Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Ara Rẹ?
Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Ara Rẹ?
AGBÉRAGA ẹ̀dá ni ẹni táa fẹ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba, ni àpọ́nlé àti iyì táwọn èèyàn ń fún un bá mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ganpá. Àmọ́ nítorí pé ìjòyè kan kò bu irú iyì yẹn fún un, ló bá tutọ́ sókè, ló fojú gbà á. Láti gbẹ̀san ọ̀rọ̀ yìí, ni ìjòyè onírera burúkú yìí bá tagbọ́n láti rẹ́yìn gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹ̀lú ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, tí wọ́n wà lábẹ́ ilẹ̀ ọba náà. Áà àá, ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú yìí mà gàgaàrá o!
Hámánì lẹni tó ń tagbọ́n burúkú yìí, àgbà ìjòyè ló sì jẹ́ ní ààfin Ahasuwérúsì Ọba Páṣíà. Ta lẹni tó ń ṣe ẹ̀tanú sí gan-an? Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣejù ti wọ ìwà pípa odindi ẹ̀yà kan run tí Hámánì gùn lé yìí, síbẹ̀ èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbéraga léwu àti pé ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dára rárá. Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí èmi-ni-mo-tó-báyìí tó ta lé e dá wàhálà sílẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, ó tún jẹ́ kó di ẹni tó tẹ́ ní gbangba, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó yọrí sí ikú fún un.—Ẹ́sítérì 3:1-9; 5:8-14; 6:4-10; 7:1-10.
Ẹ̀mí Ìgbéraga Lè Ran Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́
Jèhófà fẹ́ ká ‘jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run wa rìn.’ (Míkà 6:8) Bíbélì ní oríṣiríṣi ìtàn nípa àwọn ènìyàn kan tí wọn ò mẹ̀tọ́mọ̀wà. Èyí kó wọn síṣòro, ó tún kó ẹ̀dùn-ọkàn bá wọn. Gbígbé díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìwà òmùgọ̀ àti ewu tó wà nínú ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú.
Wòlíì Ọlọ́run nì, Jónà, jọra rẹ̀ lójú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi fẹ́ sá lọ nígbà tí Ọlọ́run rán an láti lọ kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn búburú tó wà ní Nínéfè pé ìdájọ́ Jèhófà ń bọ̀ sórí wọn. (Jónà 1:1-3) Lẹ́yìn èyí, nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù Jónà mú kí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, ló bá wúgbọ kalẹ̀ bí ẹni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Jíjẹ́ tí ó jẹ́ wòlíì mú kí ó jọ ara rẹ̀ lójú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi ka ìwàláàyè ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Nínéfè sí rárá. (Jónà 4:1-3) Táa bá lọ jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga mú ká jọra wa lójú, ó lè ṣòro fún wa láti máa fojú tó yẹ wo àwọn tó yí wa ká, a ò sì ní ka àwọn ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa sí .
Gbé ọ̀ràn ti Ùsáyà náà yẹ̀ wò, ẹni tó jẹ́ ọba rere ní Júdà. Nígbà tó di ẹni tó jọra rẹ̀ lójú, ni ẹ̀mí èmi-ni-mo-tó–báyìí bá tì í láti fẹ́ gba iṣẹ́ àwọn àlùfáà ṣe. Nítorí tí ìgbéraga ẹ̀ pọ̀, tí ìwà ọ̀yájú ẹ̀ sì tún ga, ó fi ìlera rẹ̀ dí i, ó sì tún pàdánù ojú rere Ọlọ́run.—2 Kíróníkà 26:3, 16-21.
Díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú kó bá àwọn àpọ́sítélì Jésù. Ògo àti agbára wọn ká wọn lára ju bó ti yẹ lọ. Ìgbà tí àkókò àdánwò ńlá wá dé, wọ́n fi Jésù sílẹ̀, wọ́n bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀. (Mátíù 18:1; 20:20-28; 26:56; Máàkù 9:33, 34; Lúùkù 22:24) Díẹ̀ báyìí ló kù kí ẹ̀mí ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú sọ wọ́n di ẹni tó gbàgbé ète Jèhófà àti ipa tí wọ́n ń kó nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Ọṣẹ́ Tí Ẹ̀mí Ìjọra-Ẹni-Lójú Ń Ṣe
Táa bá jọra wa lójú, ó lè kó ìbànújẹ́ bá wa, ó sì lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, a lè wà nínú yàrá kan, kí a sì ṣàkíyèsí pé tọkọtaya kan ń fetí ko ara wọn létí, tí wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín. Báa bá jẹ́ anìkànjọpọ́n, a lè máa rò pé àwa ni wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé a ò gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Ìrònú wa lè máà jẹ́ ká ronú ohun mìíràn tó ṣeé ṣe kó máa ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀ náà, ọ̀rọ̀ ta ni wọ́n tún lè máa sọ? Inú lè bí wa, ká sì pinnu pé a ò ní sọ̀rọ̀ sí wọn mọ́. Nípa báyìí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú lè yọrí sí èdè
àìyedè, ó sì lè ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́, mẹ́ńbà ìdílé, àti àwọn ẹlòmíràn jẹ́.Àwọn tó jọra wọn lójú lè di afọ́nnu, tí wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀bùn tí wọ́n ní, ìwà wọn, tàbí ohun ìní wọn fọ́ táá. Tàbí tí ọ̀rọ̀ bá délẹ̀, wọ́n á fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn nìkan ló sọ gbogbo rẹ̀ pátá, kò sí ni, wọ́n á rí nǹkan kan sọ nípa ara wọn. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fi àìnífẹ̀ẹ́ hàn, ó sì máa ń mú inú bíni. Ìdí rèé táwọn èèyàn ṣe máa ń jìnnà sí àwọn tó bá ń wú fùkẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 13:4.
Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ènìyàn lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì lè kọ etí ikún sí wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba wa. Ó yẹ ká rántí pé kì í ṣe àwa gan-an ni wọ́n ń ta kò, bí kò ṣe, Jèhófà, Orísun iṣẹ́ tí à ń jẹ́. Ṣùgbọ́n o, táa bá lọ jọra wa lójú, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ ò ní dáa rárá. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, onílé kan mú arákùnrin kan bú, ọ̀rọ̀ náà dun arákùnrin náà, lòun náà bá yọ èébú lára onílé náà. (Éfésù 4:29) Lẹ́yìn ìyẹn, arákùnrin náà ò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbéraga lè mú ká fara ya nígbà tí a bá ń wàásù. Ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi, kí irú rẹ̀ má ṣe ṣẹlẹ̀ sí wa. Kàkà tí yóò fi ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti lè ní ìmọrírì tó tọ́ fún àǹfààní táa ní láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.—2 Kọ́ríńtì 4:1, 7; 10:4, 5.
Táa bá jọra wa lójú, ó tún lè máà jẹ́ ká máa gbàmọ̀ràn tó bá yẹ. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ní orílẹ̀-èdè kan tó wà ní Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ àsọyé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run nínú ìjọ Kristẹni. Nígbà tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà fún un ní ìmọ̀ràn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ni ọmọdékùnrin tí inú ti bí gidigidi yìí bá jan Bíbélì rẹ̀ mọ́lẹ̀, ló sì bínú jáde kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú èrò pé òun ò tún ní padà wọbẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó pa ẹ̀mí ìgbéraga tì, ó yanjú ọ̀ràn náà pẹ̀lú alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà, ó sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Láìpẹ́ jọjọ, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí di Kristẹni tó dàgbà dénú.
Tí a kò bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, táa bá jọra wa lójú jù, ó lè yọrí sí bíba ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Òwe 16:5 fà wá létí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”
Níní Ẹ̀mí Àìjọra-Ẹni-Lójú
Ó ti ṣe kedere pé, kò yẹ ká jọra wa lójú. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká kàn máa sọ̀rọ̀ láìbìkítà, tàbí ká máa hùwà bí ẹni tí kì í ka nǹkan sí. Bíbélì fi hàn pé àwọn alábòójútó, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́—àní, gbogbo ìjọ—gbọ́dọ̀ ní ìwà àgbà. (1 Tímótì 3:4, 8, 11; Títù 2:2) Nítorí náà báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, ẹni tó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí kò jọra rẹ̀ lójú?
Bíbélì pèsè ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tí kò jọ ara wọn lójú. Táa bá ń sọ̀rọ̀ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ti Jésù Kristi kò láfiwé rárá. Kí Ọmọ Ọlọ́run lè ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀, kó sì lè mú kí aráyé rí ìgbàlà, ó fi ipò ológo tó ní lọ́run sílẹ̀, ó sì di ẹ̀dá ènìyàn rírẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Pẹ̀lú pé wọ́n láálí ẹ̀, tí wọ́n yọ èébú lára ẹ̀, tí wọ́n sì pa á lọ́nà tó tàbùkù ẹni, ó kóra rẹ̀ níjàánu, ó sì fọ̀wọ̀ wọ ara rẹ̀. (Mátíù 20:28; Fílípì 2:5-8; 1 Pétérù 2:23, 24) Kí ló fún Jésù láǹfààní láti ṣe èyí? Ó gbára lé Jèhófà pátápátá, ó sì pinnu láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Jésù kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó fìtara gbàdúrà, ó sì lo ara rẹ̀ tokunratokunra nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Mátíù 4:1-10; 26:36-44; Lúùkù 8:1; Jòhánù 4:34; 8:28; Hébérù 5:7) Báa bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ní ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú.—1 Pétérù 2:21.
