Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́
Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
Tá a bá ń fojú burúkú wo àwọn kan, a ò ní fẹ́ sún mọ́ wọn, ńṣe nìyẹn á sì mú ká túbọ̀ máa kórìíra wọn. Tó bá sì jẹ́ pé àwọn tá a gbà pé a jọ mọwọ́ ara wa nìkan là ń bá ṣọ̀rẹ́, ńṣe làá máa rò pé èrò, ìwà àti ìṣe wa ló dáa jù.
Ìlànà Bíbélì
“Ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 6:13.
Kí la rí kọ́? “Ọkàn” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Tó bá jẹ́ pé àwọn tá a gbà pé a jọ mọwọ́ ara wa nìkan la máa ń fìfẹ́ hàn sí, ọkàn wa ò ní ṣí sílẹ̀, ìyẹn ni pé kò ní fàyè gba àwọn tó yàtọ̀ sí wa. Kí ìṣòro yẹn má bàa wáyé, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa bá àwọn tó yàtọ̀ sí wa ṣọ̀rẹ́.
Àǹfààní Wà Nínú Ká Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́
Tá a bá ń gbìyànjú láti sún mọ́ àwọn èèyàn, àá mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀. Bá a bá ṣe ń sún mọ́ wọn sí i, tó bá yá, a ò tiẹ̀ ní rántí mọ́ pé inú ẹ̀yà míì ni wọ́n ti wá. Àá wá mọyì wọn gan-an, àá sì máa gba tiwọn rò.
Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Nazaré. Nígbà kan, ó kórìíra àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Ó ṣàlàyé ohun tó mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà, ó ní: “Mo máa ń bá wọn ṣeré, mo sì tún máa ń bá wọn ṣiṣẹ́. Mo wá rí i pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn èèyàn sọ pé wọ́n jẹ́. Tó o bá sún mọ́ àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìẹ, o ò ní máa fojú tí ò dáa wò wọ́n. Wàá nífẹ̀ẹ́ wọn, wàá sì mọyì wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
Ohun To O Lè Ṣe
Máa wá ọ̀nà láti bá àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí èdè tó yàtọ̀ sí tìẹ sọ̀rọ̀. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé:
-
Sọ pé kí wọ́n sọ díẹ̀ nípa ara wọn fún ẹ.
-
Pè wọ́n láti wá bá ẹ jẹun.
-
Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa ara wọn, kó o sì mọ ohun tó jẹ wọ́n lógún.
Tó o bá mọ ohun tójú wọn ti rí, wàá mọ ìdí tí wọ́n fi ń hu àwọn ìwà kan, ìyẹn lè wá jẹ́ kó o fẹ́ràn àwọn tó wá látinú ẹ̀yà yẹn.