Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Látọ̀dọ̀ Ìyá Kan
Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Látọ̀dọ̀ Ìyá Kan
“Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.”—Òwe1:8.
ÀWỌN òbí wa—baba àti ìyá wa—lè jẹ́ orísun ṣíṣeyebíye táa ti lè rí ìṣírí, ìtìlẹ́yìn, àti ìmọ̀ràn gbà. Ìwé Òwe inú Bíbélì sọ nípa ọ̀dọ́mọdé ọba kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lémúẹ́lì, ẹni tó gba “ìhìn iṣẹ́ wíwúwo” tó jẹ́ “ìtọ́sọ́nà” látọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí la kọ sínú Òwe orí kọkànlélọ́gbọ̀n, àwa náà sì lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ ìyá yìí.—Òwe 31:1.
Ìmọ̀ràn Tó Yẹ Ọba
Ìyá Lémúẹ́lì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tó ru ìfẹ́ ọkàn wa sókè, ó ní: “Kí ni mo ń sọ, ìwọ ọmọ mi, kí sì ni, ìwọ ọmọ ikùn mi, kí sì ni, ìwọ ọmọ àwọn ẹ̀jẹ́ mi?” Bó ṣe pàrọwà nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fi hàn pé ó ń ṣàníyàn gan-an pé kí ọmọ òun jọ̀wọ́ fetí sí ọ̀rọ̀ òun. (Òwe 31:2) Àníyàn tó ní fún ire tẹ̀mí ọmọ rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn òbí Kristẹni lónìí.
Ní sísọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà ọmọ rẹ̀, kí ló tún lè máa da ìyá kan láàmú bí kò bá ṣe àríyá aláriwo àti ìwà fífi ọtí, obìnrin, àti orin kẹ́ra ẹni bà jẹ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nínú òwe yìí? Ìyá Lémúẹ́lì kúkú sọjú abẹ níkòó pé: “Má fi ìmí rẹ fún àwọn obìnrin.” Ó ka ìwà ìṣekúṣe sí “ohun tí ń ṣokùnfà nínu àwọn ọba nù.”—Òwe 31:3.
Kó yẹ ká gbójú fo mímu ọtí lámujù. Ó kìlọ̀ pé: “Kì í ṣe fún àwọn ọba, Lémúẹ́lì, kì í ṣe fún àwọn ọba láti máa mu wáìnì.” Báwo ni ọba kan ṣe lè ṣe ìdájọ́ tó yè kooro, tó fi hàn pé ó ní làákàyè, kí ó má sì “gbàgbé ohun tí a fàṣẹ gbé kalẹ̀, kí ó sì ṣe ìyípo ọ̀ràn ẹjọ́ èyíkéyìí lára àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́” tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń mutí yó kẹ́ri?—Òwe 31:4-7.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, tí ọba náà kò bá bá wọn lọ́wọ́ nínú irú ìwà játijàti bẹ́ẹ̀, yóò rọrùn fún un láti “ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo, kí o sì gba ọ̀ràn ẹjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì rò.”—Òwe 31:8, 9.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lè máà jẹ́ “ọba” lóde òní, síbẹ̀ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n látọ̀dọ̀ ìyá Lémúẹ́lì bá àkókò mu gẹ́ẹ́, ó tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ bá a mu jù pàápàá. Mímu ọtí lámujù, mímu tábà, àti ṣíṣe ìṣekúṣe jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe òde òní, ó sì ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni fetí sílẹ̀ nígbà tí àwọn òbí wọn bá ń fún wọn ní ‘àwọn ìhìn iṣẹ́ wíwúwo.’
Aya Tí Ó Dáńgájíá
Nígbà táwọn ọmọkùnrin wọn bá ti ń di géńdé, àwọn ìyá sábà máa ń ṣàníyàn nípa irú aya tí ọmọ
wọn máa fẹ́. Ohun tí ìyá Lémúẹ́lì tún pe àfiyèsí sí lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn ànímọ́ tí aya kan tó dáńgájíá gbọ́dọ̀ ní. Ó dájú pé bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan bá ronú jinlẹ̀ lórí ojú tí obìnrin kan fi ń wo ọ̀ràn pàtàkì yìí, yóò ṣe ara rẹ̀ láǹfààní tó pọ̀.Ní ẹsẹ ìkẹ́wàá, ó fi “aya tí ó dáńgájíá” wé iyùn tó níye lórí, tó sì ṣọ̀wọ́n, tó jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kó tó lè rí i ní àkókò tí a kọ Bíbélì. Lọ́nà kan náà, kéèyàn tó lè rí aya tó dáńgájíá yóò sapá gidigidi. Dípò tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan yóò fi kánjú wọnú ìgbéyàwó, yóò dára kí ó fara balẹ̀ ná, kó ṣe àṣàyàn. Nígbà náà, yóò ṣeé ṣe fún un láti mọyì ohun iyebíye tó rí yìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa aya tó dáńgájíá, ó sọ fún Lémúẹ́lì pé: “Ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e.” (Ẹsẹ 11) Lọ́rọ̀ mìíràn, kò gbọ́dọ̀ máa retí pé gbogbo ohun tí aya òun bá fẹ́ ṣe ló gbọ́dọ̀ tọ òun wá fún, kí òun lè fọwọ́ sí i. Ní ti tòótọ́, tọkọtaya ní láti máa fikùn lukùn kí wọ́n tó ṣe ìpinnu pàtàkì, bí irú èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ríra nǹkan tó bá jẹ́ olówó ńlá tàbí tó bá kan ọ̀ràn títọ́ àwọn ọmọ wọn. Jíjùmọ̀sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀ràn báwọ̀nyí yóò jẹ́ kí ìdè tó wà láàárín wọn lágbára sí i.
Dájúdájú, iṣẹ́ tó wà lọ́rùn obìnrin tó dáńgájíá kì í ṣe kékeré. Àwọn ìmọ̀ràn àti ìlànà tí àwọn aya lè lò fún àǹfààní ìdílé wọn ní gbogbo ìgbà la tò lẹ́sẹẹsẹ sí ẹsẹ kẹtàlá sí ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n. Fún àpẹẹrẹ, nísinsìnyí tí aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé ń gbówó lórí sí i, aya tó dáńgájíá yóò kọ́ bó ṣe lè máa fúnra rẹ̀ ṣe nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí yóò sì máa ṣún owó ná kí ìdílé rẹ̀ lè wọṣọ tó dára, kí wọ́n sì ṣeé rí mọ́ni. (Ẹsẹ 13, 19, 21, 22) Ó ń dáko tí apá rẹ̀ ká, ó sì ń nájà dáadáa kó tó rà á, kó baà lè dín owó tí ìdílé rẹ̀ ń ná sórí oúnjẹ kù.—Ẹsẹ 14, 16.
Ó hàn gbangba pé obìnrin yìí kì í “jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.” Ó ń ṣe iṣẹ́ àṣekára, ó sì láápọn láti bójútó ohun tó ń lọ lágbo ilé rẹ̀. (Ẹsẹ 27) Ó “fi okun di ìgbáròkó rẹ̀” ní àmùrè, tó túmọ̀ sí pé ó múra tán láti ṣe iṣẹ́ tó gba agbára. (Ẹsẹ 17) Yóò ti jí láàárọ̀ kùtù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀, yóò sì ṣe iṣẹ́ àṣekára títí di alẹ́. Ńṣe ló dà bí ẹni pé epo kìí tán nínú fìtílà tó ń tàn ṣe iṣẹ́ tirẹ̀.—Ẹsẹ 15, 18.
Lékè gbogbo rẹ̀, aya tó dáńgájíá jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ń fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ àti ojúlówó ẹ̀rù sìn ín. (Ẹsẹ 30) Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n lè máa ṣe bíi tàwọn òbí wọn. Ẹsẹ ìkẹrìndínlọ́gbọ̀n sọ pé: Ó ń fi “ọgbọ́n” tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni “òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀.”
Ọkọ Tó Dáńgájíá
Kí Lémúẹ́lì lè máa wu aya kan tó dáńgájíá, ó ní láti ṣe ojúṣe ọkọ tó dáńgájíá. Ìyá Lémúẹ́lì rán an létí ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúṣe wọ̀nyí.
Ọkọ tó dáńgájíá yóò jẹ́ ẹni tó ní ìròyìn rere lọ́dọ̀ “àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà.” (Òwe 31:23) Ìyẹn túmọ̀ sí pé onítọ̀húǹ yóò jẹ́ ẹni tó tóótun, tó jẹ́ olóòótọ́, tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 18:21; Diutarónómì 16:18-20) Nípa bẹ́ẹ̀, yóò di ẹni “mímọ̀ . . . ní àwọn ẹnubodè,” níbi tí àwọn ọkùnrin tó yọrí ọlá máa ń kóra jọ sí láti ṣètò ìlú. Kó tó lè di ẹni “mímọ̀” gẹ́gẹ́ bí olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ó ní láti jẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò, tí ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà “ilẹ̀” náà, ìyẹn lè jẹ́ àgbègbè tàbí ìpínlẹ̀ náà.
Ó dájú pé ìrírí tí ìyá Lémúẹ́lì fúnra rẹ̀ ti ní ló fi ń gba ọmọ rẹ̀ nímọ̀ràn nígbà tó rán an létí nípa bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti mọyì àfẹ́sọ́nà rẹ̀. Kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí i jù ú lọ. Wá fojú inú wo bí ohùn ọkùnrin náà yóò ṣe fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ hàn tó nígbà tó sọ níwájú gbogbo èèyàn pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin ní ń bẹ tí ó fi ìdáńgájíá hàn, ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ lékè gbogbo wọn.”—Òwe 31:29.
Ó hàn gbangba pé Lémúẹ́lì mọrírì ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí ìyá rẹ̀ fún un. Fún àpẹẹrẹ, a ṣàkíyèsí pé ní ẹsẹ ìkíní, ó tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyá rẹ̀ sọ bí ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi “ìtọ́sọ́nà” ìyá rẹ̀ sọ́kàn, ó sì jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn rẹ̀. Yóò dára kí àwa náà jèrè látinú “ìhìn iṣẹ́ wíwúwo” yìí nípa fífi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Aya tó dáńgájíá kì í jẹ “oúnjẹ ìmẹ́lẹ́”