Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso

Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso

Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso

ÌFILỌ̀ tó yani lẹ́nu la fi mú Ìpàdé Ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania wá sópin ní ọjọ́ Saturday, October 2, 1999. Inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn ó lé ẹgbẹ̀tadínmẹ́fà [10,594] tó wà níkalẹ̀ tàbí tí wọ́n gbádùn ètò náà lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù dùn dọ́ba nígbà tí wọ́n gbọ́ pé a ti yan àwọn ẹni mẹ́rin kún Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn mẹ́ńbà tuntun yìí tí gbogbo wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ni, Samuel F. Herd; M. Stephen Lett; Guy H. Pierce; àti David H. Splane.

• Samuel Herd bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ́dún 1958, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè láti ọdún 1965 títí di 1997. Láti ìgbà yẹn wá ni òun àti aya rẹ̀, Gloria, ti di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, níbi tí Arákùnrin Herd ti ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Ó tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn.

• Stephen Lett bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní December 1966, ó sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1967 sí 1971. Nígbà tó di October 1971, ó gbé, Susan, aya rẹ̀, níyàwó, ló bá lọ́ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Láti 1979 sí 1998, ó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Láti April 1998, ni òun àti Susan ti di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn tó wà níbẹ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́, ó sì tún jẹ́ olúrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.

• Onídìílé ni Guy Pierce, òun àti aya rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní April 1982. Ó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní ọdún 1986 títí di 1997, nígbà tí òun àti aya rẹ̀, Penny, di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Orílẹ-èdè Amẹ́ríkà. Arákùnrin Pierce ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òṣìṣẹ́.

• David Splane bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní September 1963. Akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì kejìlélógójì ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead ni, ó sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní Senegal, Áfíríkà, lẹ́yìn ìyẹn ló wá fi ọdún mọ́kàndínlógún sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní Kánádà. Òun àti aya rẹ̀, Linda, ti wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti ọdún 1990, níbi tí Arákùnrin Splane ti ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn àti ti Ìkọ̀wé. Láti 1998 ló ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé.

Yàtọ̀ sí àwọn mẹ́rin táa ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn wọ̀nyí, àwọn tó tún wà nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso báyìí ni, C. W. Barber, J. E. Barr, M. G. Henschel, G. Lösch, T. Jaracz, K. F. Klein, A. D. Schroeder, L. A. Swingle, àti D. Sydlik. Àdúrà gbogbo wa ni pé, kí Jèhófà túbọ̀ máa bù kún Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tí a ti fi kún yìí, kó sì máa fún un lókun, bí ẹgbẹ́ náà ṣe ń bá a lọ láti bójú tó ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn Ọlọ́run káàkiri ayé, tó sì ń sìn fún ire wọn nípa tẹ̀mí.