Báwo Lo Ṣe Fẹ́ Kí Jèhófà Rántí Rẹ?
Báwo Lo Ṣe Fẹ́ Kí Jèhófà Rántí Rẹ?
“ỌLỌ́RUN mi, rántí mi.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Nehemáyà fi bẹ Ọlọ́run ní àwọn ìgbà bíi mélòó kan. (Nehemáyà 5:19; 13:14, 31) Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá pé ìgbà tí ìbànújẹ́ bá dorí àwọn èèyàn kodò ni wọ́n máa ń yíjú sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i lọ́nà yìí.
Ẹ dúró ná, kí làwọn èèyàn tiẹ̀ ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá sọ pé kí Ọlọ́run rántí àwọn? Ó dájú pé, wọ́n retí pé kí Ọlọ́run ṣe ju kí ó kàn rántí orúkọ wọn lásán lọ. Kò sí iyèméjì pé ohun kan náà tí ọ̀daràn tí wọ́n pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù ń retí làwọn náà ń retí. Onítibí yìí kò ṣe bí èkejì rẹ̀, ńṣe ló ń bẹ Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ kí Jésù rántí ẹni tí òun jẹ́ nìkan ni, bíkòṣe pé kó ṣe ohun kan fún òun—ìyẹn ni pé kó jí òun dìde.—Lúùkù 23:42.
Léraléra ní Bíbélì fi hàn pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run “rírántí” túmọ̀ sí gbígbé ìgbésẹ̀ kan tó dára. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí àkúnya omi ti bo ayé mọ́lẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́, “Ọlọ́run rántí Nóà . . . , Ọlọ́run sì mú kí ẹ̀fúùfù kọjá lórí ilẹ̀ ayé, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:1) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìyẹn ni Sámúsìnì tí àwọn Filísínì fọ́ lójú, tí wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n dè, gbàdúrà pé: “Jèhófà . . . , rántí mi, jọ̀wọ́, kí o sì fún mi lókun, jọ̀wọ́, lẹ́ẹ̀kan yìí péré.” Jèhófà rántí Sámúsìnì nípa fífún un ní agbára tó ju tí ẹ̀dá lọ, tó fi jẹ́ pé ó lè gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Àwọn Onídàájọ́ 16:28-30) Ní ti Nehemáyà ní tirẹ̀, Jèhófà bù kún ìsapá rẹ̀, a sì dá ìjọsìn tòótọ́ padà sí Jerúsálẹ́mù.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí. (Róòmù 15:4) Táa bá ń rántí Jèhófà nípa wíwá ọ̀nà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ti ṣe láyé ọjọ́un, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò rántí wa nípa ríràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tí a nílò lójoojúmọ́, nípa títì wá lẹ́yìn nígbà táa bá dojú kọ àdánwò, àti nípa dídá wa nídè nígbà tó bá mú ìdájọ́ wá sórí àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Mátíù 6:33; 2 Pétérù 2:9.