Tún ronú nípa àpẹẹrẹ ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba, ìyẹn Jónátánì. Nítorí tí baba rẹ̀ jẹ́ aláìgbọràn, òun ló fà á tí Jónátánì kò fi ní àǹfààní láti jọba tẹ̀ lé baba rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 15:10-29) Ǹjẹ́ inú bí Jónátánì nítorí ohun tó pàdánù? Ǹjẹ́ ó torí bẹ́ẹ̀ ṣe ìlara Dáfídì, ọ̀dọ́mọkùnrin tí yóò gbapò rẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì ju Dáfídì lọ, tó sì ṣeé ṣe kó ní ìrírí jù ú lọ, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kó fara mọ́ ètò tí Jèhófà ṣe, ó sì kọ́wọ́ ti Dáfídì lẹ́yìn gbágbáágbá. (1 Sámúẹ́lì 23:16-18) Tí òye wa nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ bá ṣe kedere, táa sì ṣe tán láti ṣe é, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ‘má ṣe ro ara wa ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.’—Róòmù 12:3.
Jésù kọ́ wa ní ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tó tún lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó ṣàkàwé èyí nípa sísọ pé, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bá lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, wọn kò gbọ́dọ̀ lọ jókòó sí ‘ibi tó yọrí ọlá jù lọ’ nítorí pé ẹni tó tún ṣe pàtàkì jù wọ́n lọ lè dé, ojú á sì tì wọ́n, nígbà tí a bá wá ní kí wọ́n dìde lọ jókòó sí ibi tó rẹlẹ̀ ju ti ìṣáájú. Kí ẹ̀kọ́ náà lè túbọ̀ ṣe kedere, Jésù fi kún un pé: Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Lúùkù 14:7-11) Yóò fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n, báa bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù, táa sì ‘fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú wọ ara wa láṣọ.’—Kólósè 3:12; 1 Kọ́ríńtì 1:31.
Àwọn Ìbùkún Tí Ẹ̀mí Àìjọra-Ẹni-Lójú Ń Mú Wá
Jíjẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà àti onírẹ̀lẹ̀ ń ran àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tòótọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ó túbọ̀ máa ń rọrùn láti sún mọ́ àwọn alàgbà nígbà tí wọ́n bá ń lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti “fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo.” (Ìṣe 20:28, 29) Èyí yóò jẹ́ kí ara gbogbo àwọn tó bá wà nínú ìjọ balẹ̀ láti bá wọn sọ̀rọ̀ àti láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀ a ó lè mú kí ìjọ wà papọ̀ nínú ẹ̀mí ìfẹ́, ọ̀yàyà, àti ìfọkàntán.
Bí a kò ba jọra wa lójú yóò rọrùn fún wa láti ní àwọn ọ̀rẹ́ rere. Jíjẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà àti onírẹ̀lẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe mú ẹ̀mí ìdíje dàgbà, a kò sì ní fẹ́ máa tayọ àwọn ẹlòmíràn nínú ìṣe àti ní ti ohun ìní ti ara. Àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ agbatẹnirò, èyí yóò sì jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti tu àwọn tí wọ́n ṣaláìní nínú, kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Fílípì 2:3, 4) Nígbà tí ìfẹ́ àti inú rere bá wú àwọn èèyàn lórí, wọ́n sábà máa ń fi ẹ̀mí tó dáa hàn. Ṣe bí ìbátan tí kò ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan nínú náà ló ń di ìpìlẹ̀ ọ̀rẹ́ tó lágbára? Àǹfààní ló mà jẹ́ o, tí a kò bá jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga mú kí a jọra wa lójú ju bó ti yẹ!—Róòmù 12:10.
Tá ò bá jọra wa lójú, yóò rọrùn fún wa láti gba àṣìṣe wa nígbà táa bá ṣẹ ẹnì kan. (Mátíù 5:23, 24) Èyí ń yọrí sí àjọṣe tó dán mọ́rán sí i, ó ń jẹ́ ká lè parí aáwọ̀, kí a sì máa bọ̀wọ̀ fúnra wa lẹ́nì kìíní kejì. Bí àwọn alábòójútó, ìyẹn àwọn Kristẹni alàgbà bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọn mẹ̀tọ́mọ̀wà, wọn yóò lè láǹfààní láti túbọ̀ ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (Òwe 3:27; Mátíù 11:29) Ó tún máa ń rọrùn fún ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ láti tètè dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́. (Mátíù 6:12-15) Kò ní fara ya nítorí tó rò pé ẹnì kan kò ka òun sí, yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láti yanjú ọ̀ràn tí kò sóhun téèyàn lè ṣe sí i.—Sáàmù 37:5; Òwe 3:5, 6.
Ìbùkún tó ga jù táa lè ní bí a bá mẹ̀tọ́mọ̀wà, táa sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé a óò rí ojú rere àti ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Ǹjẹ́ kí a má ṣe jìn sínú ọ̀fìn ríronú pé a jẹ́ nǹkan tí a kò jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba ipò táa wà nínú ètò tí Jèhófà ṣe. Ìbùkún kíkọyọyọ wà ní ìpamọ́ fún gbogbo àwọn tó bá kún ojú ìwọ̀n ‘jíjẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn.’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni Jónátánì fi kọ́wọ́ ti Dáfídì lẹ́yìn