Sún Mọ́ Ọlọ́run
Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìwé mímọ́ ni Bíbélì. Wọ́n ti rí i pé báwọn ṣe ń kà á, táwọn sì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ sílò, ńṣe làwọn túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn lójú.
Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kò ní “ẹ̀mí Ọlọ́run,” ńṣe ló ń tọ́ka sí àwọn tí kò fi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó dáa. (Júùdù 18, 19) Àmọ́ àwọn tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé e. Wọn ò dà bí àwọn ẹni tara tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa tẹ́ ara wọn lọ́rùn nìkan ni wọ́n máa ń rò.—Éfésù 5:1.
ÌRÈTÍ
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.”—Òwe 24:10, àlàyé ìsàlẹ̀.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ìrẹ̀wẹ̀sì kì í jẹ́ ká lókun láti kojú àwọn ìṣòro wa. Àmọ́, tá a bá ní ìrètí, àá ní ìgboyà láti máa fara dà á nìṣó láìbẹ̀rù. Tá a bá ń fi sọ́kàn pé láìròtẹ́lẹ̀ nǹkan lè yí pa dà sí rere, ọkàn wa máa balẹ̀; kódà, ohun rere lè tinú àwọn ìṣòro náà jáde.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Dípò kó o máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀, tàbí kó o máa dúró de àkókò tí gbogbo nǹkan máa pé pérépéré kó o tó ṣe nǹkan, á dáa kó o máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí àwọn àfojúsùn rẹ kọ̀ọ̀kan, torí pé àwọn nǹkan tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nígbàkígbà. (Oníwàásù 9:11) Ká sòótọ́, nǹkan lè pa dà wá dáa ju bá a ṣe rò lọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, nítorí o ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa, bóyá èyí tàbí ìyẹn, ó sì lè jẹ́ àwọn méjèèjì ló máa ṣe dáadáa.”—Oníwàásù 11:6.
ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Fún mi ní òye, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.’—Sáàmù 119:144, 160.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń béèrè. Bí àpẹẹrẹ, ó dáhùn àwọn ìbéèrè bíi:
-
Ibo la ti wá?
-
Kí nìdí tá a fi wà láyé yìí?
-
Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
-
Ṣé ìgbésí ayé ẹ̀dá ò jù báyìí náà lọ?
Àìmọye èèyàn kárí ayé ni ìgbésí ayé wọn ti dára gan-an, torí pé wọ́n ti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì míì.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Ṣèwádìí fúnra ẹ kó o lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá mọ̀ pé kó kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo, tàbí kó o wá sí ìpàdé wa. Gbogbo èèyàn la pè, a kì í gbowó ìwọlé.
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
MÁA WÁ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌ́RUN.
“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—MÁTÍÙ 5:3.
MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ỌLỌ́RUN NÍNÚ BÍBÉLÌ.
“Wá Ọlọ́run . . . wàá sì rí i ní ti gidi . . . kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—ÌṢE 17:27.
KA BÍBÉLÌ, KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀ NÍPA OHUN TÓ WÀ NÍNÚ RẸ̀.
“Òfin Jèhófà * máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń ṣe àṣàrò lórí òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru. . . . Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”—SÁÀMÙ 1:2, 3, àlàyé ìsàlẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 23 Nínú Bíbélì, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.