Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀

Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀

Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

A máa ń gbọ́ nípa ohun tó fà á táwọn ìdílé kan fi tú ká. Àmọ́ àwọn ìdílé tó ń láyọ̀ ńkọ́, kí ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Láàárín ọdún 1990 sí 2015, iye àwọn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún [50] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ìlọ́po méjì ju ti tẹ́lẹ̀, nígbà tí àwọn tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́ta.

  • Àwọn òbí ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́: Àwọn kan sọ pé kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà, àwọn míì sọ pé kí wọ́n má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ fún wọn rárá.

  • Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé . . .

  • Ìdílé lè láyọ̀, kó sì wà pẹ́ títí.

  • Àwọn òbí lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí.

  • Àwọn ọ̀dọ́ sì lè kọ́ àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ẹ̀dà Jí! yìí máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méjìlá tó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ láyọ̀.