Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

3 Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Rere Fi Ń Jìyà?

3 Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Rere Fi Ń Jìyà?

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì

Tí ẹni rere bá ń jìyà, kò bá ìdájọ́ òdodo mu. Ńṣe nìyẹn máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí èrè nínú kéèyàn máa ṣe rere.

Ronú Lórí Èyí

Àwọn kan gbà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá kú, wọ́n á tún pa dà bí i sáyé. Wọ́n tún sọ pé téèyàn bá ṣe rere, inú ìdẹ̀ra ni wọ́n á pa dà bí i sí, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun burúkú ló ṣe, inú ìyà ni wọ́n máa bí i sí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n ní èèyàn rere lè jìyà tó bá jẹ́ pé ó ti ṣe ohun burúkú nígbà tó “kọ́kọ́ wáyé.” Àmọ́ . . .

  • Àǹfààní wo ló wà nínú ìyà yẹn nígbà tó jẹ́ pé ẹni náà kò tiẹ̀ rántí pé òun ti kọ́kọ́ wáyé?

  • Kí nìdí tá a fi ń sapá láti ní ìlera tó dáa tàbí tá à ń sá fún jàǹbá nígbà tá a mọ̀ pé ohun tá a ṣe nígbà tá a kọ́kọ́ wáyé ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa?

    TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

    Wo fídíò Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ aráyé.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyà lè jẹ ẹnikẹ́ni torí pé ó ṣe kòńgẹ́ aburú tàbí ó wà níbi tí kò yẹ kó wà.

“Ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀, bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí, nítorí ìgbà àti èèṣì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”​ONÍWÀÁSÙ 9:11.

Ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún ń dá kún ìyà tó ń jẹ wá.

Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn gbà pé “ẹ̀ṣẹ̀” jẹ́ ìwà burúkú tẹ́nì kan hù. Àmọ́ Bíbélì tún máa ń lo ọ̀rọ̀ náà láti tọ́ka sí ohun tí gbogbo èèyàn ti jogún, ì báà jẹ́ ẹni rere tàbí ẹni burúkú.

“A bí mi ní ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ni mí látìgbà tí ìyá mi ti lóyún mi.”​SÁÀMÙ 51:5, Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé.

Ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣàkóbá ńlá fún aráyé.

Kì í ṣe àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan ni ẹ̀ṣẹ̀ bà jẹ́, ó tún fa ìyapa sáàárín àwa àtàwọn ohun yòókù tí Ọlọ́run dá. Ìyẹn sì ti yọrí sí baba ńlá ìyà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti aráyé lápapọ̀.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.”​RÓÒMÙ 7:21.

“Gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora.”​RÓÒMÙ 8:22.