A Tú Ìwé Dáníẹ́lì Palẹ̀!
A Tú Ìwé Dáníẹ́lì Palẹ̀!
ÀWỌN tó wá ṣèpàdé ti ń hára gàgà láti gba ẹ̀dà tiwọn lára ìwé tuntun olójú ewé ọ̀ọ́dúnrún ó lé ogún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde náà, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Kí ni ìmọ̀lára àwọn ènìyàn nípa ìwé náà? Gbé ohun tí àwọn kan sọ yẹ̀ wò.
“Bó ṣe máa ń ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́langba, ó máa ń ṣòro fún mi láti ka àwọn ìwé ìtàn àtijọ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí mo gba ẹ̀dà tèmi lára ìwé náà, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! kò fi bẹ́ẹ̀ wú mi lórí láti kà, àmọ́ mo gbìyànjú ẹ̀ wò. Àwé, àṣé ọ̀rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò! Ìwé nìwé yìí o. Àní n ò lè gbé e sílẹ̀! N ò tiẹ̀ wá mọ̀ pé ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣẹ́yìn ni mò ń kà mọ́. Fún ìgbà àkọ́kọ́, mo wá rí ara mi ní ipò tí Dáníẹ́lì wà. Mo wá lè fojú inú wo bó ṣe máa ń rí tí wọ́n bá mú ọ kúrò lọ́dọ̀ ìdílé rẹ, tí wọ́n mu ọ lọ sílẹ̀ òkèèrè, tí wọ́n sì ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò léraléra níbẹ̀. Ẹ ṣe gan-an fún ìwé yìí.”—Anya.
“Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ jù lọ ni ìhìn iṣẹ́ tó ṣe kedere náà pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa ń darí àwọn ọ̀ràn tó bá kan àwọn ènìyàn rẹ̀. Àwọn ìran tí Dáníẹ́lì rí àtàwọn àlá tó lá, títí kan èyí tó túmọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn fi hàn kedere pé ohunkóhun tí Ọlọ́run wa bá yọ̀ǹda kó ṣẹlẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tó bá ète rẹ̀ mu. Èyí mú kí ìrètí tí a ní nínú àwọn ìran àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì nípa ayé tuntun tí òun yóò mú wá túbọ̀ lókun sí i.”—Chester.
“Mo gbádùn ọ̀nà tí ẹ gbà mú kí Dáníẹ́lì dà bí ẹni tó ṣì wà láàyè. Ọ̀nà tí ẹ gba tẹnu mọ́ bó ṣe bìkítà tó àti àwọn àníyàn rẹ̀ mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Mo wá túbọ̀ lóye ìdí tí Jèhófà fi kà á sí ẹni tó fani lọ́kàn mọ́ra gan-an. Kò ṣàníyàn nípa ara rẹ̀ rárá ní gbogbo àkókò tó fi kojú àdánwò àti inúnibíni. Ohun tó jẹ́ olórí àníyàn rẹ̀ ni Jèhófà àti orúkọ Rẹ̀ gíga lọ́lá. Ẹ ṣeun tí ẹ jẹ́ kí kókó yìí ṣe kedere.”—Joy.
“Ohun táa ti ń retí rèé! A ò tí ì fìgbà kan rí mọ bí ìwé Dáníẹ́lì ṣe kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tó. Lẹ́yìn tí mo ti ka apá púpọ̀ lára ìwé tuntun náà lálẹ́ ọjọ́ tí mo gbà á gan-an, mo ní láti dánu dúró, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà.”—Mark.
“Ohun tí a kò retí rárá ni ipa tí yóò ní lórí àwọn ọmọ wa. Ọ̀kan nínú wọn jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta. . . . Bó ṣe jẹ́ pé ìtàn Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà ti wà lára àwọn ìtàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jù nínú Iwe Itan Bibeli Mi, ọ̀nà tí ẹ gbà gbé e kalẹ̀ nínú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ti nípa lórí wọn gan-an lọ́nà kan tí a kò retí. Kódà bí wọ́n ṣe kéré tó lọ́jọ́ orí yẹn, ó dàbí ẹni pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti fara wé àwọn ọ̀dọ́kùnrin olódodo wọ̀nyẹn. Àgbàyanu àwòkọ́ṣe ni wọ́n mà jẹ́ fún àwọn ọmọ wa o! Irin iṣẹ́ tó fakíki lẹ fún wa yìí o! Ẹ ṣeun, a dúpẹ́ gan-an ni!”—Bethel.
“O dàbí pé mo wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù wọ̀nyẹn ni, bí wọ́n ti ń kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn; ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́ láti yẹ ìgbàgbọ́ tèmi náà wò. Àpótí àtúnyẹ̀wò náà “Kí Lo Lóye?” tẹ kókó tó wà lábẹ́ àkòrí kọ̀ọ̀kan mọ́ni lọ́kàn. Ẹ ṣeun lẹ́ẹ̀kan sí i fún ìwé àgbàyanu mìíràn.”—Lydia.