Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

  • Ìgbéraga ọmọkùnrin rẹ ti ń pọ̀ jù lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọmọ ọdún mẹ́wàá péré sì ni!

  • Ńṣe ló fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa gbé òun gẹ̀gẹ̀.

Ọ̀rọ̀ náà tojú sú ẹ, o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ‘kí lọmọ yìí fẹ́ sọ ara ẹ̀ dà yìí? Òótọ́ ni pé mi ò fẹ́ kó máa ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan, síbẹ̀ mi ò tún fẹ́ kó máa rò pé kò sẹ́ni tó dáa tó òun!’

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, síbẹ̀ kí wọ́n ṣì jẹ́ ẹni iyì?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, wọ́n ti gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan táwọn ọmọ bá fẹ́ fún wọn; kí wọ́n máa gbóríyìn fún wọn dáadáa, kódà tí wọn ò bá tiẹ̀ ṣe ohun bàbàrà kan; kí wọ́n má ṣe tọ́ wọn sọ́nà tàbí kí wọ́n bá wọn wí. Èrò wọn ni pé tí wọ́n bá ń gbé àwọn ọmọ gẹ̀gẹ̀ lọ́nà yìí, èyí á mú kí wọ́n dàgbà di ẹni iyì. Àmọ́, kí ni èyí yọrí sí? Ìwé kan tó ń jẹ́ Generation Me sọ pé: “Dípò kí ara àwọn ọmọ náà yá gágá kí wọ́n sì jẹ́ ọmọlúwàbí, ńṣe ni wọ́n ya onímọtara-ẹni-nìkan àti àjọra-ẹni-lójú nítorí bí wọ́n ṣe kẹ́ wọn lákẹ̀ẹ́jù.”

Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni àwọn òbí kàn máa ń gbóríyìn fún àwọn ọmọ wọn ṣáá tí wọn kì í sọ àwọn ibi tó yẹ kí wọ́n ti ṣàtúnṣe fún wọn, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ kì í lè fara dà á táwọn èèyàn bá já wọn kulẹ̀, tí wọ́n bá ṣàríwísí wọn tàbí tí nǹkan ò bá lọ bí wọ́n ṣe fẹ́. Torí pé bí wọ́n ṣe tọ́ irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ti mú kí wọ́n jẹ́ onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọ́n bá dàgbà, wọn kì í lè bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́. Ohun tí èyí sì máa ń fà ni pé irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ní ìdààmú ọkàn.

Ohun tó ń sọ àwọn ọmọ di ẹni iyì kọ́ ni pé káwọn òbí máa sọ fún wọn nígbà gbogbo pé ẹni iyì ni wọ́n, àmọ́ táwọn ọmọ bá ń gbé àwọn nǹkan gidi ṣe ní tòótọ́, ìyẹn lè sọ wọ́n dẹni iyì. Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn gbà pé ẹni iyì làwọn, ó tún yẹ kí wọ́n kọ́ iṣẹ́ kan, kí wọ́n máa fi iṣẹ́ náà dánra wò, kí wọ́n sì máa dára sí i lẹ́nu iṣẹ́ náà. (Òwe 22:29) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ àwọn lógun. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Àfi kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tó lè ṣe irú àwọn nǹkan yìí.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gbóríyìn fún un tó bá yẹ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Tí ọmọbìnrin rẹ bá ṣe dáadáa níléèwé, gbóríyìn fún un. Tó bá jẹ́ pé kò ṣe dáadáa, má ṣe dá olùkọ́ rẹ̀ lẹ́bi. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ọmọ rẹ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ńṣe ni kó o jẹ́ kó mọ bó ṣe lè ṣe dáadáa nígbà míì. Ìgbà tó bá ṣe nǹkan tó yẹ fún oríyìn lóòótọ́ ni kó o gbóríyìn fún un.

Bá a wí nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé kó o máa bá a wí lórí gbogbo àṣìṣe tó bá ṣe. (Kólósè 3:21) Àmọ́ tó bá ṣe nǹkan tí kò dáa rárá, rí i pé o bá a wí. Èyí tún kan àwọn ìwàkíwà míì tí ọmọ rẹ lè ní, ńṣe ni kó o máa tètè bá a wí, kó má bàa di ẹni tí apá ò ká mọ́.

Bí àpẹẹrẹ, o lè kíyè sí pé ọmọkùnrinrin rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo kàn ń wò ó níran, ìgbéraga lè wọ̀ ọ́ lẹ́wù gan-an débi pé kò ní fẹ́ máa bá àwọn míì ṣe. Torí náà, jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ìgbéraga lè sọ ọ́ di èèyàn burúkú, ó sì lè mú káwọn èèyàn kàn án lábùkù. (Òwe 27:2) Tún jẹ́ kó mọ̀ pé tó bá ti di pé ẹnì kan ń fọ́nnu nípa àwọn nǹkan tó mọ̀-ọ́n ṣe, onítọ̀hún ti ń ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nìyẹn. Tó o bá fi ìfẹ́ tọ́ ọ sọ́nà, èyí á jẹ́ kó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, á sì di ẹni iyì.​—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 23:12.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ó lè kojú ìṣòro. Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí ọmọ rẹ bá ṣáà ti béèrè náà lo máa ń fún un, ó lè máa rò pé ẹ̀tọ́ òun ni pé kí ọwọ́ òun tẹ gbogbo ohun tí òun ń fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá béèrè ohun kan tí owó ìwọ òbí rẹ̀ kò ká, jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa ṣọ́wó ná. Tó bá jẹ́ pé ẹ jọ fẹ́ lọ síbì kan tẹ́lẹ̀ àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tí kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ lè lọ mọ́, o lè ṣàlàyé fún un pé nǹkan kì í rí bá a ṣe rò nígbà míì, o sì tún lè jẹ́ kó mọ ohun tí ìwọ fúnra rẹ máa ń ṣe nígbà tí ìjákulẹ̀ bá wáyé. Dípò tí wàá fi máa dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tó bá ṣáà ti yọjú, ńṣe ni kó o jẹ́ kó mọ àwọn ìṣòro tó lè wáyé bó ṣe ń dàgbà àti bó ṣe lè kojú wọn. Ìlànà Bíbélì: Òwe 29:21.

Kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ ọ̀làwọ́. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ lè jọ kọ orúkọ àwọn kan sílẹ̀ tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́, bóyá tẹ́ ẹ lè lọ bá ra nǹkan lọ́jà, tẹ́ ẹ lè lọ fi ọkọ̀ gbé tàbí tẹ́ ẹ lè bá tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Kó o sì mú ọmọ rẹ dání nígbà tó o bá fẹ́ lọ ran àwọn ẹni náà lọ́wọ́. Jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé inú ìwọ òbí rẹ̀ ń dùn, ọkàn rẹ sì balẹ̀ bó o ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń kọ́ ọmọ rẹ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lọ́nà tó dáa jù lọ, ìyẹn nípa àpẹẹrẹ ìwọ fúnra rẹ.​—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 6:38.