Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Ṣé èèyàn rẹ kan kú ni?
Lọ sórí ìkànnì jw.org, kó o sì wá “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀.”
Ṣé ọrọ̀ ajé rẹ ti dẹnu kọlẹ̀?
Lọ sórí ìkànnì jw.org, kó o sì wá “Máa Fọgbọ́n Náwó.”
Ṣé o ti béèrè rí pé, ‘Kí ni mò ń ṣe láyé?’
Lọ sórí ìkànnì jw.org, kó o sì wá “má ṣe jẹ́ káyé sú ẹ” àti “ayé rẹ ṣì máa dùn!”
Ṣé àìsàn tí ò lọ bọ̀rọ̀ ló ń bá ẹ fínra?
Lọ sórí ìkànnì jw.org, kó o sì wá “bí àwọn ìdílé ṣe lè kojú ìṣòro àìsàn bára kú.”
Inú Bíbélì lo ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù lọ nípa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára gan-an. Àwọn ìlànà Bíbélì á jẹ́ kó o túbọ̀ máa ronú dáadáa kó o sì ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.—ÒWE 1:1-4.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ. Wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?