2 Ṣé Àwa La Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
Tó bá jẹ́ pé àwa la lẹ̀bi, á jẹ́ pé a lè mú àwọn ìyà kan tó ń jẹ wá kúrò.
Ronú Lórí Èyí
Èwo lára àwọn ohun tó ń fa ìyà wọ̀nyí làwa èèyàn jẹ̀bi rẹ̀?
-
Ìwà Ìkà.
Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé èèyàn kan nínú mẹ́rin ni wọ́n ti hùwà ìkà sí nígbà tó wà lọ́mọdé. Bákan náà, ọ̀kan nínú obìnrin mẹ́ta ni wọ́n ti hùwà ìkà sí tàbí tí wọ́n ti fipá bá lò pọ̀ rí.
-
Ọ̀fọ̀.
Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde sọ pé: “Kárí ayé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (477,000) èèyàn ni wọ́n pa lọ́dún 2016.” Èyí sì jẹ́ àfikún sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́sàn-án (180,000) tí wọ́n gbà pé wọ́n kú sínú ogun àti ìjà lọ́dún yẹn.
-
Àìlera.
Nínú àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn National Geographic, òǹkọ̀wé Fran Smith sọ pé: “Àwọn tó ń mu sìgá ju bílíọ̀nù kan lọ, sìgá sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fa àrùn márùn-ún tó ń pa èèyàn jù lọ. Àwọn àrùn náà ni: àrùn ọkàn, àrùn rọpárọsẹ̀, àìsàn èémí, àìsàn tó ń mú kí òpó ẹ̀jẹ̀ dí àti jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró.”
-
Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́.
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jay Watts tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú ẹ̀dá sọ pé: “Ipò òṣì, fífojú pa àwọn èèyàn rẹ́, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, èrò pé ọkùnrin lọ̀gá obìnrin, lílé àwọn èèyàn kúrò nílùú àti gbígbé àṣà ìbílẹ̀ kan ga ju ìkejì lọ máa ń kó ìdààmú ọkàn bá èèyàn.”
TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I
Wo fídíò Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwa èèyàn la lẹ̀bi ọ̀pọ̀ lára ìyà tó ń jẹ wá.
Àwọn ìjọba tó ń fìyà jẹ aráàlú ti mú kí ayé nira fáwọn èèyàn tí wọ́n sọ pé àwọn ń bójú tó.
“Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” —ONÍWÀÁSÙ 8:9.
A lè mú àwọn ìyà kan kúrò.
Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ìlera wa á dáa sí i, àá sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn.
“Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun, àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.”—ÒWE 14:30.
“Ẹ mú gbogbo inú burúkú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín, títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.”—ÉFÉSÙ 4:31.