Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìforítì Ní Ń Múni Ṣàṣeyọrí

Ìforítì Ní Ń Múni Ṣàṣeyọrí

Ìforítì Ní Ń Múni Ṣàṣeyọrí

ÌFORÍTÌ ti wá di ohun tó ṣọ̀wọ́n gan-an láyé òde òní. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ọ̀ràn ṣíṣàṣeyọrí kì í ṣe pé ká ní ìforítì bí kò ṣe pé ká rí i pé a wà níbi tó yẹ ká wà lákòókò tó yẹ. Ta ló wá fẹ́ sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí? Ohun táa máa ń fìgbà gbogbo gbọ́ nínú ìròyìn ni àwọn ọ̀rọ̀ ìpolówó ọjà tó jẹ́ pé èrò tó ń fi síni lọ́kàn ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohunkóhun tóo bá ń fẹ́ ló lè tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ tóo bá ṣáà ti sapá díẹ̀, tóo sì náwó díẹ̀ lé e lórí. Àwọn ìwé ìròyìn ǹ gbé ìtàn rẹpẹtẹ jáde nípa àwọn tó ń ṣàṣeyọrí lọ́sàn-án-kan-òru-kan àti nípa àwọn ọmọdé tí wọ́n ń dáwọ́ lé okòwò ní gbàrà tí wọ́n ń jáde ile ìwé, tí wọ́n sì ti lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀.

Leonard Pitts tó jẹ́ òǹkọ̀wé ìròyìn kédàárò pé: “Nínú àwùjọ kan tí ìmọ̀ gbà lọ́kàn yìí, ó dàbí ẹni pé dídi ẹni ńlá ò ṣòro rárá. . . . Àfi bí ẹni fẹran jẹ̀kọ, tí olúwaarẹ̀ bá sáà ti lágbára àtiṣe é, tàbí tí Ọlọ́run bá ti gbà fún un bẹ́ẹ̀.”

Kí Ni Ìforítì?

Ìforítì túmọ̀ sí láti ‘dúró ṣinṣin láìyẹsẹ̀ lórí àwọn ète kan, ipò kan, tàbí àwọn ìdáwọ́lé kan láìka àwọn ìdènà tàbí ìfàsẹ́yìn tó lè mú wá sí.’ Ó túmọ̀ sí fífarada ìpọ́njú, ká máa rọ́jú, ká má sì juwọ́ sílẹ̀. Bíbélì tẹnu mọ́ bí ànímọ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó. Fún àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà,” “ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín,” “ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà,” kí ẹ sì “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀ mú ṣinṣin.”—Mátíù 6:33; Lúùkù 11:9; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:21.

Apá kan tó ṣe pàtàkì nínú ìforítì ni fífarada àwọn ìfàsẹ́yìn kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Kàkà kí ẹni tó ní ìforítì ‘juwọ́ sílẹ̀’ nígbà tó bá dojú kọ ìṣòro tàbí ìdènà, ńṣe ni yóò ‘gbéra ńlẹ̀,’ ‘tí yóò tẹ̀ síwájú,’ tí yóò sì tún máa gbìyànjú rẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ni kì í múra de ìṣòro tàbí ìdènà tí wọ́n ń bá pàdé. Nígbà tó jẹ́ pé wọn ò fìgbà kan ní in lọ́kàn pé àwọn ó forí tì í, kíá ni wọ́n ó juwọ́ sílẹ̀. Òǹkọ̀wé Morley Callaghan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń bara jẹ́ jù bó ti yẹ lọ nígbà tí nǹkan tí wọ́n ń fẹ́ ò bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n á wá máa káàánú ara wọn, wọ́n á máa dá gbogbo èèyàn lẹ́bi, wọ́n á máa kanra gógó, wọ́n á wá . . . juwọ́ sílẹ̀.”

Ó mà ṣe o. Pitts là á mọ́lẹ̀ pé: “Ó jọ pé a máa ń gbàgbé pé ìdí kan wà tó fi yẹ ká la àdánwò kọjá, ìyẹn ni pé àwọn àǹfààní kan wà táa lè rí nínú ìpọ́njú.” Irú àǹfààní wo nìyẹn o? Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “[Ẹni náà] á kẹ́kọ̀ọ́ pé béèyàn bá ṣubú ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò lè dìde mọ́, kò túmọ̀ sí pé kò lè gbérí mọ́ nílé ayé. Olúwaarẹ̀ yóò túbọ̀ lókun sí i ni. Ẹni náà yóò ti wá múra pé ibi tó bá le làá bọ́mọkùnrin.” Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn pé: “Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà.”—Òwe 14:23.

