Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tó o bá láwọn ìwà tó dáa, tí ìṣòro bá dé wàá dúró digbí

ÀWỌN Ọ̀DỌ́

9: Ẹni Tó O Jẹ́

9: Ẹni Tó O Jẹ́

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Kì í ṣe orúkọ rẹ tàbí ìrísí rẹ la fi máa mọ irú ẹni tó o jẹ́. Ìwà tó ò ń hù, ohun tó o gbà gbọ́ àti bó o ṣe ń ronú ló máa sọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tó o bá mọ irú ẹni tó o jẹ́ ní ti gidi, wàá dúró lórí ohun tó o gbà gbọ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ò sì ní máa darí rẹ síbi tó wù wọ́n.

“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló dà bíi bèbí tí wọ́n fi ń polówó aṣọ. Àwọn ẹlòmíì ló máa ń yan aṣọ tí wọ́n máa wọ̀.”​—Adrian.

“Mo ti kọ́ bí mo ṣe lè máa ṣe ohun tó tọ́ kódà nígbà tí kò bá rọrùn láti ṣe. Mo mọ àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí mo ní, bí wọ́n ṣe ń hùwà sí mi ló jẹ́ kí n mọ̀, ó sì ní bí èmi náà ṣe ń ṣe tí mo bá wà pẹ̀lú wọn.”​—Courtney.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.’​—Róòmù 12:2.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ìsinsìnyí ló yẹ kó o mọ irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tó o fẹ́ dà. Bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o mọ àwọn ibi tó o dáa sí, àwọn ibi tó ti yẹ kó o ṣàtúnṣe àti ohun tó jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lójú. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Ibi tó o dára sí: Àwọn nǹkan wo ni mo mọ̀ ọ́ń ṣe? Kí làwọn èèyàn mọ̀ nípa mi? (Bí àpẹẹrẹ: Ṣe mo máa ń fi nǹkan falẹ̀? Ṣé mo máa ń kó ara mi ní ìjánu? Ṣe mo máa ń ṣiṣẹ́ kára? Ṣé mo lawọ́?) Àwọn nǹkan dáadáa wo ni mo máa ń ṣe?

ÀBÁ: Tó bá ṣòro fún ẹ láti mọ àwọn nǹkan dáadáa tó o máa ń ṣe, ohun tó o lè ṣe rèé. Lọ bá àwọn òbí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tó o fọkàn tán, ní kí wọ́n sọ àwọn ibi tó o dára sí àti ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”Gálátíà 6:4.

Àwọn ibi tó o kù sí: Kí ló yẹ kí ń ṣàtúnṣe sí nínú ìwà mi? Àwọn ìgbà wo ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n ṣe nǹkan tí kò dára? Àwọn apá ibo ló yẹ kí n ti túbọ̀ máa kó ara mi ní ìjánu?

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,’ a ń ṣi ara wa lọ́nà ni.”​—1 Jòhánù 1:8.

Ohun tó o gbà gbọ́: Àwọn ìlànà wo ni mò ń tẹ̀ lé, kí sì nìdí? Ṣé mo gbà pé Ọlọ́run wà? Àwọn ẹ̀rí wo ni mo rí ti mo fi gbà pé Ọlọ́run wà? Àwọn nǹkan wo ni mò ń rí tí mo kà sí ìwà ìrẹ́jẹ, kí sì nìdí? Àwọn nǹkan wo ni mo gbà pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.”​—Òwe 2:11.