JÍ! No. 6 2017 | Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
Kí nìdí tó fi dà bíi pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe?
Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Ìwé ìròyìn “Jí!” yìí ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?
Ohun tó wà lójú Doomsday Clock báyìí fi hàn pé àkókò yìí ni aráyé sún mọ́ àjálù jù lọ láti ọgọ́ta [60] ọdún tí aago yìí ti ń ka wákàtí! Ṣé lóòótọ́ ni àjálù kan tí aráyé ò rírú ẹ̀ rí máa tó ṣẹlẹ̀?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?—Ohun Tí Àwọn Èèyàn Ń Sọ
Ohun táwọn oníròyìn ń sọ ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Báwo ni ayé yìí tiẹ̀ ṣe bà jẹ́ tó?
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?—Kí ni Bíbélì Sọ?
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ pé ayé yìí máa bà jẹ́ gan-an.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó má sì ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN
Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílè-èdè New Zealand kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ síbẹ̀ nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta [3,000,000] èèyàn ló máa ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ síbẹ̀ lọ́dọọdún. Kí ló mú kí wọ́n máa lọ síbẹ̀?
ÌTÀN ÀTIJỌ́
Alhazen
O lè má tí ì gbọ́ orúkọ rẹ̀ rí, ohun kan ni pé ò ń jàǹfààní lára àwọn iṣẹ́ tí ọkùnrin yìí ti ṣe.
OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Orukọ Ọlọ́run
Oríṣiríṣi orúkọ oyè làwọn èèyàn máa ń pe Ọlọ́run Olódùmarè. Àmọ́, ó ní orúkọ tó ń jẹ́ gangan.
Atọ́ka Àwọn Àkòrí fún Jí! 2017
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àkòrí àpilẹ̀kọ tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2017.
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Jẹ́ Olóòótọ́
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa sọ òótọ́ nígbà gbogbo?
Báwo Lo Ṣe Lè Dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀?
Bíbélì sọ ohun mẹ́sàn-án tá a lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀.