Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?

‘Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.’​—KÓL. 3:15.

ORIN 46 A Dúpẹ́, Jèhófà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo ni ará Samáríà tí Jésù wò sàn ṣe dúpẹ́ oore?

ÀWỌN ọkùnrin mẹ́wàá kan wà tí wọ́n jẹ́ adẹ́tẹ̀. Wọ́n ń wá ìwòsàn lójú méjèèjì, àmọ́ kò jọ pé wọ́n á rí ẹni ràn wọ́n lọ́wọ́. Lọ́jọ́ kan, wọ́n rí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà látọ̀ọ́kán. Wọ́n ti gbọ́ pé onírúurú àìsàn ni Jésù máa ń wò, torí náà ó dá wọn lójú pé á wo àwọn náà sàn. Wọ́n wá kígbe pé: “Jésù, Olùkọ́ni, ṣàánú fún wa!” Bí wọ́n ṣe rí ìwòsàn gbà nìyẹn o. Kò sí àní-àní pé gbogbo wọn ló mọyì ohun tí Jésù ṣe fún wọn. Àmọ́, ẹnì kan ṣoṣo péré ló pà dá wá dúpẹ́ * oore tí Jésù ṣe fún un. Ó ṣe kedere pé kì í wulẹ̀ ṣe pé ará Samáríà yẹn moore nìkan, kódà ó “fi ohùn rara” yin Ọlọ́run lógo.​—Lúùkù 17:12-19.

2-3. (a) Kí ni kì í sábà jẹ́ kéèyàn dúpẹ́ oore? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Bíi ti ará Samáríà yẹn, ó máa ń wù wá pé ká dúpẹ́ oore táwọn èèyàn ṣe fún wa. Àmọ́ nígbà míì, a lè má rántí dúpẹ́ oore náà.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi hàn pé a moore, lọ́rọ̀ àti níṣe. Àá gbé àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n dúpẹ́ oore yẹ̀ wò nínú Bíbélì àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà pàtó tá a lè gbà fi hàn pé a moore.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA FI ÌMOORE HÀN?

4-5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìmoore hàn?

4 Tó bá di pé ká fẹ̀mí ìmoore hàn, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Jèhófà. Àbí, kí nìdí tí Jèhófà fi ń bù kún àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Kò sí àní-àní, torí pé ó mọyì ohun tí wọ́n ṣe ni. (2 Sám. 22:21; Sm. 13:6; Mát. 10:40, 41) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbà wá níyànjú pé ká “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfé. 5:1) Torí náà, ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ oore ni pé a fẹ́ fara wé Jèhófà.

5 Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ìdí míì tó fi yẹ ká máa fi ìmoore hàn. Téèyàn bá mọyì oore tí wọ́n ṣe é àmọ́ tí kò fi í hàn, ṣe ló dà bí ẹni tó ń dá jẹ oúnjẹ aládùn. Àmọ́ téèyàn bá fi ìmoore hàn, ṣe ló dà bí ẹni tó ní káwọn míì bá òun jẹ nínú oúnjẹ náà, ó ṣe tán wọ́n sọ pé àjọjẹ ló máa ń dùn. Tó bá hàn sí wa pé àwọn èèyàn mọyì wa tàbí ohun tá a ṣe fún wọn, inú wa máa ń dùn. Táwa náà bá ń fi hàn pé a moore, a máa múnú àwọn míì dùn. Ẹni tó ṣe wá lóore tá a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ á mọ̀ pé a mọyì òun, á sì gbà pé ìsapá òun kò já sásán. Nípa bẹ́ẹ̀, okùn ọ̀rẹ́ wa á túbọ̀ lágbára.

6. Báwo ni ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ ṣe jọra pẹ̀lú èso ápù tó jẹ́ góòlù?

6 Ohun iyì ni téèyàn bá ń dúpẹ́ oore. Bíbélì sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Báwo lẹ rò pó ṣe máa rí tí wọ́n bá fi èso ápù tó jẹ́ góòlù sínú àwo fàdákà? Ǹjẹ́ kò ní dùn ún wò? Kódà, àrímáleèlọ ni! Jẹ́ ká sọ pé wọ́n firú ẹ̀ ta ẹ́ lọ́rẹ, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Bó o ṣe mọyì ápù góòlù yẹn náà làwọn èèyàn ṣe máa mọyì ẹ̀mí ìmoore tó o bá fi hàn. Kókó míì rèé o: Tí wọ́n bá fún ẹnì kan nírú ápù bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ṣe lá tọ́jú ẹ̀ pa mọ́, kò sì ní jẹ́ kó sọnù láé. Lọ́nà kan náà, tá a bá fi ìmoore hàn fún ohun tẹ́nì kan ṣe fún wa, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ lá máa rántí.

