JÍ! No. 2 2020 | Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Ń Jẹ Aráyé?
Oríṣiríṣi nǹkan ló lè fìyà jẹni láyé, a ò sì ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. Ó lè jẹ́ ogun, àìsàn, jàǹbá tàbí àwọn àjálù bí àkúnya omi àti ìjì líle.
Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ìdí tá a fi ń jìyà.
Àwọn kan sọ pé wọ́n kádàrá ìyà mọ́ wa ni, kò sì sóhun tẹ́nì kankan lè ṣe nípa ẹ̀.
Àwọn míì gbà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá ń jìyà, á jẹ́ nítorí pé ẹni náà ti ṣe ohun tí kò dáa láyé yìí tàbí nígbà tó kọ́kọ́ wáyé.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ ìdí tí ìyà fi ń jẹ aráyé, àmọ́ wọn ò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ohun Táwọn Kan Gbà Gbọ́
Wo ohun tí oríṣiríṣi ẹ̀sìn sọ nípa ìdí tá a fi ń jìyà.
1 Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
Wọ́n ti kọ́ àwọn èèyàn ni ohun tí kò jóòótọ́ nípa Ọlọ́run. Kí ni òtítọ́?
2 Ṣé Àwa La Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
Tó bá jẹ́ pé àwa la lẹ̀bi, á jẹ́ pé a lè mú àwọn ìyà kan tó ń jẹ wá kúrò.
3 Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Rere Fi Ń Jìyà?
Bibeli je ka mo idahun re.
4 Ṣé Látìbẹ̀rẹ̀ Ni Ọlọ́run Ti Dá Wa Pé Ká Máa Jìyà?
Ṣó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run tó dá ayé tó rẹwà yìí ló ń fìyà jẹ wá? Tó bá sì jẹ́pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ ìdí tá a fi n jìyà?
5 Ṣé Ìyà Máa Dópin?
Bíbélì sọ fún wa ní pàtó bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìyà kúrò pátápátá.
Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Tó bá tiẹ̀ jọ pé àwọn ìṣòro wa kò ṣeé yanjú, ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára wà tó máa ràn wá lọ́wọ́.