Ọdún Tí Bíbélì Táa Pín Kiri Pọ̀ Jù Lọ
Ọdún Tí Bíbélì Táa Pín Kiri Pọ̀ Jù Lọ
ÀWỌN èèyàn tó ní Bíbélì báyìí ti pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Ohun tí ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ United Bible Societies sọ nìyẹn, nítorí pé Bíbélì táa pín kiri ní 1998 fi ohun tó lé ní ìdajì mílíọ̀nù pọ̀ ju ti ọdún tó ṣáájú rẹ̀ lọ. Lápapọ̀, Bíbélì tó lé ní ẹgbẹ̀ta dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mílíọ̀nù [585,000,000]—lápá kan tàbí lódindi—la pín káàkiri àgbáyé. Ìròyìn náà sọ pé: “Èyí wúni lórí gidigidi. Nítorí pé àwọn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dé ọ̀dọ̀ wọn lónìí ti pọ̀ sí i.”
Àmọ́ ṣá o, ìyàtọ̀ wà láàárín níní Bíbélì àti kíkà á. Fún àpẹẹrẹ, ìròyìn kan fi hàn pé ó lé ní ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà tó ní, ó kéré tán, Bíbélì kan, àwọn tó sì tó iye yẹn ló gbà pé Bíbélì jẹ́ orísun ẹ̀kọ́ ìwà rere. Àmọ́, ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́ta péré ló sọ pé àwọ́n ń yíjú sí Bíbélì fún àmọ̀ràn. Ìpín mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló jẹ́wọ́ pé àwọn “ò fi bẹ́ẹ̀” lóye Bíbélì tàbí pé àwọn “ò tiẹ̀” lóye rẹ̀ rárá.
Yàtọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ Bíbélì, tí wọ́n sì ń pín in kiri, wọ́n tún ń bá àwọn ènìyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ ní ohun tó lé ní ọgbọ̀nlénígba ilẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jákèjádò ayé ló ń jàǹfààní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí ní báyìí. Wọ́n ń gba ìrànlọ́wọ́ nípa bí wọn ó ṣe kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ní báyìí, wọ́n sì tún ń kọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú amọ́kànyọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tí yóò wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run—Aísáyà 48:17, 18; Mátíù 6:9, 10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
(Láti apá òsì sí apá ọ̀tún) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ní Bolivia, Gánà, Sri Lanka, àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì