Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àwọn Ará ní Poland”—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ṣenúnibíni sí Wọn?

“Àwọn Ará ní Poland”—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ṣenúnibíni sí Wọn?

“Àwọn Ará ní Poland”—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ṣenúnibíni sí Wọn?

Lọ́dún 1638, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Poland kó wàhálà ńlá bá àwùjọ ẹ̀sìn kékeré kan táa mọ̀ sí Àwọn Ará ní Poland. Wọ́n ba ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ náà jẹ́. Wọ́n ti Yunifásítì Raków pa, wọ́n sì rán àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n ń kọ́ni níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.

Ogún ọdún lẹ́yìn náà, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà tún gbé ìgbésẹ̀ mìíràn. Ó pàṣẹ fún gbogbo mẹ́ńbà ẹ̀sìn náà láti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ o. Báwo lọ̀ràn ṣe wá burú tó báyìí ní orílẹ̀-èdè kan tó jẹ́ pé òun la kà sí èyí tó fàyè gbẹ̀sìn jù lọ ní Yúróòpù lákòókò yẹn? Kí ni Àwọn Ará ní Poland ṣe, tí irú ìyà bẹ́ẹ̀ fi tọ́ sí wọn?

GBOGBO wàhálà yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àárín Ìjọ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin ní Poland ò gún mọ́. Kókó ohun tó sì fa awuyewuye ọ̀hún ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú kan nínú ìjọ náà sọ pé àwọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n ní kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Èyí ló mú káwọn aṣáájú ìjọ gbaná jẹ, lẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú bá fọ́.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin máa ń pe àwọn tó yapa yìí ní àwọn Ọmọlẹ́yìn Arius, a ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọ tuntun yìí máa ń pe ara wọn ni Kristẹni tàbí àwọn Ará ní Poland. A tún mọ̀ wọ́n sí Socinian, ìyẹn ni ọmọlẹ́yìn Laelius Socinus, ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tí Servetus ti yí lérò padà, ẹni tí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń jẹ́ Faustus Socinus rìnrìn àjò lọ sí Poland, tó sì di olókìkí nínú ẹgbẹ́ náà.

Nígbà yẹn, ọ̀tọ̀kùlú ọmọ ilẹ̀ Poland kan, Jan Sienieński, fẹ́ fún ìjọ tuntun náà ni ohun tó pè ní “ibi píparọ́rọ́, tó wà ní kọ́lọ́fín,” ibi tí ìjọ náà ti lè gbèrú. Nípa lílo àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí ọba Poland fún un, Sienieński tẹ ìlú Raków dó, ibi tó wá di ibùdó ẹ̀sìn Socinus ní Poland. Sienieński fún àwọn ọmọ ìlú Raków ni àwọn ẹ̀tọ́ díẹ̀, títí kan ẹ̀tọ́ jíjọ́sìn lómìnira.

Àwọn oníṣẹ́ ọnà, oníṣègùn, apoògùn, àwọn aráàlú, àwọn ọ̀tọ̀kùlú láti inú onírúurú ìsìn bẹ̀rẹ̀ síí rọ́ wá sí ìlú tuntun náà. Láfikún sí i, àwọn òjíṣẹ́ ń rọ́ wá láti ilẹ̀ Poland, Lithuania, Transylvania, Faransé, àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pàápàá. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé wọ̀nyí ló tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ Socinus o; látàrí èyí fún odindi ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, ìyẹn láti ọdún 1569 sí 1572, Raków di ibi tí àwọn èèyàn ti wá ń ṣawuyewuye nípa ẹ̀sìn. Kí ló wá yọrí sí?

Ilé Tó Yapa

Ẹgbẹ́ Socinus fúnra rẹ̀ ti fọ́, àwọn onígbàgbọ́ àṣerégèé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn tó sì jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì. Àmọ́ ṣá o, láìka èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ẹgbẹ́ wọn sí, ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ wọn lápapọ̀ yàtọ̀ gédégbé. Wọn kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan; wọn kì í ṣe ìrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́; wọn kì í gbé ohun ìjà ogun, lọ́pọ̀ ìgbà wọn kì í sì í di ipò òṣèlú mú. b Wọ́n tún sọ gbangba pé kò síbi tó ń jẹ́ ọ̀run àpáàdì táa ti ń dáni lóró. Pẹ̀lú gbogbo èyí, wọn kì í tún lọ́wọ́ sí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ olókìkí tó jẹ mọ́ ti ìsìn.

Làwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin àtàwọn àlùfáà Kátólíìkì bá gbé àtakò gbígbóná janjan dìde sí ìjọ yìí, ṣùgbọ́n àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn Socinus lo àǹfààní òmìnira ẹ̀sìn tí àwọn ọba bíi Sigismund Kejì ti ilẹ̀ Poland àti Stephen Báthory gbé lárugẹ, láti kọ́ni ní ojú ìwòye wọn.

Iṣẹ́ Mánigbàgbé Tí Budny Ṣe

Bíbélì tí ọmọlẹ́yìn Calvin kan túmọ̀ nígbà yẹn, tó sì jẹ́ pé òun ló wọ́pọ̀ jù lọ, kò yanjú ìṣòro ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé. Wọn ò lo àwọn ìtumọ̀ èdè ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ láti túmọ̀ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n lo ìtumọ̀ Vulgate lédè Látìn àti ìtumọ̀ èdè Faransé tó wà ní àkókò yẹn. Aláṣẹ kan sọ pé: “Níbi tí wọ́n ti ń wá ọ̀rọ̀ dídùn kiri, ìtumọ̀ tó ṣeé gbíyè lé tó sì péye sọnù mọ́ wọn lọ́wọ́.” Ọ̀pọ̀ àṣìṣe ló kún inú rẹ̀. Nítorí èyí ni wọ́n ṣe pe ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Szymon Budny, láti wá ṣàtúnṣe ìtumọ̀ náà. Ó pinnu pé ohun tó máa rọrùn jù ni pé kí òun kúkú túmọ̀ rẹ̀ lákọ̀tun dípò tí òun yóò fi tún ti tẹ́lẹ̀ ṣe. Nǹkan bí ọdún 1567 ni Budny dáwọ́ lé iṣẹ́ náà.

Nígbà tí Budny ń túmọ̀ ìwé náà, gbogbo tìfuntẹ̀dọ̀ ọ̀rọ̀ tó lò, ló yẹ̀ wò fínnífínní, kò tí ì sẹ́nikẹ́ni tó ṣe bẹ́ẹ̀ rí nílẹ̀ Poland. Níbi tí ọ̀rọ̀ Hébérù bá ṣòroó túmọ̀, yóò kọ ìtumọ̀ rẹ̀ ní ṣáńgílítí síbi àlàyé etí ìwé. Nígbà tó bá pọndandan, ó máa ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun, tí yóò sì gbìyànjú láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye, ìyẹn èyí tí wọ́n ń lò nílẹ̀ Poland nígbà ayé rẹ̀. Góńgó rẹ̀ ni pé kí ó gbé ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣe é gbíyè lé, tó sì péye kalẹ̀.

Ọdún 1572 la gbé ìtumọ̀ odindi Bíbélì tí Budny ṣe jáde. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ṣe ìwé náà jáde kó àbààwọ́n bá ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tó wà nínú Bíbélì náà. Láìmikàn, Budny tún dáwọ́ lé ṣíṣe àtúnṣe ẹ̀dà náà, ó sì parí rẹ̀ lọ́dún méjì lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀. Ìtumọ̀ tó yanjú tí Budny gbé jáde lórí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì dáa ju àwọn ìtumọ̀ tó ti wà tẹ́lẹ̀ lédè Polish lọ. Ní àfikún sí i, ní ọ̀pọ̀ ibi ló ti dá orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, padà sí àyè rẹ̀.

Láti apá ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sí ọgbọ̀n ọdún àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, Raków, olú ìlú tí ìjọ yìí wà wá di ibi tí wọ́n ti ń jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ibi tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń gbárí jọ sí. Ibẹ̀ ni àwọn aṣáájú ìjọ àwọn Ará ní Poland àti àwọn òǹkọ̀wé wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé àṣàrò kúkúrú àti àwọn ìwé mìíràn jáde.

Wọ́n Gbé Ètò Ẹ̀kọ́ Lárugẹ

Nǹkan bí ọdún 1600 ni iṣẹ́ ìtẹ̀wé àwọn Ará ní Poland bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú, nígbà tí wọ́n dá ilé ìtẹ̀wé kan sílẹ̀ ní Raków. Ilé ìtẹ̀wé náà lè tẹ àwọn ìwé pélébé àti ìwé ńlá jáde lónírúurú èdè. Gẹ́gẹ́ bí ibi ìgbáríjọ fún ilé ìtẹ̀wé, kò pẹ́ tí Raków fi di ìlú tó ní ilé ìtẹ̀wé tó dára jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù. A gbọ́ pé nǹkan bí igba ìtẹ̀jáde la tẹ̀ níbẹ̀ láàárín ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e. Ilé iṣẹ́ kan tó ń ṣe bébà nítòsí tó jẹ́ ti àwọn Ará ní Poland, ló ń pèsè ojúlówó bébà tí wọ́n fi ń tẹ̀wé.

Kò pẹ́ tí àwọn Ará ní Poland fi rí i pé ó ṣe pàtàkì láti kọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́. Kí èyí lè ṣeé ṣe, wọ́n dá Yunifásítì Raków sílẹ̀ lọ́dún 1602. Ilé ẹ̀kọ́ yìí làwọn ọmọ àwọn Ará ní Poland, àti àwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì máa ń lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ ìsìn ni yunifásítì yìí, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nìkan kọ́ ni wọ́n ń kọ́ níbẹ̀. Wọ́n tún ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ bíi, èdè ilẹ̀ òkèèrè, ìlànà ìwà híhù, ìtàn, òfin, ọgbọ́n orí, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìṣirò, ìṣègùn, àti eré ìdárayá. Yunifásítì náà ní ilé ìkàwé tó tóbi, tó sì ń tóbi sí i, nítorí ilé ìtẹ̀wé tó wà ládùúgbò náà.

Bí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ti ń kógbá sílé, ó dà bíi pé àwọn Ará ní Poland yóò máa gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Àmọ́, ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀ lọ rárá.

Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba Fìjà Pẹẹ́ta

Zbigniew Ogonowski ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Nílẹ̀ Poland ṣàlàyé pé: “Ní òpin ọgbọ̀n ọdún àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, nǹkan ò rọrùn fún àwọn ọmọlẹ́yìn Arius nílẹ̀ Poland mọ́.” Èyí jẹ́ nítorí ìgbòkègbodò tí àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì fi ìmójúkuku ṣe láìdáwọ́dúró. Gbogbo ọ̀nà làwọn àlùfáà náà lò láti ba orúkọ àwọn Ará ní Poland jẹ́, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ wọn láìdáa, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọ̀wé burúkú nípa wọn. Ohun tó tún wá mú kó rọrùn láti ṣàtakò náà ni ètò ìṣèlú tó yí padà nílẹ̀ Poland. Ọ̀tá àwọn Ará ní Poland ni Sigismund kẹta Vasa jẹ́, ìyẹn ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ ní Poland. Àwọn ọba tó tún jẹ lẹ́yìn rẹ̀, pàápàá jù lọ, John Kejì Casimir Vasa, ti Ìjọ Kátólíìkì lẹ́yìn láti dojú ìjọ àwọn Ará ní Poland bolẹ̀.

