Táwọn tó wà nínú ìdílé bá ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àlàáfíà á jọba, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n.
-
Ìwé The Seven Principles for Making Marriage Work sọ pé tí tọkọtaya bá ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, wọ́n á túbọ̀ mọyì ara wọn, wọ́n á sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn “nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe lójoojúmọ́, kódà nínú àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan.”
-
Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọdé tó bá ń bọ̀wọ̀ fúnni máa ń níyì lójú ara wọn, wọ́n máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ní àárẹ̀ ọpọlọ.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tẹ́ ẹ máa ṣe nínú ìdílé yín. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ rí i pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé yín ló mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa “bọ̀wọ̀” fúnni. Ìkejì, ẹ kọ àwọn ìwà tẹ́ ẹ fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé yín máa hù àtàwọn tẹ́ ọ̀ fẹ́ kí wọ́n máa hù. Ìkẹta, ẹ jọ jíròrò àwọn nǹkan yìí nínú ìdílé yín kí gbogbo yín lè mọ bẹ́ ẹ ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ara yín.
Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ṣé o máa ń ṣàríwísí àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ tí wọ́n bá ṣàṣìṣe? Ṣé o máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá sọ èrò wọn? Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ṣé o kì í já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ wọn lẹ́nu tàbí kó o mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bíi pé o ò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ? Fi sọ́kàn pé tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn á rọrùn fún wọn láti máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.
Ohun tó o lè ṣe: Má retí pé ohun tí ẹnì kejì ẹ tàbí àwọn ọmọ ẹ bá ṣe láá mú kó o máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, múra tán láti máa bọ̀wọ̀ fún wọn ní gbogbo ìgbà.
Máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn tó ò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò wọn. Tó o bá ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, má ṣe máa lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “gbogbo ìgbà lo máa ń” tàbí “kò sígbà tó o.” Ńṣe nirú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń buni kù, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ, ó sì lè sọ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di bàbàrà.
OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rọ àwọn tó wà nínú ìdílé pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. A sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àwọn àpilẹ̀kọ, ìwé àtàwọn fídíò tá à ń gbé jáde, ọ̀fẹ́ sì ni gbogbo ẹ̀.
ÀWỌN TỌKỌTAYA: Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ . . .
-
bí wọ́n ṣe lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa
-
bí wọ́n ṣe lè jáwọ́ nínú bíbá ara wọn yan odì
-
bí wọ́n ṣe lè jáwọ́ nínú bíbá ara wọn jiyàn
(Wá “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” lórí jw.org)
ÀWỌN ÒBÍ: Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn . . .
-
bí wọ́n ṣe lè jẹ́ onígbọràn
-
bí wọ́n ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé
-
bí wọ́n ṣe lè máa sọ “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun”
(Wá “Ọmọ Títọ́” àti “Bó O Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọ̀dọ́” lórí jw.org)
Tún wo àfikún náà “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè,” nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní. (Wá “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè” lórí jw.org)
ÀWỌN Ọ̀DỌ́: Ní abala Ọ̀dọ́ lórí jw.org, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ, àwọn fídíò àtàwọn ìwé àjákọ tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ . . .
-
bí wọ́n ṣe lè lájọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn
-
bí wọ́n ṣe lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tí wọ́n ṣe
-
bí wọ́n ṣe lè jẹ́ káwọn òbí wọn fọkàn tán wọn
(Wá “Ọ̀dọ́” lórí jw.org)
O ò ní sanwó tó o bá fẹ́ lo jw.org. Kò sí pé ò ń san owó sílẹ̀ kó o tó lè lo ìkànnì náà, o ò sì nílò láti forúkọ sílẹ̀ tàbí kó o sọ ìsọfúnni nípa ara ẹ.