ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Kọ́ Ọmọ Rẹ Nípa Ìbálòpọ̀
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn òbí ló máa ń kọ́kọ́ láǹfààní láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Wọ́n sì máa ń ṣàlàyé fún wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, bí ọjọ́ orí ọmọ náà bá ṣe rí.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí. Ìwé The Lolita Effect sọ pé: “Àti kékeré làwọn ọmọ ti ń rí ìsọfúnni nípa ìbálòpọ̀, ńṣe ló sì ń pọ̀ sí i.” Ṣé gbogbo èyí wá ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ ni àbí ó ń pa wọ́n lára?
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
Àwòrán ìṣekúṣe wà káàkiri. Deborah Roffman ṣe ìwé kan tó pè ní Talk to Me First. Nínú ìwé náà ó sọ pé ‘ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ, ìpolówó ọjà, fíìmù, ìwé, ọ̀rọ̀ orin, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àtẹ̀jíṣẹ́, géèmù, pátákó ìpolówó, fóònù àti kọ̀ǹpútà kún fún onírúurú àwòrán ìṣekúṣe, ọ̀rọ̀ rírùn àtàwọn àṣà tí kò tọ́. Èyí sì ń mú kí ọ̀pọ̀ [ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún] gbà pé ìbálòpọ̀ lóhun tó ṣe pàtàkì jù láyé.’
Ẹ̀bi díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn tó ń polówó ọjà. Àwọn tó ń polówó ọjà àtàwọn tó ń tajà máa ń gbé àwọn aṣọ tí kò bójú mu lárugẹ. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn ọmọdé máa ronú kọjá àlà nípa ìrísí wọn. Ìwé kan tó ń jẹ́ Sexy So Soon sọ pé: “Àwọn tó ń polówó ọjà mọ̀ pé àwọn ọmọdé kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́n, torí náà wọ́n máa ń tàn wọ́n jẹ. Kì í ṣe pé wọn fẹ́ lo àwọn àwòrán yẹn láti sún àwọn ọmọdé ṣe ìṣekúṣe,” àmọ́ “bí wọ́n ṣe máa tajà tiwọn ni wọ́n ń wá.”
Ìsọfúnni tí kò kún tó. Bó ṣe jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn mọ bí ọkọ̀ kan ṣe ń ṣiṣẹ́ àti kéèyàn jẹ́ awakọ̀ tó dáńgájíá, bẹ́ẹ̀ náà ni ìyàtọ̀ ṣe wà nínú kéèyàn ní ìmọ̀ nípa ìbálòpọ̀ àti kéèyàn lo ìmọ̀ yẹn láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Àkókò tá a wà yìí ló ṣe pàtàkì jù lọ pé káwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “kọ́ agbára ìwòye wọn” kí wọ́n lè máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Má ṣe dá wọn dá a. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sísọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lè máa fì ẹ́ lẹ́nu, síbẹ̀ o ní láti gbà pé ojúṣe rẹ ni kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa ìbálòpọ̀ jẹ́.
Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan. Dípò tí wàá fi rọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sí ọmọ rẹ lórí lẹ́ẹ̀kan náà, ńṣe ni kó o máa ṣé e díẹ̀díẹ̀. O lè lo àkókò tẹ́ ẹ jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀, bóyá nígbà tí ẹ jọ ṣeré jáde tàbí tẹ́ ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ ilé. Kí ọmọ rẹ lè sọ tinú ẹ̀, ńṣe ní kó o béèrè èrò rẹ̀ nípa nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi sọ pé, “Ṣó o máa ń fẹ́ràn àwọn ìpolówó ọjà tí wọ́n ti máa ń ṣí ara sílẹ̀?” o lè sọ pé, “Kí lo rò pé ó ń mú káwọn tó ń polówó ọjà máa lo irú àwòrán yìí láti fi polówó ọjà wọn?” Tí ọmọ rẹ bá ti dáhùn, o lè sọ pé, “Báwo ló ṣe rí lára ẹ?”
Jẹ́ kó bá ọjọ́ orí rẹ̀ mu. O lè kọ́ ọmọ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ iléèwé ní orúkọ tí àwọn ẹ̀yà ìbímọ ń jẹ́ gangan, àti bí wọ́n ṣe lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, o lè kọ́ wọn nípa béèyàn ṣe ń lóyún tó sì ń bímọ. Tí wọ́n bá ti bàlágà, ó yẹ kí wọ́n ti mọ gbogbo ohun tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ àti bí wọ́n ṣe lè ní èrò tó yẹ nípa ìbálòpọ̀.
Kọ́ wọn ní ìwà rere. Ìgbà tí ọmọ ṣì wà ní kékeré ló yẹ káwọn òbí ti kọ́ ọ nípa jíjẹ́ olóòótọ́, ìwà tó tọ́ àti bíbọ̀wọ̀ fúnni. Tí ẹ bá wá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálópọ̀, ẹ ti máa ní ohun tẹ́ ẹ máa gbé ọ̀rọ̀ yín kà. Bákan náà, jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó o fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tí o bá gbà pé kò tọ̀nà láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, jẹ́ kí wọ́n mọ̀. Kó o sì ṣàlàyé ìdí tí kò fi tọ̀nà àti ewu tó rọ̀ mọ́ ọn. Ìwé Beyond the Big Talk sọ pé: “Táwọn ọmọ bá mọ̀ pé àwọn òbí àwọn kò fọwọ́ sí kí ọmọdé máa ní ìbálòpọ̀, ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti yẹra fún ìbálòpọ̀.”
Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Máa fi ohun tí ò ń kọ́ni ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o máa ń rẹ́rìn-ín sí àpárá rírùn? Ṣé o máa ń wọ aṣọ tó ń ṣí ibi kọ́lọ́fín ara sílẹ̀? Ṣé o máa ń tage? Irú àwọn àṣà yìí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ ka ìwà rere tí ò ń kọ́ wọn sí pàtàkì.
Sọ ohun tó dáa. Ẹ̀bùn ni ìbálòpọ̀ jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ kí àwọn tó ti ṣègbéyàwó gbádùn ara wọn. (Òwe 5:18, 19) Jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ̀ pé tó bá tó àkókò òun náà máa gbádùn ẹ̀bùn yìí. Kó sì mọ̀ pé ìbànújẹ́ àti ìdààmú ni ìbálòpọ̀ láìṣe ìgbéyàwó máa ń fà.