WỌ́N FI ÌMOORE HÀN

7. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 27:4, báwo ni Dáfídì àtàwọn míì tó kọ Sáàmù ṣe fi hàn pé àwọn moore?

7 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ ló fi hàn pé àwọn moore. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì. (Ka Sáàmù 27:4.) Ó mọyì ìjọsìn Jèhófà gan-an, ó sì fi hàn bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìmọye nǹkan olówó ńlá ló fi ṣètọrẹ fún iṣẹ́ tẹ́ńpìlì kíkọ́. Àwọn ọmọ Ásáfù náà fi hàn pé àwọn moore nígbà tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn orin ìyìn, ìyẹn àwọn sáàmù. Nínú ọ̀kan lára orin tí wọ́n kọ, wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì sọ pé àwọn mọyì “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” Jèhófà. (Sm. 75:1) Ó ṣe kedere pé Dáfídì àtàwọn ọmọ Ásáfù fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé àwọn mọyì gbogbo bó ṣe bù kún wọn. Àwọn ọ̀nà wo nìwọ náà lè gbà fi hàn pé o moore bíi tàwọn tó kọ sáàmù yìí?

Kí la rí kọ́ nínú lẹ́tà ìmọrírì tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù? (Wo ìpínrọ̀ 8-9) *

8-9. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mọyì àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí nìyẹn sì yọrí sí?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sì hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ nípa wọn. Ìgbà gbogbo ló máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí wọn. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun mọyì wọn nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹsẹ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àkọ́kọ́ nínú ìwé Róòmù orí kẹrìndínlógún (16), ó dárúkọ àwọn ará mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) láìfi ọ̀kan pe méjì. Pọ́ọ̀lù dìídì sọ̀rọ̀ Pírísíkà àti Ákúílà pé “wọ́n fi ọrùn ara wọn wewu” nítorí òun, ó sì sọ pé Fébè jẹ́ “olùgbèjà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,” títí kan òun. Ó gbóríyìn fún àwọn ará tó wà níjọ yẹn lọ́kùnrin àti lóbìnrin fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe.​—Róòmù 16:1-15.

9 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé aláìpé làwọn ará tó wà nínú ìjọ Róòmù, síbẹ̀ nígbà tó ń parí lẹ́tà rẹ̀, ibi tí wọ́n dáa sí ló tẹnu mọ́. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn nígbà tí wọ́n ń ka lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sétí gbogbo ìjọ! Kò sí àní-àní pé àárín àwọn àti Pọ́ọ̀lù á túbọ̀ gún régé. Ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ni pé: Ṣé èmi náà máa ń fi hàn pé mo mọyì àwọn ará tá a jọ wà nínú ìjọ?

10. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe gbóríyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

10 Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré sọ, ó gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń bá ìjọ Tíátírà sọ̀rọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn náà: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.” (Ìṣí. 2:19) Kì í ṣe bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ṣe ń tẹ̀ síwájú nìkan ni Jésù sọ, ó tún gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n ní àwọn ànímọ́ rere tó mú kí wọ́n máa ṣe dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà nínú ìjọ yẹn tó nílò ìbáwí, síbẹ̀ ṣe ló kọ́kọ́ fún wọn níṣìírí, ọ̀rọ̀ ìṣírí náà ló sì fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ìṣí. 2:25-28) Ṣé ẹ ò gbàgbé pé Jésù tó jẹ́ orí ìjọ là ń sọ̀rọ̀ ẹ̀? Ṣé a lè sọ pé ó jẹ wá ní gbèsè ọpẹ́ torí ohun tá a ṣe fún un? Síbẹ̀, Jésù máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún àwọn alàgbà!

ÀWỌN TÍ KÒ MOORE

11. Hébérù 12:16 ṣe sọ, ojú wo ni Ísọ̀ fi wo nǹkan tẹ̀mí?

11 Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan wà nínú Bíbélì tí wọ́n ya aláìmoore. Àpẹẹrẹ kan ni Ísọ̀, ilé ire ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, olùjọsìn Jèhófà sì làwọn òbí rẹ̀, àmọ́ kò mọyì nǹkan tẹ̀mí rárá. (Ka Hébérù 12:16.) Kí ló ṣe tó fi hàn pé kò moore àti pé kò mọyì nǹkan tẹ̀mí? Ó ta ogún ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù arákùnrin rẹ̀ nítorí abọ́ ọbẹ̀ kan ṣoṣo. (Jẹ́n. 25:30-34) Nígbà tó yá, ó ti ìka àbámọ̀ bọnú. Àmọ́ ìyẹn ti bọ́ sórí, ẹ̀pa ò sì bóró mọ́. Torí náà, kò yẹ kó bínú pé wọn ò fún òun ní ìbùkún tó tọ́ sí àkọ́bí.

12-13. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé àwọn ò moore, kí nìyẹn sì yọrí sí?