Ọ̀ràn ọ̀hún dójú ẹ̀ nígbà tókìkí kàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan láti Raków tẹ́ńbẹ́lú àgbélébùú. Ọ̀ràn yìí ni wọ́n wá gùn lé láti rí i pé àwọn rẹ́yìn àwọn Ará ní Poland. Wọ́n wọ́ ẹni tó ni yunifásítì Raków wá síwájú kóòtù ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ‘ó ń tan ìwà ibi kálẹ̀’ nípa ṣíṣàtìlẹ́yìn fún Yunifásítì Raków àti ilé ìtẹ̀wé rẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn Ará ní Poland pé wọ́n ń gbìmọ̀ láti dojú ìjọba délẹ̀, wọ́n ní aláṣejù ni wọ́n, wọ́n ní wọ́n ń ṣèṣekúṣe. Ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin bá pinnu pé kí wọ́n ti Yunifásítì Raków pa pátápátá, kí wọ́n sì run ilé ìtẹ̀wé àti ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ ti àwọn Ará ní Poland. Wọ́n pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà jáde nílùú. Wọ́n láwọn ò gbọ́dọ̀ rẹ́sẹ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì mọ́ ní orílẹ̀-èdè náà, tí wọ́n bá sì dán an wó pẹ́nrẹ́n, ìyà ikú ni wọ́n o fi jẹ́ wọn. Ni àwọn kan lára àwọn Ará ní Poland bá lọ wá ibì kan forí ara wọn pa mọ́ sí, wọ́n sá lọ sí àwọn ibi bíi Silesia àti Slovakia.

Lọ́dún 1658 ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà ṣòfin pé láàárín ọdún mẹ́ta kí àwọn Ará ní Poland ta dúkìá wọn, kí wọ́n wábi gbà. Nígbà tó yá, wọ́n tún dín in kù sí ọdún méjì. Lẹ́yìn ọdún méjì yìí, ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun di ìgbàgbọ́ wọn mú, pípa ni wọ́n ó pa á.

Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Socinus kó lọ sí Netherlands, níbi tí wọ́n ti ń bá iṣẹ́ ìtẹ̀wé wọn lọ. Ní Transylvania, ìjọ kan wà níbẹ̀ títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún. Nínú ìpàdé wọn, èyí tí wọ́n máa ń ṣe nígbà mẹ́ta lọ́sẹ̀, wọ́n máa ń kọ sáàmù lórin, wọ́n máa ń gbọ́ ìwàásù, wọ́n á sì ka katikísìmù tí wọ́n ti ṣètò láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ wọn. Láti rí i pé ìjọ wà ní mímọ́, wọ́n máa ń tún ojú ìwòye àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe, wọ́n máa ń gbà wọ́n níyànjú, tó bá tún pọndandan, wọ́n máa ń yọ wọ́n lẹ́gbẹ́.

Akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn Ará ní Poland jẹ́. Ọ̀pọ̀ òtítọ́ ṣíṣeyebíye ni wọ́n ṣàwárí, wọn ò sì lọ́ra láti sọ wọ́n fáwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù, èyí ló wá jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún wọn láti wà níṣọ̀kan. Nígbà tó yá, àwọn Ará ní Poland pòórá pátápátá.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Arius (250-336 Sànmánì Tiwa) jẹ́ àlùfáà ní Alẹkisáńdíríà, òun ló jiyàn pé Jésù àti Baba rẹ̀ kì í ṣẹgbẹ́ rárá. Ìgbìmọ̀ Niséà kò gba ojú ìwòye rẹ̀ wọlé lọ́dún 325 Sànmánì Tiwa—Wo Jí! June 22, 1989, ojú ìwé 18.

b Wo Jí!, May 22, 1989, ojú ìwé 19, “Àwọn Onísìn Socinus—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ṣá Mẹ́talọ́kan Tì?”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ilé kan tó jẹ́ ti òjíṣẹ́ ẹ̀sìn Socinus tẹ́lẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lókè: Raków lónìí; ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tí wọ́n dá sílẹ̀ ní 1650 ló wà lọ́wọ́ ọ̀tún, àwọn ló ń rí sí fífa “ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Arius” tu ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò; nísàlẹ̀: Ibi yìí ní àwọn àlùfáà Kátólíìkì wá rí àgbélébùú mọ́ láti lè bá àwọn Ará ní Poland fa wàhálà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]

Ẹ̀yìn ìwé náà, Biblia nieświeska láti ọwọ́ Szymon Budny, 1572