Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fúnni Ní Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la

Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fúnni Ní Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la

Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fúnni Ní Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la

ỌPẸ́LỌPẸ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì Mímọ́, òun ló jẹ́ kí àwọn Kristẹni lè máa fi ọkàn ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ẹ̀mí nǹkan yóò dára wo ọjọ́ iwájú. Nítorí tí ìbátan tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, wọ́n gbà pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí a fi ṣí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti ṣàlàyé rẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Nítorí náà, kí ni Jèhófà ní ní ìpamọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí? Pẹ̀lú Bíbélì wọn tó ti wà ní sẹpẹ́, gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ ló fẹ́ mọ nǹkan náà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọpọ̀ náà la fi ṣe ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó dá dúró.

ỌJỌ́ KÌÍNÍ: Rírìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀rọ̀ náà, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣamọ̀nà Wa,” ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn Jèhófà dà bí ọkùnrin kan tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ nínú òkùnkùn lóru. Bí oòrùn ti ń yọ, ló bẹ̀rẹ̀ sí í rí òjìji, àmọ́ ó wá ríran kedere nígbà tó di ọjọ́kanrí, tí oòrùn ti ràn. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 4:18 ti sọ, oòrùn òtítọ́ tó mọ́lẹ̀ rokoṣo, èyí tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ wá láti inú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn Jèhófà wá rí ọ̀nà wọn kedere. A kò fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n nínú òkùnkùn tẹ̀mí.

Lájorí àsọyé náà, “Máa Fiyè sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run,” rán àwọn olùgbọ́ létí pé, àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bọ́ lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ àti ìtànjẹ tí àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn mèsáyà àti wòlíì èké ń dojú kọ. Ẹ wá wo ìyàtọ̀ ńláǹlà tó wà ní ti pé, ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù Kristi ni ojúlówó Mèsáyà pọ̀ rẹpẹtẹ! Fún àpẹẹrẹ, ìyípadà ológo tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù lọ́nà ìyanu jẹ́ ọ̀nà kan láti rí i ṣáájú pé òun ni ọba Ìjọba Ọlọ́run tí yóò gorí ìtẹ́. Àtìgbà tí Jésù ti dé nínú agbára Ìjọba ní 1914 ló ti di “ìràwọ̀ ojúmọ́” tí a mẹ́nu kàn nínú 2 Pétérù 1:19. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tó jẹ́ Ìràwọ̀ Ojúmọ́, ó kéde ojú ọjọ́, tàbí sànmánì tuntun, tó ti mọ́ fún gbogbo aráyé onígbọràn.”

Ọ̀rọ̀ náà, “Títàn bí Atànmọ́lẹ̀,” tí a fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tọ̀sán, ṣàlàyé ìwé Éfésù 5:8 lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, níbi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti gbà wá nímọ̀ràn láti “máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Atànmọ́lẹ̀ làwọn Kristẹni jẹ́, kì í ṣe nítorí pé wọ́n ń sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn ènìyàn nìkan ni, àmọ́ nípa bí wọ́n ṣe tún ń fi Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn ní àfarawé Jésù.

Láti jẹ́ irú atànmọ́lẹ̀ bí èyí, a gbọ́dọ̀ “Ní Ìdùnnú Nínú Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Inú àpínsọ àsọyé mẹ́ta la ti ṣàlàyé àkòrí yìí. Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Abraham Lincoln, tó pe Bíbélì ní “ẹ̀bùn tó dára jù lọ tí Ọlọ́run fún ènìyàn,” ó wá béèrè lọ́wọ́ àwọn tó wà láwùjọ bóyá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ka Bíbélì ń fi bí ìmọrírì wọn fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn. A wá rọ àwọn olùgbọ́ láti máa ka Bíbélì wọn dáradára, kí wọ́n sì máa wá àyè láti fojú inú wo àwọn àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì rí ìbátan tó wà nínú ohun tuntun tí wọ́n ń gbọ́ àti èyí tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀.