Ní ti tòótọ́, kì í sábà rọrùn láti tún máa bá a nìṣó lẹ́yìn tí ìfàsẹ́yìn bá dé báni. Nígbà mìíràn, a lè dojú kọ àwọn ìpèníjà tó lè dà bí èyí tí yóò sọ gbogbo ìsapá wa láti borí àwọn ìṣòro náà di ohun tí kò gbéṣẹ́ mọ́. Kàkà tá ó fi rọ́nà àtiyanjú ìṣòro náà, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni àwọn góńgó tí a ń lépa yóò fi di àléèbá mọ́ wa lọ́wọ́. Ọkàn wa lè wá pòrúùru, ká wá dà bí ẹni tí ò mọ̀ọ́ṣe mọ́, kí ilé ayé wá sú wa pátápátá, kí ìbànújẹ́ wá dorí wa kodò. (Òwe 24:10) Síbẹ̀, Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”Gálátíà 6:9.

Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ní Ìforítì?

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti forí ti nǹkan ni pé kí a gbé góńgó kan tó ní láárí, tí ọwọ́ wá sì lè tẹ̀ kalẹ̀. Ó dájú pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lóye èyí. Ó sọ fún àwọn ara Kọ́ríńtì pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tí òun ò bá fẹ́ kí ìsapá òun já sásán, òun gbọ́dọ̀ ní góńg̣ó kan pàtó, bíi ti sárésáré tó fọkàn rẹ̀ sí bí òun yóò ṣe dé òpin eré ìje náà. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 9:24, 26) Báwo la ṣe lè ṣe èyí?

Òwe 14:15 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Ó jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ká máa ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe ń lo ìgbésí ayé wa, kí a máa bi ara wa pé níbo là ń lọ, ká sì wò ó bóyá àwọn àtúnṣe kan wà táa gbọ́dọ̀ ṣe. Ó ṣe pàtàkì pé kí a mọ ohun táa fẹ́ ṣe, ká sì mọ ìdí tí a fi fẹ́ ṣe é. A ò ní tètè juwọ́ sílẹ̀ bí a bá ń fojú inú wo ibi tí a ń lọ gan-an. Òwe onímìísí náà rọni pé: “Ní ti ojú rẹ, ọ̀kánkán tààrà ni kí ó máa wò, . . . kí gbogbo àwọn ọ̀nà tìrẹ [lè] fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—Òwe 4:25, 26.

Lẹ́yìn tóo bá ti mọ àwọn góńgó rẹ dájú, ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e ni pé kí o fara balẹ̀ ronú lórí bí o ṣe lè lé wọn bá. Jésù béèrè pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà?” (Lúùkù 14:28) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yìí, ògbógi kan nínú ìtọ́jú àrùn ọpọlọ sọ pé: “Ohun kan tí mo ti ṣàkíyèsí nípa àwọn èèyàn tó ṣàṣeyọrí ni pé wọ́n mọ̀ dájú pé ẹnu òfìfo kì í dún nàmùnàmù. Àwọn èèyàn tó ṣàṣeyọrí mọ̀ pé bí àwọn bá ń wá nǹkan, àwọn ò ní jókòó gẹlẹtẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe kí ọwọ́ àwọn lè tẹ̀ ẹ́.” Lílóye gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ kí a gbé láti lè rí ohun tí a ń fẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè pọkàn pọ̀ sórí góńgó wa. Yóò sì tún jẹ́ kó rọrùn fún wa láti túnra mú táa bá ní ìfàsẹ́yìn. Irú àgbéyẹ̀wò tó gba àròjinlẹ̀ yìí ló mú kí Orville àti Wilbur Wright ṣàṣeyọrí.

Nítorí náà, nígbà tí ìfàsẹ́yìn bá ṣẹlẹ̀, sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fi ẹ̀mí tí ó dára gbà á, kí o sì kà á sí ìrírí tó lè kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Gbé ipò náà yẹ̀ wò dáadáa, mọ ibi tóo ti ṣe àṣìṣe, kí o sì ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe náà tàbí kí o wá nǹkan ṣe sí ìkùdíẹ̀-káàtó náà. Fífikùn lukùn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tún máa ń ṣèrànwọ́, nítorí pé “ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 20:18) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, ìsapá kọ̀ọ̀kan tí o bá ṣe ni yóò máa fún ọ lóye àti ọgbọ́n sí i, èyí tí yóò wá ṣàlékún àṣeyọrí rẹ níkẹyìn.

Apá kẹta tó pọndandan nínú ìforítì ni pé ká má ṣe ju ara wa lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòlétò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.” (Fílípì 3:16) Bí olùkọ́ni kan ṣe ṣọ ọ́ ni pé, “jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ẹni tí kì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ máa ń yọrí sí ohun tó dára.” Èyí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ dáadáa nínú ìtàn àròsọ tí Aesop sọ nípa ìjàpá àti ehoro, èyí táa mọ̀ bí ẹní mowó. Ìjàpá ló borí nínú eré ìje náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè sáré tó ehoro rárá. Kí nìdí ẹ̀? Ìdí ni pé ìjàpá ṣe bó ti mọ, kò ṣe ju ara rẹ̀ lọ. Kò lóun ò sáré mọ́, àmọ́ ó rọra ń lọ bí agbára rẹ̀ ṣe mọ, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe títí tó fi dé òpin eré ìje náà. Èyí fi hàn pé ẹni tó wà létòlétò, tí kì í sì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ yóò máa ní ìlọsíwájú déédéé, kò ní sú u, kò sì ní juwọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó di ẹni tó fìdí rẹmi níbi eré ìje. Òdodo ọ̀rọ̀ lèyí o, “ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀” kí ọwọ́ yín lè tẹ góńgó yín.

Yíyan Góńgó Tó Ní Láárí

Ó dájú pé kí ìforítì tó lè múni ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ ní àwọn góńgó tó ní láárí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lépa àwọn nǹkan tí kì í mú ayọ̀ wá. Àmọ́, Bíbélì sọ ọ́ ní kedere pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn . . . yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Jákọ́bù 1:25) Bẹ́ẹ̀ ni, kíkẹ́kọ̀ọ́ láti lóye òfin Ọlọ́run tí a là lẹ́sẹẹsẹ sínú Bíbélì jẹ́ góńgó kan tí ó ní láárí. Èé ṣe? Ní pàtàkì, ìdí ni pé a gbé òfin Ọlọ́run ka ìlànà tí ó pé, tó sì jẹ́ ti òdodo. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, ó mọ ohun tí ó lè ṣe àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ láǹfààní. Nítorí náà, bí a bá tẹra mọ́ kíkọ́ àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run, tí a sì ń fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé wa, ó dájú pé irú ìforítì bẹ́ẹ̀ yóò fún wa ní ayọ̀. Òwe 3:5, 6 ṣèlérí pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà . . . Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”

Ní àfikún sí i, Jésù sọ pé gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti òun sínú ló ń “túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 17:3) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí. (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:3-13) Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run, ìṣàkóso òdodo rẹ̀, yóò dé fún àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Ìjọba yìí yóò mú àkókò àlàáfíà tí kò sí irú rẹ̀ rí, áásìkí, àti ìdẹ̀rùn wá fún gbogbo ìran ènìyàn onígbọràn. (Sáàmù 37:10, 11; Ìṣípayá 21:4) Ìṣe 10:34 sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo ènìyàn la pè láti wá gbádùn àwọn àǹfààní yìí!

Ìwé àtayébáyé tó kún fún ọgbọ́n, tó sì nítumọ̀ ni Bíbélì. Ó ń gba àkókò àti ìsapá ká tó lè lóye rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run—tí a bá sì tẹra mọ́ wíwá ìmọ̀ rẹ̀—yóò yé wa yékéyéké. (Òwe 2:4, 5; Jákọ́bù 1:5) Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti fi ohun tí a ń kọ́ sílò. Ó lè gbà pé kí a yí ìrònú àti ìwà wa padà. Àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mẹ́ńbà ìdílé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa pàápàá lè takò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí ìforítì fi ṣe pàtàkì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé Ọlọ́run yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí wọ́n bá ní “ìfaradà nínú iṣẹ́ rere.” (Róòmù 2:7) lnú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ góńgó yìí.

Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé wàá ṣàṣeyọrí bóo bá tẹra mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì ń fi ohun tí ò ń kọ́ sílò ní gbogbo ìgbà.—Sáàmù 1:1-3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Wàá ṣàṣeyọrí bóo bá tẹra mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Culver Pictures