12 Wọ́n máa ń sọ pé téèyàn bá mọnú rò, á mọpẹ́ dá. Ọ̀pọ̀ ìdí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní tó fi yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Jèhófà ló dá wọn nídè lóko ẹrú Íjíbítì lẹ́yìn tó mú Ìyọnu Mẹ́wàá bá àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. Ó mú kí wọ́n la Òkun Pupa já, ó sì mú kí gbogbo ọmọ ogun Íjíbítì kú sínú omi yẹn. Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn débi pé ṣe ni wọ́n ń jó tí wọ́n ń yọ̀, tí wọ́n sì forin yin Jèhófà. Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ náà rí lára wọn jálẹ̀ ìrìn àjò wọn nínú aginjù?

13 Tí wọ́n bá ti ní ìṣòro, kíá ni wọ́n á gbàgbé gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wọn, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi hàn pé àwọn ò moore. (Sm. 106:7) Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, “Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà ni wọ́n ń kùn sí. (Ẹ́kís. 16:2, 8) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an. Ó wá sọ fún wọn pé gbogbo ìran yẹn ló máa kú sínú aginjù, àyàfi Jóṣúà àti Kálébù. (Núm. 14:22-24; 26:65) Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún wa, àmọ́ kí la lè ṣe tá ò fi ní fìwà jọ wọ́n? Báwo la ṣe lè fara wé àwọn tó moore?

BÍ A ṢE LÈ MÁA FI ÌMỌRÍRÌ HÀN LÓNÌÍ

14-15. (a) Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì ara wọn? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa dúpẹ́ oore?

14 Nínú ìdílé. Gbogbo ìdílé ló máa ṣe láǹfààní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ń fi ìmoore hàn. Báwọn tọkọtaya bá mọyì ara wọn, àárín wọn á túbọ̀ gún régé. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní ṣòro láti gbójú fo àṣìṣe ara wọn. Tí ọkọ kan bá mọyì ìyàwó rẹ̀, kì í ṣe pé ó máa kíyè sí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe nìkan ni, kódà á ‘dìde, á sì yìn ín.’ (Òwe 31:10, 28) Aya tó gbọ́n máa jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ mọ̀ pé òun mọyì rẹ̀, kódà á sọ àwọn ohun pàtó tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe tó ń wú u lórí.

15 Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ yín láti máa dúpẹ́ oore? Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀yin làwọn ọmọ yín ń wò, ohun tẹ́ ẹ bá ń ṣe làwọn náà á máa ṣe. Torí náà, ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn tí wọ́n bá bá yín ṣe nǹkan, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lára yín. Bákan náà, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa dúpẹ́ oore táwọn èèyàn bá ṣe fún wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá mọyì ohun táwọn míì ṣe fún wọn lóòótọ́, kò yẹ kí wọ́n pa á mọ́ra, ṣe ló yẹ kí wọ́n dúpẹ́. Tí wọ́n bá fi ìmoore hàn, inú àwọn èèyàn á dùn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Clary sọ pé: “Nígbà tí màámi wà lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32), ṣàdédé ni wọ́n mú bàbá mi, tí wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n, ló bá di pé kí màmá mi nìkan máa dá tọ́ àwa ọmọ mẹ́ta. Nígbà témi náà pé ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32), mo ronú bó ti máa ṣòro tó fún màámi nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Mo sọ fún wọn pé mo mọyì gbogbo ohun tí wọ́n yááfì kí wọ́n lè bójú tó èmi, ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi ọkùnrin. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, màámi sọ fún mi pé ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí mo sọ múnú àwọn dùn gan-an, àwọn sì mọyì rẹ̀. Wọ́n ní kò sígbà táwọn rántí tí kì í mú kí orí àwọn wú.”

Kọ́ ọmọ rẹ láti máa fi ìmọrírì hàn (Wo ìpínrọ̀ 15) *

16. Sọ àpẹẹrẹ bí ọ̀rọ̀ ìmọrírì ṣe lè fún àwọn míì níṣìírí.

16 Nínú ìjọ. Tá a bá ń fi hàn pé a mọyì àwọn míì, ó máa fún wọn níṣìírí. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Jorge, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28). Alàgbà ni, àmọ́ ìgbà kan wà tó ṣàìsàn tí kò sì lè lọ sípàdé fún odindi oṣù kan. Lẹ́yìn tí ara ẹ̀ le díẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, kò rọrùn fún un láti máa ṣiṣẹ́. Arákùnrin Jorge sọ pé: “Torí pé mi ò lè ṣe nǹkan kan nípàdé, ṣe ló ń ṣe mí bíi pé mi ò wúlò. Lẹ́yìn tí ìpàdé parí lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan sọ fún mi pé: ‘Arákùnrin Jorge, èmi àti ìdílé mi fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé àpẹẹrẹ rere lẹ jẹ́ fún wa. A máa ń rántí àwọn àsọyé tẹ́ ẹ sọ láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ó sì máa ń fún wa lókun gan-an.’ Mi ò mọ ohun tí mo lè fi dá arákùnrin náà lóhùn, ńṣe lomi lé ròrò lójú mi. Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn bọ́ sí àkókò fún mi gan-an.”