Apá kejì àpínsọ àsọyé náà tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìkẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe kíka ìwé lásán, bí a bá fẹ́ máa gba “oúnjẹ líle” sínú. (Hébérù 5:13, 14) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń gbéni ró gan-an, bí a bá ‘múra ọkàn wa’ ṣáájú, bíi ti àlùfáà Ísírẹ́lì nì, Ẹ́sírà. (Ẹ́sírà 7:10) Àmọ́, èé ṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó kan ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà ní tààràtà. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a fọwọ́ dan-in dan-in mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó jẹ́ ohun tó máa ń dùn mọ́ wa, tó sì máa ń tù wá lára, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gba ìsapá táa lo ọpọlọ fún. Báwo la ṣe ń wá àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀? Ẹni tó sọ apá tó kẹ́yìn nínú àpínsọ àsọyé náà sọ pé nípa “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà” ìyẹn ni pé kí a gbà á lọ́wọ́ àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. (Éfésù 5:16) Dájúdájú, ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tí a fi lè rí àkókò ni pé kí a lo àkókò tí a bá ní dáradára.

Ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọ́run Ń Fagbára Fẹ́ni Tó Ti Rẹ̀,” fi hàn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti rẹ̀ lóde òní. Ká lè ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, a ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí “ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 4:7; Aísáyà 40:29) Àwọn ohun tí ń fúnni lókun ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àdúrà, ìjọ Kristẹni, lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn déédéé, àwọn Kristẹni alábòójútó, àti àpẹẹrẹ àwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́. Àkòrí ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ Lójú Ìwòye Ibi Tí Àkókò Dé,” tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún àwọn Kristẹni láti jẹ́ olùkọ́, kí wọ́n tún jẹ́ oníwàásù, kí wọ́n sì tún máa ṣe iṣẹ́ àṣekára nípa mímú “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” sunwọ̀n sí i.—2Tímótì 4:2.

Ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn ní ọjọ́ náà, “Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí,” mẹ́nu kan itú táwọn kan ti pa láwọn ilẹ̀ kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti sọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orúkọ tí kì í ṣe tiwa, wọ́n ní ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ burúkú ni wá. Àmọ́, kò yẹ ká bẹ̀rù, nítorí Aísáyà 54:17 sọ pé: “‘Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,’ ni àsọjáde Jèhófà.”

ỌJỌ́ KEJÌ: Àwọn Ohun Tí A Sọ Di Mímọ̀ Nípasẹ̀ Àwọn Ìwé Mímọ́ Alásọtẹ́lẹ̀

Lẹ́yìn ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì ọjọ́ náà, àwọn tó péjọ gbádùn àpínsọ àsọyé kejì táa ṣètò fún àpéjọpọ̀ náà, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Yíyin Jèhófà Lógo bí Àwọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀.” Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ fi hàn pé góńgó Kristẹni kan ni láti yin Jèhófà lógo nípa wíwàásù níbi gbogbo. Apá tí ó tẹ̀ lé e sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti máa darí àwọn tó bá fìfẹ́ hàn sínú ètò Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Nípa lílo nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá láti fi bí ètò àjọ Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ hàn wọ́n, a lè kọ́kọ́ ṣe èyí ṣáájú gbogbo ìgbà táa bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn nínú ilé wọn tàbí lẹ́yìn tí a bá parí rẹ̀. Ọ̀rọ̀ kẹta lórí àpínsọ àsọyé yìí tẹnu mọ́ ìdí tí a fi ní láti fògo fún Ọlọ́run nípa ṣíṣe iṣẹ́ àtàtà.

Ọ̀rọ̀ náà, “Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Lọ́nà Tí Ó Peléke,” dá lórí àwọn ẹsẹ tí a yàn nínú ìwé Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà. Láìsí àní-àní, a nílò ìránnilétí, nítorí pé gbogbo wa la lè gbàgbé nǹkan. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà láti nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìránnilétí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe!

Ẹ̀yìn ìyẹn ni gbankọgbì ọ̀rọ̀ bọ́—ìyẹn ni ọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Kíkọbiara sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Náà Ń Ṣamọ̀nà sí Batisí.” A rán àwọn tó fẹ́ ṣe ìbatisí létí láti fara wé Kristi, kì í ṣe nípa ṣíṣe ìbatisí nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ní láti máa tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pétérù 2:21) Ẹ wo àǹfààní ńlá tí èyí jẹ́ fún àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí láti nípìn-ín nínú ìmúṣẹ Jòhánù 10:16, níbi tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun óò kó “àwọn àgùntàn mìíràn” jọ láti ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí a fẹ̀mí yàn!

Ọ̀rọ̀ náà, “Gbọ́ Ohun Tí Ẹ̀mí Ní Láti Sọ,” ló bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tọ̀sán, ó ṣàlàyé pé ẹ̀mí Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” àti ẹ̀rí ọkàn wa táa fi Bíbélì kọ́. (Mátíù 24:45) Látàrí èyí, àwọn Kristẹni kò ní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ọ̀run kí wọ́n tó mọ bí àwọn ó ṣe wu Ọlọ́run. Ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e, “Dúró Gbọn-in Nínú Ẹ̀kọ́ Tó Wà Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìfọkànsin Ọlọ́run,” rọ àwọn Kristẹni láti má ṣe máa tanná wá àwọn èrò búburú, tó lè bani jẹ́, tó kún inú ayé yìí. Lóòótọ́, wíwá fìn-ín ìdí kókò lè mú kí a rí ìsọfúnni tí ń pani lára gbà látọ̀dọ̀ àwọn apẹ̀yìndà àti àwọn ìránṣẹ́ mìíràn tí Sátánì ń lò. Ó kúkú dára jù ká máa ka Bíbélì àti àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé.

Ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e tí ó ní àkọlé náà, “Máa Di Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-Nílera Mú,” tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì dídi ojúlùmọ̀ “àpẹẹrẹ” tàbí ọ̀nà tí a gbà gbé òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ kalẹ̀. (2 Tímótì 1:13) Kì í ṣe ìfọkànsin Ọlọ́run nìkan ni àpẹẹrẹ yìí lè jẹ́ kí a ní, yóò tún jẹ́ kí a dá àwọn ohun tí kò bá òtítọ́ mu mọ̀.

Rò ó wò ná, pé Jèhófà ka ọ́ sí ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra. Iyì ńlá mà lèyí jẹ́ o! Ọ̀rọ̀ tí a gbé karí àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì náà, “‘Àwọn Ohun Fífani-Lọ́kàn-Mọ́ra Ń Kún Ilé Jèhófà,” ló fúnni níṣìírí jù lọ, nítorí pé ó mú un dá mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan lójú pé ní tòótọ́, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra lójú Jèhófà. (Ìṣípayá 7:9) Nítorí ìdí èyí, Jèhófà yóò pa wọ́n mọ́ nígbà àṣekágbá “ìmìtìtì” rẹ̀ tí yóò mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀. (Hágáì 2:7, 21, 22; Mátíù 24:21) Àmọ́ ṣá o, ní báyìí ná, àwọn ènìyàn Jèhófà ní láti máa ṣọ́nà nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú apá náà, “Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Ń Mú Kí A Wà Lójúfò Láti Máa Ṣọ́nà.” Olùbánisọ̀rọ̀ fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ, nígbà tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mátíù 24:42) Báwo la ṣe ń wà lójúfò nípa tẹ̀mí? Nípa mímú kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí a máa gbàdúrà déédéé, ká sì máa retí dídé ọjọ́ ńlá Jèhófà.

Àkòrí ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn lọ́jọ́ náà ni “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ ní Àkókò Òpin.” Fún ọ̀pọ̀ ọdún la ó máa rántí rẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé olùbánisọ̀rọ̀ náà kéde ìmújáde ìwé tuntun náà Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ìwé aláwọ̀ mèremère tó ní ojú ewé ọ̀ọ́dúnrún lé ní ogún yìí, kárí gbogbo apá tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì.” Ẹ̀rí tí ń fúnni lókun mà lèyí jẹ́ o, pé Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sórí Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀!

