Ṣé Ìwà Àpọ́nlé Ò Ti Dàwátì Báyìí?
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA PỌ́N ÀWỌN ÈÈYÀN LÉ
Tá a bá ń pọ́n àwọn èèyàn lé, inú wọn á máa dùn sí wa, ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan ò sì ní máa di wàhálà láàárín wa.
-
Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Tá a bá ń hùwà àfojúdi sáwọn èèyàn, tá a sì ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé a ò pọ́n wọn lé, ìyẹn lè múnú bí wọn, ó sì lè jẹ́ kí nǹkan bà jẹ́ kọjá àtúnṣe.
-
Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tá a bá sọ sẹ́nì kan sábà máa ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Ó lè fi hàn pé a ò gba tẹni náà torí pé ẹ̀yà ẹ̀, èdè tó ń sọ, orílẹ̀-èdè tó ti wá tàbí ipò tó wà láwùjọ yàtọ̀ sí tiwa.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dọ̀ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) èèyàn ní orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n (28), ó ju ìdajì lára wọn tó sọ pé kò tíì sígbà táwọn èèyàn ń hùwà àfojúdi bíi ti àsìkò wa yìí.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Tó o bá wà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́, ó yẹ kó o máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn, tó ò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò wọn. Ronú jinlẹ̀ kó o lè ríbi tí èrò ìwọ àti tàwọn èèyàn ti jọra. Ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ṣàríwísí wọn tàbí kó o máa dá wọn lẹ́jọ́.
Ohun tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí ẹ ni kó o máa ṣe sí wọn. Tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, tó ò sì ṣojúsàájú, ó máa wu àwọn náà kí wọ́n ṣe dáadáa sí ẹ.
Máa dárí jini. Tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó dùn ẹ́, má ronú pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ múnú bí ẹ.
OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ládùúgbò wa àti níbi tá a ti ń ṣiṣẹ́, a sì ń rọ àwọn èèyàn pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.
À ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo èèyàn ló láǹfààní láti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí, àmọ́ a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti fara mọ́ èrò wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn a máa ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé ká bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:15; 2 Tímótì 2:24.
A kì í ṣojúsàájú, gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló lè wá sáwọn ìpàdé wa. A máa gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, láìka bí wọ́n ṣe rí tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. A máa ń gbìyànjú láti “bọ̀wọ̀ fún gbogbo enìyàn” tá ò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò wọn.—1 Pétérù 2:17, Bíbélì Yorùbá.
A máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè tá à ń gbé. (Róòmù 13:1) A máa ń pa òfin mọ́, a sì ń san owó orí. Òótọ́ ni pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ ogun tàbí ọ̀rọ̀ òṣèlú, síbẹ̀ a mọ̀ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló lómìnira láti pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí.