Sùúrù
Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká sá fún ìbínú òdì àtàwọn ìwà míì tó léwu, ká sì sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó ṣàǹfààní.
ÌBÍNÚ
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju akíkanjú ọkùnrin.”—Òwe 16:32.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Àǹfààní ńlá ló wà nínú kéèyàn máa kápá ìbínú rẹ̀. Nígbà míì, èèyàn lè bínú, àmọ́ ó yẹ kéèyàn máa rántí pé ìbínú òdì máa ń ba nǹkan jẹ́ ni. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé tẹ́nì kan bá ń bínú lọ́wọ́, ó sábà máa ń sọ ohun tí kò yẹ tàbí kó ṣe ohun tó máa pa dà kábàámọ̀.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Máa ṣe sùúrù, kí ìbínú má bàa sọ ẹ́ di ẹrú. Àwọn kan máa ń wo ẹni tó ń bínú sódì bí alágbára èèyàn, àmọ́ ká sòótọ́, àbùkù ló jẹ́ fún ẹni tí kò bá lè kápá ìbínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí ìlú tí a ya wọ̀, tí kò ní ògiri, ni ẹni tí kò lè kápá ìbínú rẹ̀.” (Òwe 25:28) Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà kápá ìbínú wa ni pé ká máa gbìyànjú láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ká tó dá sí i. “Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀.” (Òwe 19:11) Tọ́rọ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká fetí sílẹ̀ dáadáa, ká sì gbọ́ tọ̀tún-tòsì lágbọ̀ọ́yé ká tó ṣe ohunkóhun, ìyẹn ni ò ní jẹ́ ká ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ká ṣìwà hù.
ÌMOORE
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Téèyàn bá ń dúpẹ́ oore, á máa láyọ̀. Kódà àwọn tí aburú ńlá ṣẹlẹ̀ sí pàápàá gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n sọ pé ohun pàtàkì tó jẹ́ káwọn lè ṣọkàn gírí ni pé àwọn gbọ́kàn kúrò lórí ohun táwọn pàdánù, àwọn sì pọkàn pọ̀ sórí oore táwọn lè máa dúpẹ́ fún.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Lójoojúmọ́, máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó o lè dúpẹ́ fún. Kò pọn dandan kó jẹ́ àwọn nǹkan ńlá. O lè ronú nípa àwọn nǹkan tí kò tó
nǹkan lójú ẹlòmíì, ó lè jẹ́ bójú ọ̀run ṣe rí nígbà tí oòrùn yọ, tàbí ńṣe lo gbádùn ọ̀rọ̀ tí ìwọ àti enì kan tó o fẹ́ràn jọ sọ tàbí bó o ṣe ń sùn tó o sì ń jí lójoojúmọ́. Tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan yìí, tó o sì ń dúpẹ́ oore, wàá máa láyọ̀.Àǹfààní tó pọ̀ ni wàá rí tó o bá ń ronú jinlẹ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́ fún ẹbí àti ọ̀rẹ́ tó o ní. Tó o bá rí ohun kan tó o mọyì nípa ẹnì kan, o lè sọ fún ẹni náà, o lè kọ lẹ́tà sí i tàbí kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí fóònù. Ìyẹn máa jẹ́ kí àárín ìwọ àti ẹni náà gún régé sí i, wàá sì láyọ̀ torí pé o ṣe ohun tó mú inú ẹni náà dùn.—Ìṣe 20:35.
ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
YẸRA FÚN ÀRÍYÀNJIYÀN.
“Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dà bí ìgbà téèyàn ṣí ibú omi sílẹ̀; kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”—ÒWE 17:14.
MÁ ṢE MÁA RONÚ JÙ NÍPA ỌJỌ́ Ọ̀LA.
“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”—MÁTÍÙ 6:34.
MÁA RONÚ KÓ O TÓ ṢE NǸKAN.
“Làákàyè yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò sì máa dáàbò bò ọ́.”—ÒWE 2:11.