ỌJỌ́ KẸTA: Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Kì í Kùnà

Ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àpínsọ àsọyé náà, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Yóò Nímùúṣẹ ní Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀.” Apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Hábákúkù sọ nípa bí Jèhófà yóò ṣe múdàájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Ti àkọ́kọ́ jẹ́ lórí Júdà alágídí, èkejì dá lórí Bábílónì agbonimọ́lẹ̀. Èyí tó kẹ́yìn tí kò tí ì ní ìmúṣẹ ni ti ìparun tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí gbogbo àwọn ènìyàn burúkú. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì, arákùnrin tí ó sọ apá tó kẹ́yìn nínú àpínsọ àsọyé náà gbin ìbẹ̀rù Ọlọ́run sínú àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́nà rere, nígbà tó sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá tú agbára ńlá rẹ̀ jáde pátápátá.”

“Mímọrírì Ogún Tẹ̀mí Táa Ní” ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ inú Bíbélì tí a ṣe ní àpéjọpọ̀ náà. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó múni ronú jinlẹ̀ yìí la gbé karí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀mí tí Jékọ́bù àti Ísọ̀ ní sí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ísọ̀ ò ka ogún tẹ̀mí tó ní sí, a sì tipa bẹ́ẹ̀ fún Jékọ́bù, tó mọyì rẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá béèrè lọ́wọ́ àwùjọ pé: “Kí ni [ogún tẹ̀mí] tí Jèhófà fún wa? Ó dáhùn pé: “Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì; ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun; àti ọlá tó fún wa láti ṣojú fun òun gẹ́gẹ́ bí olùkéde ìhìn rere náà ni”

Àkòrí apá tó tẹ̀ lé e ni “Kí ni Ogún Tẹ̀mí Táa Ní Túmọ̀ Sí fún Ọ?” A fi ẹ̀mí tó dára hàn sí ogún tẹ̀mí táa ní nípa fífi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti àwọn àǹfààní tẹ̀mí táa ní ṣáájú nǹkan tó jẹ́ tiwa tàbí àǹfààní ọrọ̀ àlùmọ́nì. Lọ́nà yìí, a ń mú kí ìgbésí ayé wa bá ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà mu, kí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti Ádámù, Ísọ̀, àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́.

Àwíyé fún gbogbo ènìyàn, “Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun— Bí A Ti Sọ Ọ́ Tẹ́lẹ̀,” kó àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ṣe kókó nípa “ọ̀run tuntun” àti “ayé tuntun” pa pọ̀. (Aísáyà 65:17-25; 66:22-24; 2 Pétérù 3:13a; Ìṣípayá 21:1, 3-5) Ní kedere, Jèhófà ní ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí lọ́kàn lọ́nà tó ga lọ́lá ju ti ìmúṣẹ tó ní lọ́kàn nígbà ìmúpadàbọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Dájúdájú, Ìjọba rẹ̀ ló ní lọ́kàn (ìyẹn ni “ọ̀run tuntun”) àti àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé (ìyẹn ni “ayé tuntun”), tí wọ́n máa gbádùn párádísè ológo tí yóò kárí ayé.

Ọ̀rọ̀ kan tó múni láyọ̀, tó sì tún tani jí táa fi parí àpéjọpọ̀ náà ni “Àwọn Ohun Tí A Ń Fojú Sọ́nà fún Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣamọ̀nà Wa.” Ó rán gbogbo wa létí pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù” láti parí iṣẹ́ ìkéde Ìjọba náà “ti dín kù.” (1 Kọ́ríńtì 7:29) Bẹ́ẹ̀ ni, a ti wà ní bèbè ìgbà tí àwọn àṣẹ Jèhófà yóò ní ìmúṣẹ sórí Sátánì àti gbogbo ètò búburú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù náà ní, nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Àní ọkàn wa ti ń fojú sọ́nà fún Jèhófà. Òun ni olùrànlọ́wọ́ wa àti apata wa.” (Sáàmù 33:20) Ìrètí ológo gbáà mà lèyí fáwọn tó gbé ìfojúsọ́nà wọn ka orí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run o!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ títanijí ru ìmọrírì tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní fún ogún tẹ̀mí sókè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ tó kọbiara sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ṣe ìrìbọmi