Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlóde Lè Ṣe fún Ìrònú Ẹ?
Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i tí wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe mọ ọ̀pọ̀ nǹkan. Wọ́n ń kọ́ ohun tó máa wúlò fún wọn nílé ìwé, níbi iṣẹ́ tàbí láwọn ọ̀nà míì. Ẹ̀rọ ìgbàlódé sì ti wá mú kíyẹn rọrùn. Láìkúrò nílé rárá, èèyàn lè kọ́ gbogbo ohun tó fẹ́ kọ́, kódà, ó lè má dìde níbi tó jókòó sí.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lálòjù ti rí i pé . . .
-
ó máa ń ṣòro gan-an fún wọn láti pọkàn pọ̀ tí wọ́n bá ń kàwé.
-
wọn kì í lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ kan láìyà sídìí nǹkan míì.
-
nǹkan tètè máa ń sú wọn tí wọ́n bá dá wà.
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
TÓ O BÁ Ń KÀWÉ
Àwọn kan tó máa ń kàwé lórí ẹ̀rọ ìgbàlódé kì í lè fara balẹ̀ ka gbogbo ohun tó wà nínú ìwé tí wọ́n ń kà, ṣe ni wọ́n á kàn fojú wò ó gààràgà, tí wọ́n á sì lọ síbi táwọn kókó kan wà.
Kò burú kéèyàn fojú wòwé gààràgà tó bá jẹ́ pé èèyàn kàn fẹ́ sáré wá ìdáhùn ìbéèrè kan ni. Àmọ́, téèyàn bá jẹ́ kíyẹn lọ mọ́ òun lára, kò ní lè kàwé lọ́nà tí ohun tó ń kà fi máa yé e dáadáa.
RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ara ẹ máa ń balẹ̀ tí apá ibi tó ò ń kà nínú ìwé kan bá pọ̀ díẹ̀? Tó o bá ń fara balẹ̀ kàwé, báwo nìyẹn ṣe lè mú kí ohun tó ò ń kà túbọ̀ yé ẹ?—ÒWE 18:15.
MÁA PỌKÀN PỌ̀
Táwọn kan bá ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, wọ́n máa ń ṣe ohun méjì pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Bí àpẹ̀ẹrẹ, wọ́n lè máa kàwé, kí wọ́n sì tún máa tẹ àtẹ̀jíṣẹ́. Àmọ́, wọ́n lè má ṣe ìkankan yọrí nínú méjèèjì, pàápàá tí ohun méjèèjì bá gba pé kí wọ́n pọkàn pọ̀.
Kò rọrùn láti pọkàn pọ̀ lóòótọ́, àmọ́ tó o bá lè ṣe é, wàá jèrè púpọ̀. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Grace sọ pé: “Ó máa ń dín àṣìṣe àti ìdààmú kù. Ó sàn kéèyàn ṣe ohun kan láṣeyọrí ju kéèyàn wa ọ̀pọ̀ nǹkan máyà kí gbogbo ẹ̀ wá dojú rú.”
RÒ Ó WÒ NÁ: Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, kí lo máa ń ṣe tí kì í jẹ́ kó o lóye ohun tó ò ń kọ́, kó o sì rántí wọn?—ÒWE 17:24.
TÓ O BÁ DÁ WÀ
Táwọn kan bá dá wà níbi tó pa rọ́rọ́, nǹkan kì í pẹ́ sú wọn, wọn á yáa ki ẹ̀rọ ìgbàlódé mọ́lẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ ẹ́, ìgbà yẹn lara wọn á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá balẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Olivia sọ pé: “Tó bá ti ń tó ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tí mi ò rí fóònù tẹ̀, tí mi ò sì rí tẹlifíṣọ̀n wò, nǹkan á ti sú mi.”
Ì báà jẹ́ ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, tá a bá dá wà, a lè fi àsìkò yẹn ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kọ́, ìyẹn sì máa jẹ́ ká ní ìmọ̀ dáadáa.
RÒ Ó WÒ NÁ: Tó o bá dá wà, ṣó o máa ń fi àkókò yẹn ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan pàtàkì?—1 TÍMÓTÌ 4:15.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
BÁWO LO ṢE Ń LO Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ?
Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà lo ẹ̀rọ ìgbàlódé táá mú kó o túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀? Àwọn ọ̀nà wo lo rò pé o lè gbà lò ó táá mú kó ṣòro fún ẹ láti pọkàn pọ̀ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́?
ÌLÀNA BÍBÉLÌ: “Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.”—ÒWE 3:21.