Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Táwọn Kan Gbà Gbọ́

Ohun Táwọn Kan Gbà Gbọ́

Àwọn Ẹlẹ́sìn Híńdù

Wọ́n gbà gbọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ń dá báyìí tàbí èyí tó dá nígbà tó kọ́kọ́ wá sáyé ló fa ìyà tó ń jẹ ẹ́. Kí ẹni náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà, ó dìgbà tó bá dé ìpele tí wọ́n ń pè ní moksha, ìyẹn ni ìgbà tí kò ní tún ayé wá mọ́. Nígbà yẹn kò ní ro ohun ti ayé mọ́.

Àwọn Mùsùlùmí

Wọ́n gbà gbọ́ pé ìyà jẹ́ èrè ẹ̀ṣẹ̀ àti àdánwò ìgbàgbọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Sayyid Syeed, tó jẹ́ ààrẹ Islamic Society of North America sọ pé àwọn àjálù ń rán wa létí pé “ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn oore tó ń ṣe fún wa, ó sì tún ń rán wa létí pé ká máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.”

Àwọn Ẹlẹ́sìn Júù

Wọ́n gbà gbọ́ pé àfọwọ́fà ni ìyà tó ń jẹ èèyàn. Àwọn Júù kan sọ pé àjíǹde máa wà, lẹ́yìn náà ni àwọn aláìṣẹ̀ tó ń jìyà máa gba ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹlẹ́sìn Júù tó gbà gbọ́ nínú agbára abàmì gbà pé àtúnwáyé wà, èyí tó máa fún ẹnì kan láǹfààní láti ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́sìn Búdà

Wọ́n gbà gbọ́ pé ẹnì kan á máa jìyà ní gbogbo ìgbà tó bá tún ayé wá àfìgbà tẹ́ni náà bá jáwọ́ nínú ìwà, èrò àti ìfẹ́ ọkàn tí kò dáa. Wọ́n tún sọ pé téèyàn bá ní ọgbọ́n, tó ń ṣiṣẹ́ òdodo, tó sì ń kó èrò rẹ̀ níjàánu, ó máa dé ìpele nirvana, ìyẹn ìgbà tí gbogbo ìyà ẹni náà máa dópin.

Àwọn Ẹlẹ́sìn Confucius

Ìwé kan tó ń jẹ́ Dictionary of Comparative Religion sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Confucius gbà gbọ́ pé “ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe èèyàn” ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú ìyà tó ń jẹ aráyé. Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn sọ pé èèyàn lè dín ìyà náà kù tó bá ń gbé ìgbé ayé òdodo, àmọ́ àwọn “ẹ̀mí tó lágbára ju èèyàn ló lè mú ìyà náà kúrò. Nírú ipò bẹ́ẹ̀ àfi kéèyàn fara mọ́ ohun tí kádàrá ẹ̀ bá sọ.”

Àwọn Ẹlẹ́sìn Ìbílẹ̀

Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn ló ń fa ìyà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé àwọn àjẹ́ lè mú kéèyàn ṣoríire tàbí kí wọ́n ba tèèyàn jẹ́, àfi kéèyàn ṣe ètùtù láti tù wọ́n lójú. Torí náà, nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣàìsàn, àwọn babaláwo máa ń rúbọ tàbí kí wọ́n ṣe oògùn téèyàn lè fi ṣẹ́gun àwọn àjẹ́ náà.

Àwọn Kristẹni

Wọ́n gbà gbọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀dá méjì tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ló fa ìyà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ẹ̀sìn Kristẹni ló ti ṣe àbùmọ́ ẹ̀kọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kátólíìkì sọ pé èèyàn lè fara jìyà láti fi tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ìjọ tàbí pé kó wo ọlá ìyà tẹ́nì kan jẹ láti gba ẹlòmíì là.

TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

Wo fídíò náà Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà? Ó wà lórí jw.org.