17. Kólósè 3:15 ṣe sọ, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa?

17 Mọyì Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ni Jèhófà ń pèsè fún wa. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí àwọn ìtọ́ni gbà láwọn ìpàdé wa, nínú àwọn ìwé wa àti lórí ìkànnì wa. Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tó o ka àpilẹ̀kọ kan tàbí tó o gbọ́ àsọyé kan, tàbí kẹ̀ tó o wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW, tó o wá sọ pé, ‘Èmi gan-an lọ̀rọ̀ yìí kàn’? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe fún wa? (Ka Kólósè 3:15.) Ọ̀nà kan ni pé tá a bá ń gbàdúrà, ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà gbogbo fún àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa.​—Ják. 1:17.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa ni pé ká máa tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a mọyì Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?

18 A lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń mú káwọn ibi ìpàdé wa wà ní mímọ́ tónítóní. Torí náà, ó yẹ ká máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ará yòókù tí wọ́n bá ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ká sì máa tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Ó ṣe pàtàkì káwọn tó wà nídìí ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àtèyí tá a fi ń wo fídíò máa ṣe é jẹ́jẹ́, kó má bàa bà jẹ́. Tá a bá ń bójú tó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa déédéé, wọ́n á tọ́jọ́, àtúnṣe tá a máa ṣe kò sì ní tó nǹkan. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè ní owó tó pọ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ibòmíì láyé tàbí ká fi tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba míì ṣe.

19. Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí alábòójútó àyíká kan àti ìyàwó rẹ̀?

19 Mọyì àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ètò Ọlọ́run. Tá a bá sọ̀rọ̀ ìmọrírì fáwọn èèyàn, ó lè mú kí wọ́n fojú tó yàtọ̀ wo ìṣòro yòówù tí wọ́n ní. Bí ọ̀rọ̀ alábòójútó àyíká kan àti ìyàwó rẹ̀ ṣe rí nìyẹn. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń bọ̀ láti òde ẹ̀rí, òtútù mú gan-an ó sì ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Òtútù mú ìyàwó náà débi pé ṣe ló wọ aṣọ òtútù ẹ̀ sùn. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé iṣẹ́ náà ti sú òun. Àmọ́ kó tó dọwọ́ ọ̀sán, wọ́n gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, ìyàwó yẹn gan-an ni wọ́n kọ ọ́ sí. Nínú lẹ́tà náà, wọ́n gbóríyìn fún un pé àwọn mọyì iṣẹ́ ribiribi tó ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ẹ̀mí ìfaradà tó ní. Wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn mọ bó ti nira tó kéèyàn máa kó kiri lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìmọrírì tó wà nínú lẹ́tà yẹn tù ú nínú gan-an débi pé kò tún sọ pé òun máa fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀ mọ́. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń gbà mí níyànjú tó bá ti fẹ́ sú mi.” Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) ọdún ni tọkọtaya yìí fi ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká!

20. Kí ló yẹ ká máa ṣe lójoojúmọ́, kí sì nìdí?

20 Ẹ jẹ́ ká máa fi hàn lójoojúmọ́ pé a moore, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ àti níṣe. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú tá a sọ tàbí ohun tá a ṣe ló máa tu ẹnì kan lára, pàápàá nínú ayé táwọn èèyàn ò ti moore tó sì kún fún wàhálà yìí. Tá a bá ń fi hàn pé a moore, àárín àwa tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ á túbọ̀ gún régé nísinsìnyí àti títí láé. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà Baba wa ọ̀run tó jẹ́ ọ̀làwọ́ tó sì tún moore.

ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

^ ìpínrọ̀ 5 Tó bá di pé kéèyàn fi ìmoore hàn, kí la rí kọ́ lára Jèhófà, Jésù àti adẹ́tẹ̀ kan tó jẹ́ ará Samáríà? A máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ yìí àtàwọn míì. A tún máa sọ ìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ oore, àá sì sọ àwọn ọ̀nà pàtó tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tá a bá dúpẹ́ oore, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì ẹni tó ṣe wá lóore àtohun tó ṣe fún wa. Ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ lọ̀rọ̀ téèyàn sọ látọkàn wá.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Wọ́n ń ka lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí etíìgbọ́ àwọn ará ìjọ Róòmù; inú Ákúílà, Pírísílà, Fébè àtàwọn míì dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ orúkọ wọn.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Ìyá kan ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún arábìnrin àgbàlagbà kan torí pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere.