Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Sínágọ́gù Tó Wà Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí bí sínágọ́gù ṣe máa ń rí. Èyí ni sínágọ́gù tó wà ní Gamla, ó sì jìn tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá (ìyẹn máìlì mẹ́fà) sí àríwá Òkun Gálílì

Ìgbà Wo Làwọn Júù Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo Sínágọ́gù?

Ọ̀RỌ̀ náà “sínágọ́gù” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “àpéjọ” tàbí “ìpéjọpọ̀.” Orúkọ yẹn bá a mu torí pé ọjọ́ pẹ́ táwọn Júù ti máa ń kóra jọ sínú sínágọ́gù láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì jọ́sìn. Kò fi bẹ́ẹ̀ síbì kan pàtó nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó mẹ́nu kan sínágọ́gù, àmọ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì mẹ́nu kàn àn. Ìyẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé ṣáájú ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti ń lo sínágọ́gù.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé ìgbà táwọn Júù wà nígbèkùn Bábílónì ni wọ́n dá sínágọ́gù sílẹ̀. Ìwé Encyclopædia Judaica sọ pé: “Àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn Bábílónì ò ní Tẹ́ńpìlì, ilẹ̀ àjèjì ni wọ́n wà, wọ́n sì nílò ìtùnú lójú méjèèjì. Torí náà, wọ́n máa ń kóra jọ bóyá láwọn ọjọ́ Sábáàtì kí wọ́n lè jọ ka Ìwé Mímọ́.” Nígbà tí wọ́n kúrò nígbèkùn, ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ṣì ń kóra jọ láti gbàdúrà kí wọ́n sì ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń dá sínágọ́gù sílẹ̀ níbikíbi tí wọ́n bá tẹ̀ dó sí.

Nígbà tó máa fi di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, sínágọ́gù ti di ibi táwọn Júù máa ń lò déédéé fún ìjọsìn, wọ́n sì máa ń kóra jọ láti bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ míì. Bó ṣe wà ní Mediterranea ló wà ní Middle East àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Professor Lee Levine ti Hebrew University of Jerusalem sọ pé: “Wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, wọ́n máa ń ṣe àwọn àjọyọ̀, wọ́n máa ń gbọ́ ẹjọ́ níbẹ̀, wọ́n ń kówó ìlú pa mọ́ síbẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe onírúurú ìpàdé. Àmọ́, ìjọsìn lohun tó ṣe pàtàkì jù tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.” A wá rídìí tí Jésù náà fi máa ń lọ sí sínágọ́gù nígbà táwọn èèyàn bá kóra jọ. (Máàkù 1:21; 6:2; Lúùkù 4:16) Ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn níbẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì ń fún wọn níṣìírí. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà wàásù lọ́pọ̀ ìgbà nínú sínágọ́gù. Torí pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń lọ sí sínágọ́gù déédéé, ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti máa ń kọ́kọ́ lọ wàásù tó bá wọ ìlú kan.​—Ìṣe 17:1, 2; 18:4.