OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ogun
Ní ayé àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jagun ní orúkọ Ọlọ́run wọn Jèhófà. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun táwọn èèyàn ń jà lónìí?
Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ fi máa ń jagun?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ọlọ́run tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ “tó sì fẹ́ràn ogun” ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jọ́sìn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun kún fún ìwà ipá àti àwọn ìwà burúkú bíi kí wọ́n máa bá ẹranko lò pọ̀, kí wọ́n máa bá ìbátan tímọ́tímọ́ lò pọ̀, wọ́n sì tún máa ń fi ọmọ wọn rúbọ. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fún wọn ní àyè tó pọ̀ tó láti yí pa dà, Ọlọ́run sọ pé: “Nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.”—Léfítíkù 18:21-25; Jeremáyà 7:31.
“Ní tìtorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn kúrò níwájú rẹ.”—Diutarónómì 9:5.
Ṣé Ọlọ́run máa ń gbè sẹ́yìn àwọn èèyàn tó ń jagun lónìí?
O LÈ TI KÍYÈSÍ PÉ
Nígbà tí àwọn èèyàn bá ń bá ara wọn jagun, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó gbè sẹ́yìn apá kọ̀ọ̀kan máa ń sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn. Ìdí nìyẹn tí ìwé The Causes of War fi sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ogun tí wọ́n jà tí ẹ ò ní rí ọwọ́ àwọn ẹlẹ́sìn níbẹ̀.”
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn Kristẹni kò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá àwọn ọ̀tá wọn jà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín.”—Róòmù 12:18, 19.
Jésù kò sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa jagun, ohun tó sọ fún wọn ni pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:44, 45) Kódà tí àwọn Kristẹni bá ń gbé ní orílẹ̀ èdè kan tó ń jagun lọ́wọ́, wọn kò gbọdọ̀ bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ogun, torí pé wọn “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ kárí ayé nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ apá kan ayé, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ á tún máa gbè sẹ́yìn àwọn tó ń jagun lónìí?
“Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.”—Jòhánù 18:36.
Ǹjẹ́ ogun lè dópin?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ogun kò lè tán. Ìwé War and Power in the 21st Century sọ pé: “Ogun á máa wà títí lọ ni. Ayé kò lè ní àlàáfíà tó máa tọ́jọ́ lákòókò tá a wà yìí.”
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Tí kò bá wu ẹnikẹ́ni láti jagun mọ́, ogun á tán pátápátá. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tí yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run máa mú gbogbo ohun ìjà kúrò láyé, àwọn èèyàn á sì di ẹni àlàáfíà. Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò “mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá tí ó jìnnà réré. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Míkà 4:3.
Bíbélì kọ́ni pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kò ní sí àwọn ìjọba onímọtara-ẹni tó ń bá ara wọn jagun, kò ní sí ìrẹ́jẹ tó ń mú kí àwọn aráàlú wọ́de tàbí ẹ̀tanu tó ń fa kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Torí náà, kò ní sí ogun mọ́. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
“Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.” —Sáàmù 46:9.