Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ò Níyì Lójú Ara Wọn Mọ́!

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ò Níyì Lójú Ara Wọn Mọ́!

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÉÈYÀN NÍYÌ LÓJÚ ARA Ẹ̀

Àwọn tó bá níyì lójú ara wọn kì í kọ́kàn sókè tí wọ́n bá níṣòro, nǹkan kì í sì í tètè tojú sú wọn.

  • Ìwádìí fi hàn pé àwọn tí kò bá níyì lójú ara wọn máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sábà máa ń ṣàníyàn, wọ́n máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, wọ́n máa ń jẹun jù tàbí kí wọ́n má jẹun dáadáa. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń lo oògùn olóró, wọ́n sì lè máa mu ọtí lámujù.

  • Àwọn tó bá níyì lójú ara wọn máa ń mọ̀wọ̀n ara wọn, torí náà wọn kì í fi ara wọn wé àwọn míì. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àmọ́, àwọn tí kò bá níyì lójú ara wọn sábà máa ń kanra, wọ́n máa ń ṣàríwísí, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wọn.

  • Táwọn tó níyì lójú ara wọn bá tiẹ̀ níṣòro, wọ́n máa ń láforítì. Tí wọ́n bá pinnu láti ṣe ohun kan, wọn kì í jẹ́ kí ìṣòro tó bá yọjú dí wọn lọ́wọ́. Àmọ́, táwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ níyì lójú ara wọn bá tiẹ̀ ní ìṣòro tí kò tó nǹkan, ńṣe ni wọ́n máa ń kà á sí nǹkan bàbàrà. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí nǹkan tètè sú wọn.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Àwọn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni kó o mú lọ́rẹ̀ẹ́. Kó o tó mú ẹnì kan lọ́rẹ̀ẹ́, rí i pé ẹni náà máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, ó ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ ẹ sì jẹ ẹ́ lógún.

“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.

Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, títí kan àwọn tí kò lè san án pa dà fún ẹ, wàá láyọ̀, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. Inú ẹ á máa dùn táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ mọyì ohun tó o ṣe.

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ bí wọ́n ṣe lè níyì lójú ara wọn. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé táwọn ọmọ ẹ bá níṣòro, jẹ́ kí wọ́n máa yanjú ẹ̀ débi tágbára wọn gbé e dé. Ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé mọ bí wọ́n ṣe lè fara da ìṣòro àti bí wọ́n ṣe lè yanjú ẹ̀. Àwọn nǹkan yìí á jẹ́ kí wọ́n níyì lójú ara wọn, á sì túbọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

“Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6, àlàyé ìsàlẹ̀.

OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE

Láwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí wọ́n lè ṣe káyé wọn lè dáa. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n máa wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.

ÀWỌN ÌPÀDÉ WA

Láwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń gbọ́ àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì tó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe ká lè níyì lójú ara wa. Gbogbo èèyàn ló lè wá sáwọn ìpàdé wa, a kì í sì í gbégbá ọrẹ níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ láwọn ìpàdé wa, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa . . .

  • ohun tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún

  • béèyàn ṣe lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀

  • bó o ṣe lè láwọn ọ̀rẹ́ tó máa wà pẹ́ títí

Wàá tún rí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì ń “ṣìkẹ́ ara wọn.”—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.

Kó o lè mọ àwọn nǹkan tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa, wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? lórí jw.org.

ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

A máa ń lo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Nínú ìwé náà, wàá ráwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì, àwọn àlàyé àtàwọn ìbéèrè táá mú kó o ronú jinlẹ̀, àwọn fídíò àtàwọn àwòrán lóríṣiríṣi. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń hùwà tó dáa, wọ́n sì níyì lójú ara wọn.

Kó o lè mọ àǹfààní tó o máa rí tó o bá jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí jw.org.